ÌDÙNNÚ Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ń Fúnni
GBOGBO èèyàn ló fẹ́ káyé wọn ládùn kó lóyin. Àmọ́ ó ṣeni láàánú pé àwọn ìṣòro “tí ó nira láti bá lò” là ń bá yí láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (2 Tím. 3:1) Bí àpẹẹrẹ, ìwà ìrẹ́jẹ, àìsàn, àìríṣẹ́ṣe, ẹ̀dùn ọkàn àtàwọn nǹkan míì tó ń fa ìbànújẹ́ àti àníyàn ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn má láyọ̀ mọ́. Kódà, àwọn kan lára wa ti rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n sì ti pàdánù ayọ̀ wọn. Tírú ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ, kí lo lè ṣe táá jẹ́ kó o pa dà láyọ̀?
Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ó ṣe pàtàkì ká kọ́kọ́ mọ ohun tó túmọ̀ sí tá a bá sọ pé èèyàn ń dunnú tàbí pé ó láyọ̀, àá sì jíròrò ohun tó mú káwọn kan máa láyọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ níṣòro. Lẹ́yìn náà, a máa mọ ohun tí ò ní jẹ́ ká pàdánù ayọ̀ wa àtohun tá a lè ṣe láti pa kún ayọ̀ tá a ní.
KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ TÁ A BÁ SỌ PÉ ÈÈYÀN LÁYỌ̀?
Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín kéèyàn láyọ̀ àti kéèyàn jẹ́ aláwàdà tàbí kéèyàn máa rẹ́rìn-ín. Ẹ wo àkàwé yìí ná: Tẹ́nì kan bá mutí yó, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́rìn-ín. Àmọ́ kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí ọtí bá ká lójú ẹ̀ tán? Kò ní sẹ́rìn-ín lẹ́nu rẹ̀ mọ́, ṣe ni ìbànújẹ́ á dorí ẹ̀ kodò. Ó ṣe kedere pé kì í ṣe ojúlówó ayọ̀ ló mú kó máa rẹ́rìn-ín.—Òwe 14:13.
Inú ọkàn lọ́hùn-ún ni ojúlówó ayọ̀ ti máa ń wá. Àwọn kan sọ pé ayọ̀ ni ìmọ̀lára téèyàn máa ń ní tọ́wọ́ ẹni bá tẹ ohun téèyàn ń fẹ́ tàbí tó dá a lójú pé òun máa rí nǹkan náà gbà. Kéèyàn láyọ̀ túmọ̀ sí pé kéèyàn máa dunnú kí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀ yálà nǹkan rọgbọ tàbí kò rọgbọ. (1 Tẹs. 1:6) Àní sẹ́, èèyàn lè láyọ̀ kódà nígbà tí nǹkan bá ń da ọkàn rẹ̀ láàmú. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n na àwọn àpọ́sítélì lẹ́gba torí pé wọ́n ń wàásù nípa Kristi. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé wọ́n “bá ọ̀nà wọn lọ kúrò níwájú Sànhẹ́dírìn, wọ́n ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 5:41) Ó ṣe kedere pé kì í ṣe torí pé wọ́n nà wọ́n ni wọ́n ṣe ń yọ̀. Àmọ́ wọ́n ń yọ̀ torí pé wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run.
A kì í bí ayọ̀ mọ́ni, bẹ́ẹ̀ sì lèèyàn ò lè ṣàdédé ní in. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé apá kan lára èso ti ẹ̀mí ni ayọ̀ tòótọ́. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè mú ká ní “àkópọ̀ ìwà tuntun,” èyí sì máa jẹ́ ká ní ayọ̀. (Éfé. 4:24; Gál. 5:22) Tá a bá ní ojúlówó ayọ̀, àá lè fara da àwọn ìṣòro ìgbésí ayé láìbọ́hùn.
ÀWỌN TÁ A LÈ FARA WÉ
Àwọn nǹkan dáadáa ni Jèhófà fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ láyé, kì í ṣe àwọn nǹkan búburú tó gba ayé kan lónìí. Síbẹ̀, ìyẹn ò ní kí Jèhófà má láyọ̀ mọ́. Kódà Bíbélì sọ pé: “Okun àti ìdùnnú ń bẹ ní ipò rẹ̀.” (1 Kíró. 16:27) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn nǹkan rere táwa ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbé ṣe ń “mú ọkàn-àyà [Jèhófà] yọ̀.”—Òwe 27:11.
