Síṣiṣẹ́sìn Jehofa Pẹlu Ayọ̀
“Ṣiṣẹ́sìn Jehofa pẹlu inu didun. Wá sí iwájú rẹ̀ pẹlu igbe ayọ̀.”—SAAMU 100:2, New World Translation.
1, 2. (a) Bawo ni a ṣe mú ẹtanu ẹ̀yà ìran wá sojutaye ní Berlin, Germany, ṣugbọn bawo ni ìgbétáásì fun “Ijọba Germany Ẹlẹgbẹrun Ọdun” ṣe ṣàṣeyọrí? (b) Ìyàtọ̀ wo sí ti 1936 ni a ṣàkíyèsí ní Olympia Stadium ní July 1990, kinni a sì so ayọ̀ àwùjọ jákèjádò agbaye tí wọn péjọ síbẹ̀ mọ́?
IBI iran naa jẹ́ Olympia Stadium, Berlin. Ọdun mẹrinlelaadọta ṣaaju, stadium dídára yii di ìkóríjọ àríyànjiyàn nigbati a ròhìn pe apàṣẹ-wàá Nazi naa Adolf Hitler tẹmbẹlu sárésáré ara America kan ti o dúláwọ̀ ẹni tí ó ṣẹ́gun gbà àmì-ẹ̀yẹ wúrà mẹrin. Ajalu ni o jẹ nitootọ fun ọrọ naa “ìlọ́lájù ẹya iran Aryan”a tí Hitler fi itẹnumọ sọ pẹlu ẹ̀tanu ẹya iran! Ṣugbọn nisinsinyi, ní July 26, 1990, awọn dúdú, funfun, pupa—awọn ènìyàn tí a sopọ̀ṣọ̀kan lati 64 àwùjọ orílẹ̀-èdè, 44,532 lapapọ—péjọpọ̀ níbi yìí fun Apejọpọ Àgbègbè “Èdè Mímọ́gaara” ti awọn Ẹlẹrii Jehofa. Irú ayọ̀ wo ni ó gbilẹ̀ ní ọsan Thursday yẹn! Tẹle ọ̀rọ̀-àsọyé lórí baptism, awọn olùnàgà fun àǹfààní ti wọn jẹ 1,018 kígbe jáde pe, “Ja!” ati lẹẹkan síi, “Ja!” ní fifi itẹnumọ polongo ìyàsímímọ́ wọn sí Jehofa Ọlọrun lati ṣe ìfẹ́-inú rẹ̀.
2 Ó gba 19 iṣẹju fun awọn Ẹlẹrii titun wọnyi lati tò jáde kuro ninu stadium naa ní mimu ọ̀nà wọn pọ̀n lọ sí ìkùdu baptism naa. Ati láàárín gbogbo àkókò wọnni, àtẹ́wọ́ adún-bí-àrá ndún lọ jákèjádò ibudo iṣere salalu yẹn. Awọn ajagunmólú ninu awọn Eré ìdárayá Olympic kò tíì nírìírí àtẹ́wọ́ irú eyi ri tí ó ńkí ọgọrọọrun awọn wọnyi kaabọ nisinsinyi, lati inú ọpọlọpọ àwùjọ orílẹ̀-èdè, tí wọn ńfi ìgbàgbọ́ tí ó ṣẹ́gun ayé han ni gbangba. (1 Johanu 5:3, 4) Ayọ̀ wọn ni a sopọ gírígírí mọ ìgbẹ́kẹ̀lé naa pe Ijọba Ọlọrun tí a ńṣàkóso lati ọwọ́ Kristi yoo mú ẹgbẹrun ọdun ibukun ológo wá fun aráyé nitootọ.—Heberu 6:17, 18; Iṣipaya 20:6; 21:4, 5.
3. Otitọ wo ni a tẹnumọ́ nipa ìgbẹkẹle awọn olùpéjọpọ̀, bawo sì ni?
3 Kò sí ìkórìíra ẹ̀yà ìran tabi ti ìfẹ́-orílẹ̀-èdè ẹni níhìn-ín, nitori gbogbo wọn ni wọn ńsọ èdè mímọ́gaara ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ti wọn tipa bayii ńtẹnumọ́ otitọ awọn ọ̀rọ̀ Peteru: “Nitootọ mo wòye pe, Ọlọrun kii ṣe ojúsàájú ènìyàn: ṣugbọn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ńṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.”—Iṣe 10:34, 35; Sẹfanaya 3:9.
