ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/03 ojú ìwé 1
  • “Ẹ Fi Ayọ̀ Yíyọ̀ Sin Jèhófà”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Fi Ayọ̀ Yíyọ̀ Sin Jèhófà”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jẹ́ Kí Ayọ̀ Tí Ò Ń Ní Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Pọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìdùnnú​—Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ń Fúnni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ṣiṣẹ́sin Jehofa Pẹ̀lú Ìdùnnú-Ayọ̀ Ọkàn-Àyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Síṣiṣẹ́sìn Jehofa Pẹlu Ayọ̀
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 10/03 ojú ìwé 1

“Ẹ Fi Ayọ̀ Yíyọ̀ Sin Jèhófà”

1. Kí lohun tó lè fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ayọ̀ ńláǹlà?

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Fílí. 4:4) Àǹfààní ńláǹlà tí a ní láti wàásù ìhìn rere fún àwọn ẹni bí àgùntàn àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jọ́sìn Jèhófà jẹ́ ohun tó ń fún wa ní ayọ̀ ńláǹlà. (Lúùkù 10:17; Ìṣe 15:3; 1 Tẹs. 2:19) Àmọ́ o, kí la lè ṣe bí a bá ṣàkíyèsí pé a ò láyọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

2. Báwo ni ríronú nípa ẹni tó yan iṣẹ́ ìwàásù fún wa ṣe lè fún wa láyọ̀?

2 Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Yàn fún Wa: Rántí pé Jèhófà ló pàṣẹ fún wa láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Dájúdájú, àǹfààní ńlá gbáà la ní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run” nínú iṣẹ́ pípòkìkí ìhìn Ìjọba àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn! (1 Kọ́r. 3:9) Kristi Jésù wà pẹ̀lú wa bí a ti ń ṣe iṣẹ́ tí a kò tún ní padà ṣe mọ́ láé yìí. (Mát. 28:18-20) Àwọn áńgẹ́lì náà ń kópa tó pọ̀ gan-an nínú iṣẹ́ yìí, wọ́n sì ń bá wa ṣiṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí títóbi tó ń lọ lọ́wọ́ nísinsìnyí. (Ìṣe 8:26; Ìṣí. 14:6) Ìwé Mímọ́, pa pọ̀ pẹ̀lú ìrírí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ní, fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé Jèhófà ń ti iṣẹ́ yìí lẹ́yìn. Nítorí náà, nígbà tí a bá ń wàásù, ńṣe là ń lọ “gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ní iwájú Ọlọ́run, ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi.” (2 Kọ́r. 2:17) Láìsí àní-àní, ó yẹ kí èyí fún wa láyọ̀!

3. Ipa wo ni àdúrà ń kó ká bàa lè jẹ́ aláyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run?

3 Àdúrà ṣe kókó bí a bá fẹ́ jẹ́ aláyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. (Gál. 5:22) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run láìsí pé ó fún wa ní okun rẹ̀, ó yẹ ká máa bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀, èyí tó máa ń fún àwọn tó bá ń béèrè fún un ní fàlàlà. (Lúùkù 11:13; 2 Kọ́r. 4:1, 7; Éfé. 6:18-20) Gbígbàdúrà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí pé nǹkan á dára nígbà tí a bá bá àwọn tí kò fi ìfẹ́ hàn sí iṣẹ́ ìwàásù wa pàdé. Yóò jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa fi àìṣojo àti ayọ̀ wàásù nìṣó.—Ìṣe 4:29-31; 5:40-42; 13:50-52.

4. Báwo ni mímúra sílẹ̀ dáadáa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù, àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ wo la sì lè gbà múra sílẹ̀?

4 Múra Sílẹ̀ Dáadáa: Ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan láti gbà mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i nígbà tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni pé ká máa múra sílẹ̀ dáadáa. (1 Pét. 3:15) Kò yẹ kí irú ìmúrasílẹ̀ bẹ́ẹ̀ gba àkókò púpọ̀. Kìkì ìṣẹ́jú díẹ̀ lo nílò láti ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá fún fífi àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọni tàbí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tó bá ìwé tó o fẹ́ fi lọni mu. Bó o bá fẹ́ mọ àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o lè lò, o lè wo ìwé Reasoning tàbí àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ti kọjá. Àwọn akéde kan ti rí i pé kíkọ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí sórí ìwé pélébé kan gbéṣẹ́ gan-an. Lóòrèkóòrè, wọ́n máa ń wo ìwé náà gààràgà láti lè rántí ohun tí wọ́n á sọ. Èyí ni kì í jẹ́ kí ojora mú wọn, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n lè fi ìfọ̀kànbalẹ̀ wàásù.

5. Báwo ni ayọ̀ ṣe ń ṣe àwa àtàwọn ẹlòmíràn láǹfààní?

5 Ayọ̀ máa ń ṣeni ní ọ̀pọ̀ àǹfààní. Bí ayọ̀ bá hàn lójú wa, yóò jẹ́ kí iṣẹ́ wa túbọ̀ fani mọ́ra. Ayọ̀ ń fún wa lókun láti ní ìfaradà. (Neh. 8:10; Héb. 12:2) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ wa ń fi ògo fún Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa “fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà.”—Sm. 100:2.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́