Ẹ jẹ́ ká fara wé Jèhófà, ká má ba ọkàn jẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ táwọn nǹkan ò bá rí bá a ṣe fẹ́. Dípò tá a fi máa pàdánù ayọ̀ wa, ẹ jẹ́ ká máa pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan rere tá à ń gbádùn báyìí, ká sì máa fi sùúrù retí àwọn nǹkan àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.a
Nínú Bíbélì, a tún rí àpẹẹrẹ àwọn tó ń láyọ̀ láìka ìṣòro tí wọ́n kojú sí. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù fara da ọ̀pọ̀ ìnira àtàwọn ìṣòro míì táwọn èèyàn fà fún un. (Jẹ́n. 12:10-20; 14:8-16; 16:4, 5; 20:1-18; 21:8, 9) Kódà lójú gbogbo ìṣòro yẹn, Ábúráhámù ṣì láyọ̀. Kí ló mú kó máa láyọ̀? Ó nírètí pé òun máa gbé nínú ayé tuntun lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà. (Jẹ́n. 22:15-18; Héb. 11:10) Jésù sọ pé: “Ábúráhámù baba yín yọ̀ gidigidi nínú ìfojúsọ́nà fún rírí ọjọ́ mi.” (Jòh. 8:56) Àwa náà lè fara wé Ábúráhámù tá a bá ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tá a ní.—Róòmù 8:21.
Bíi ti Ábúráhámù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Sílà pọkàn pọ̀ sórí àwọn ìlérí Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ wọn lágbára, wọn ò sì jẹ́ kí ìṣòro mú kí wọ́n pàdánù ayọ̀ wọn. Ní ọjọ́ tí wọ́n lù wọ́n bí ẹni lu bàrà tí wọ́n sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n, Bíbélì sọ pé: “Ní nǹkan bí àárín òru, [wọ́n] ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.” (Ìṣe 16:23-25) Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fara dà á ni pé wọ́n ń ronú nípa ìlérí Ọlọ́run, wọ́n sì ń yọ̀ torí wọ́n mọ̀ pé torí Kristi làwọn ṣe ń jìyà. Àwa náà lè fara wé Pọ́ọ̀lù àti Sílà tá a bá ń ronú nípa ayọ̀ tá a máa ní tá a bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.—Fílí. 1:12-14.
A rí àpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí tí wọn ò jẹ́ kí ìṣòro tí wọ́n ń kojú mú kí wọ́n pàdánù ayọ̀ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ní November 2013, ìjì líle tí wọ́n pè ní Super Typhoon Haiyan jà láwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Philippines. Ìjì yẹn ṣọṣẹ́ gan-an débi pé àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan [1,000] ló pàdánù ilé wọn. Arákùnrin George tí ilé rẹ̀ nílùú Tacloban wó pátápátá sọ pé: “Láìka gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn sí, ṣe ni inú àwọn ará ń dùn. Àní sẹ́, ayọ̀ tá a ní kọjá àfẹnusọ.” Torí náà, nígbàkigbà tá a bá kojú ìṣòro tó le, ẹ jẹ́ ká máa ronú nípa àwọn nǹkan rere tí Jèhófà ṣe fún wa, tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ àá láyọ̀. Àwọn nǹkan míì wo ni Jèhófà fún wa tó ń mú ká máa láyọ̀?
ÌDÍ AYỌ̀ WA PỌ̀ GAN-AN
Ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa láyọ̀ ni pé a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Ẹ wò ó ná: A mọ Jèhófà Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run. Òun ni Baba wa, òun ni Ọlọ́run wa, òun sì tún ni Ọ̀rẹ́ wa!—Sm. 71:17, 18.
A tún mọyì bí Jèhófà ṣe dá wa tó sì fún wa láwọn nǹkan tó ń mú ká máa gbádùn ara wa. (Oníw. 3:12, 13) Torí pé Jèhófà mú kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ òun, a mọ ohun tó ní lọ́kàn fáráyé. (Kól. 1:9, 10) Torí náà, ìgbésí ayé wa nítumọ̀. Lọ́wọ́ kejì, ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà láyé ni ò mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwa àti irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ó ní: “ ‘Ojú kò tíì rí, etí kò sì tíì gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò tíì rò nínú ọkàn-àyà ènìyàn àwọn ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ Nítorí àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.” (1 Kọ́r. 2:9, 10) Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn pé a mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé?
Ẹ tún jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tí Jèhófà ṣe fún àwa èèyàn rẹ̀. Jèhófà ń dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ìyẹn sì ń múnú wa dùn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? (1 Jòh. 2:12) Torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa, ó mú kó dá wa lójú pé ayé tuntun ò ní pẹ́ dé. (Róòmù 12:12) Kódà ní báyìí, à ń láyọ̀ torí pé Jèhófà fún wa ní ẹgbẹ́ àwọn ará tá a jọ ń jọ́sìn rẹ̀. (Sm. 133:1) Bákan náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà máa dáàbò bo àwa èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù. (Sm. 91:11) Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìbùkún tí Jèhófà fi jíǹkí wa yìí, àá máa láyọ̀, ayọ̀ wa á sì máa pọ̀ sí i.—Fílí. 4:4.