4. Lábẹ́ awọn ipò wo ni ọpọjulọ lara awọn olùpéjọpọ̀ ti di onígbàgbọ́, bawo sì ni a ṣe dáhùn adura wọn?
4 Ìpín títóbi lara awọn olùpéjọpọ̀ wọnyi ní Berlin ti di onígbàgbọ́ láàárín ọpọlọpọ ọdun ìnilára, tí ó kárí àkókò Nazi (1933-45) ati ti àkókò ijọba-ajumọni tí ó tẹle e ní Ìlà-oòrùn Germany, níbi tí a ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mú ìfòfindè awọn Ẹlẹrii Jehofa kúrò lọna òfin ní March 14, 1990. Fun ìdí yii, ọ̀pọ̀ julọ ninu wọn ti “gba ọ̀rọ̀ naa ninu ìpọ́njú ọpọlọpọ, pẹlu ayọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.” (1 Tẹsalonika 1:6) Wọn ní òmìnira pupọ sii nisinsinyi lati ṣiṣẹ́sin Jehofa, ayọ̀ wọn kò sì ní ààlà.—Fiwera pẹlu Aisaya 51:11.
Awọn Àkókò fun Ayọ̀
5. Bawo ni Israẹli ṣe ṣayẹyẹ ìdáǹdè Jehofa ní Òkun Pupa?
5 Ìtúsílẹ̀ awọn arakunrin wa ní Ìlà-oòrùn Europe, ati láìpẹ́ yii ní awọn apá Africa ati Asia, rán wa létí awọn ìdáǹdè lati ọwọ́ Jehofa ní awọn àkókò tí ó ti kọjá. Awa rántí ìṣe alágbára Jehofa ní Òkun Pupa, ati bí orin ìdúpẹ́ awọn ọmọ Israẹli yii ṣe dé òtéńté rẹ̀ ninu awọn ọ̀rọ̀ naa: “Tani ó dabi iwọ, Oluwa [“Jehofa,” NW], ninu awọn alágbára? Tani ó dabi iwọ, ológo ní mímọ́, ẹlẹ́rù ní ìyìn, tí ńṣe ohun ìyanu?” (Ẹksodu 15:11) Lonii, awa kò ha nbaalọ lati yọ̀ ninu awọn ohun ìyanu tí Jehofa ńṣe fun awọn ènìyàn rẹ̀? Dajudaju awa ṣe bẹẹ!
6. Kinni a lè kẹ́kọ̀ọ́ lati inú hiho Israẹli fun ayọ̀ ní 537 B.C.E.?
6 Ayọ̀ kún àkúnwọ́sílẹ̀ ní 537 B.C.E. nigbati a mú Israẹli padàbọ̀sípò sí ilẹ̀ rẹ̀ lẹhin ìgbèkùn ní Babiloni. Orílẹ̀-èdè Jehofa lè polongo nisinsinyi, gẹgẹbi Aisaya ti sọtẹlẹ: “Kíyèsíi, Ọlọrun ni ìgbàlà mi; emi ó gbẹ́kẹ̀lé e, emi kì yoo sì bẹ̀rù: nitori Oluwa Jehofa ni agbára mi ati orin [“okun,” NW] mi; oun pẹlu sì di ìgbàlà mi.” Ẹ wo ayọ̀ àṣeyọrí ti eyi jẹ! Bawo ni orílẹ̀-èdè naa yoo ṣe fi ayọ̀ yẹn hàn? Aisaya nbaalọ: “Ní ọjọ́ naa ni ẹyin yoo sì wipe, Yin Oluwa [“Jehofa,” NW], képe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ láàárín awọn ènìyàn, mú un wá sí iranti pe, orukọ rẹ̀ ni a gbélékè. Kọrin sí Oluwa [“Jehofa,” NW]: Nitori ó ti ṣe ohun dídára.” Wọn lè “hó” nisinsinyi ní mímú kí awọn iṣẹ́ alágbára rẹ̀ “di mímọ̀ ní gbogbo ayé,” gan-an gẹgẹbi awọn iranṣẹ Jehofa tí a sọ dòmìnira ti ṣe lonii.—Aisaya 12:1-6.
Ayọ̀ ninu Iṣẹ́ Jehofa
7. Awọn ìdáǹdè wo ni ó beere fun ayọ̀ àṣeyọrí ní 1919?
7 Ní àkókò òde-òní awọn iranṣẹ Jehofa bẹrẹsii hó fun ayọ̀ nigbati oun fi ìdáǹdè àgbàyanu fun wọn ní 1919. Ní March 26 ọdun yẹn, awọn memba Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ni a túsílẹ̀ kuro ninu ẹ̀wọ̀n ni United States níbi tí a ti há wọn mọ́ túbú fun oṣu mẹsan-an lábẹ́ ẹ̀sùn èké ti ìdìtẹ̀ sí ijọba. Irú ayẹyẹ títóbilọ́lá wo ni ó ṣẹlẹ̀ ní kíkí wọn káàbọ̀ padà sí Bethel ti Brooklyn! Jù bẹ́ẹ̀ lọ, gbogbo awọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró lè yọ̀ nisinsinyi fun dídi ẹni tí a túsílẹ̀ nipa tẹ̀mí lati inú Babiloni Nla, ètò-ìgbékalẹ̀ ti ìsìn ninu eyi tí Satani ti dẹkùn mú gbogbo ayé lódidi.—Iṣipaya 17:3-6; 18:2-5.
8. Ìmújáde yiyanilẹnu wo ni a kede rẹ̀ ní Apejọpọ Cedar Point ní 1919, ìpè wo ni a sì fifúnni fun bibọ sẹnu iṣẹ?
8 Awọn ohun tí wọn jẹyọ ninu ọ̀rọ̀-ìtàn ní 1919 ni a déládé nipasẹ apejọpọ awọn ènìyàn Ọlọrun tí a ṣe ní Cedar Point, Ohio, U.S.A., ní September 1 sí 8. Ní ọjọ́ karùn-ún apejọ yẹn, “Ọjọ́ Awọn Ẹlẹgbẹ Alájọṣiṣẹ́,” ààrẹ Watch Tower Society, J. F. Rutherford, bá 6,000 eniyan sọrọ ninu àsọyé tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Kikede Ijọba naa.” Lẹhin jíjíròrò Iṣipaya 15:2 ati Aisaya 52:7, oun sọ fun awọn olùfetísílẹ̀ pe ìwé-ìròhìn titun kan, The Golden Age (tí a mọ̀ nisinsinyi gẹgẹbi Awake! [Ji!]) ni a ó maa tẹ̀jáde ní gbogbo ọsẹ mejimeji, ní pàtàkì fun ìpínkiri ní pápá. Ní ipari ọrọ rẹ ó wipe: “Awọn tí wọn nfi gbogbo ara fọkansin Oluwa; awọn tí wọn jẹ́ aláìbẹ̀rù, tí ọkàn-àyà wọn mọ́ gaara, tí wọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ati Jesu Oluwa pẹlu gbogbo èrò-inú, okun, ọkàn ati wíwà wọn gẹgẹbi ẹnikan, gẹgẹbi àǹfààní ti yọọda, yoo yọ̀ lati lọwọ ninu iṣẹ́ yii. Ẹ beere lọwọ Oluwa fun ìtọ́sọ́nà ati ìdarí kí ó lè ṣe yin ní ikọ̀ tootọ, ti o gbeṣẹ ti o si jẹ olùṣòtítọ́. Nigba naa, pẹlu orin ayọ̀ ninu ọkàn-àyà yin, ẹ maa lọ lati ṣiṣẹ́sìn ín.”
9, 10. Bawo ni Jehofa ṣe mú ìtẹ̀jáde awọn iwe-irohin Ilé-ìṣọ́nà ati Ji! láásìkí?
9 “Orin ayọ̀” yii ni a ti gbọ́ jákèjádò ayé! Ọpọlọpọ awọn onkawe wa ti nipin-in, láìsí iyèméjì, ninu mímú ìlọyíká ìwé-ìròhìn Ji! lọsókè dé 12,980,000 awọn ẹ̀dà ìtẹ̀jáde kọọkan nisinsinyi ní 64 èdè. Gẹgẹbi ohun èèlò alágbára ninu ṣíṣamọ̀nà awọn olufifẹhan sí otitọ, Ji! ṣiṣẹ́ gẹgẹbi alábàákẹ́gbẹ́ Ilé-ìṣọ́nà. Ní orílẹ̀-èdè Gábàsì kan, arabinrin aṣaaju-ọna kan, tí ńṣiṣẹ́ ni ipa-ọ̀nà ìwé-ìròhìn déédéé kan, ni ẹnu yà lati ríi pe ìgbà kọọkan tí oun ba fi awọn ìwé-ìròhìn ti wọn ṣẹṣẹ jade jiṣẹ, onílé naa ńfi ohun tí ó bá $7 (U.S.) dọ́gba tọrẹ fun iṣẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa yika aye—o daju pe ó ńfi ìmọrírì rere hàn fun iṣẹ́ Ijọba naa!