BÁ A ṢE LÈ MÚ KÍ AYỌ̀ WA PỌ̀ SÍ I
Báwo làwa Kristẹni ṣe lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i? Jésù sọ pé: “Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ìdùnnú mi lè wà nínú yín, kí a sì lè sọ ìdùnnú yín di kíkún.” (Jòh. 15:11) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ Jésù yìí kò fi hàn pé a lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i? Ṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí ẹni tó ń dáná igi. Tí kò bá fẹ́ kí iná náà kú, ó ṣe pàtàkì kó máa koná mọ́ ọn. Lọ́nà kan náà, tó o bá ń mú kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára, ayọ̀ rẹ á pọ̀ sí i. Rántí pé, ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń mú kéèyàn láyọ̀. Torí náà, wàá túbọ̀ láyọ̀ tó o bá ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàdúràtàdúrà, tó o sì ń bẹ Jèhófà nígbà gbogbo pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Sm. 1:1, 2; Lúùkù 11:13.
O tún lè mú kí ayọ̀ rẹ pọ̀ sí i tó o bá ń lo ara rẹ lẹ́nu iṣẹ́ tó ń múnú Ọlọ́run dùn. (Sm. 35:27; 112:1) Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé Jèhófà dá wa ká lè ‘bẹ̀rù òun Ọlọ́run tòótọ́, ká sì pa àwọn àṣẹ òun mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.’ (Oníw. 12:13) Lédè míì, torí ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ló fi dá wa sáyé. Torí náà, tá a bá ń fayé wa sin Jèhófà, ìgbésí ayé tó dáa jù tó sì kún fáyọ̀ la máa ní.b
ÀǸFÀÀNÍ TÉÈYÀN Á RÍ TÓ BÁ Ń LÁYỌ̀
Bí ayọ̀ wa ṣe ń pọ̀ sí i, ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí. Bí àpẹẹrẹ, àá túbọ̀ múnú Baba wa ọ̀run dùn bá a ṣe ń fayọ̀ sìn ín bá a tiẹ̀ ń fara da ìṣòro. (Diu. 16:15; 1 Tẹs. 5:16-18) Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a ní ayọ̀ tòótọ́, a kì í lépa àwọn nǹkan tara. Kàkà bẹ́ẹ̀, àá máa fara wa jìn ká lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 13:44) Nígbà tá a bá rí àwọn àbájáde lílo ara wa nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i, inú wa máa dùn pé ohun gidi là ń fayé wa ṣe, àá sì tún mú káwọn míì láyọ̀.—Ìṣe 20:35; Fílí. 1:3-5.
Olùṣèwádìí kan nílé ẹ̀kọ́ gíga University of Nebraska sọ pé: “Tí inú rẹ bá ń dùn tó o sì ní ìtẹ́lọ́rùn báyìí, ó ṣeé ṣe kí ìlera rẹ sunwọ̀n sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́.” Èyí bá ohun tí Bíbélì sọ mu, pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” (Òwe 17:22) Ó ṣe kedere pé bí ayọ̀ rẹ ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìlera rẹ á máa sunwọ̀n sí i.
Lóòótọ́ àsìkò yìí nira gan-an, síbẹ̀ a lè ní ojúlówó ayọ̀ báyìí àti lọ́jọ́ iwájú tá a bá ń sapá láti ní ẹ̀mí mímọ́. A lè rí ẹ̀mí mímọ́ yìí gbà tá a bá ń gbàdúrà, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tá a sì ń ṣàṣàrò lé e lórí. Bákan náà, a lè mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i tá a bá ń ronú lórí àwọn ìbùkún tá à ń rí báyìí, tá à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àwọn míì, tá a sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Lọ́nà yìí, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 64:10 máa ṣẹ sí wa lára, pé: “Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà, yóò sì sá di í ní tòótọ́.”
a A máa sọ̀rọ̀ nípa sùúrù tàbí ìpamọ́ra tó jẹ́ apá kan “èso ti ẹ̀mí” nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí lọ́jọ́ iwájú.
b Tó o bá fẹ́ mọ àwọn ohun míì tó o lè ṣe táá mú kí ayọ̀ rẹ pọ̀ sí i, wo àpótí náà “Bí Ayọ̀ Rẹ Ṣe Lè Pọ̀ Sí I.”