10 Nisinsinyi ní bíbẹ̀rẹ̀ ọdun 112 ti a ti ntẹ ẹ jade, ìwé-ìròhìn Ilé-ìṣọ́nà ti lọyíká to 15,290,000 ní 111 èdè, ti 59 lara awọn ẹ̀dà ìtẹ̀jáde wọnyi sì ńfarahàn nígbà kan naa yíká ayé pẹlu awọn ọ̀rọ̀ inú ìwé kan naa. Gẹgẹbi ìríjú olùṣòtítọ́, aṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró nbaa lọ lati fun awọn onkawe onímọrírì ní “ìwọ̀n ounjẹ [tẹ̀mí] wọn ní àkókò.” (Luku 12:42) Ní ọdun 1990, awọn Ẹlẹrii Jehofa rohin ifisode 2,968,309 awọn àsansílẹ̀-owó titun fun awọn ìwé-ìròhìn mejeeji, ìbísí ti o jẹ ipin 22.7 ninu ọgọrun-un rekọja ti ọdun 1989.
Ayọ̀ Búrẹ́kẹ́
11. (a) Ìpè wo ni a nawo rẹ si awọn ènìyàn Ọlọrun ní Cedar Point ní 1922? (b) Bawo ni a ṣe mú ìhó ayọ̀ gbòòrò sii?
11 Ayọ̀ tún búrẹ́kẹ́ bi awọn ènìyàn Ọlọrun tí iye wọn jẹ́ 10,000 nisinsinyi ti péjọ fun apejọpọ keji ní Cedar Point, ní September 1922, pẹlu 361 tí a baptisi. Ninu àwíyé rẹ̀ “Ijọba Ọrun ti Sunmọle,” tí a gbékarí Matiu 4:17, Arakunrin Rutherford sọrọ de òtéńté arunisókè naa: “Ayé gbọdọ mọ̀ pe Jehofa ni Ọlọrun ati pe Jesu Kristi ni Ọba awọn ọba ati Oluwa awọn oluwa. Ọjọ́ gbogbo awọn ọjọ́ ni eyi. Ẹ kíyèsíi, Ọba naa ńjọba! Ẹyin ni aṣojú ìpolongo rẹ̀. Nitori naa, ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, ẹ fọnrere, Ọba naa ati Ijọba rẹ̀.” Awọn wọnni tí wọn bújáde pẹlu igbe ayọ̀ tí ó dun sókè ní apejọpọ yẹn ti pọ sii ní iye títí o fi di ọdun 1989 nigba tiohun tí ó ju 6,600,000 pàdépọ̀ ni 1,210 apejọpọ awọn Ẹlẹrii Jehofa yíká ayé, níbití 123,688 ti ṣe baptism.
12. (a) Ninu ayọ̀ aláìṣeé díyelé wo ni awọn ènìyàn Ọlọrun ṣàjọpín lonii? (b) Bawo ni a ṣe mú iṣẹ́-ìsìn wa sí Jehofa pẹlu ìgbọràn sí “awọn aláṣẹ onípò gígajù wadeedee?
12 Awọn Ẹlẹrii Jehofa mọriri òmìnira wọn. Lékè gbogbo rẹ̀, wọn yọ̀ ninu ìmúṣẹ awọn ọ̀rọ̀ Jesu lode-oni: “Ẹyin yoo sì mọ otitọ, otitọ yoo sì sọ yin di òmìnira.” Irú ayọ̀ wo ni ó jẹ́ lati dòmìnira kuro ninu awọn ohun-ìjìnlẹ̀ ati ìgbàgbọ́ asán ti ìsìn èké! Irú ayọ̀ aláìṣeé díyelé wo ni ó jẹ́ lati mọ Jehofa ati Ọmọkunrin rẹ̀ ati lati jẹ́ alájọṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu wọn, pẹlu ireti iye ainipẹkun! (Johanu 8:32; 17:3; 1 Kọrinti 3:9-11) Awọn iranṣẹ Ọlọrun tún mọrírì rẹ̀ nigbati “awọn aláṣẹ onípògígajù,” ti ayé yii, lábẹ́ eyi tí wọn ńgbé, bá bọlá fún ominira wọn lati pòkìkí ireti ológo ti Ijọba Jehofa lábẹ́ Kristi. Wọn nfi tinutinu “san ohun tí ńṣe ti Kesari fun Kesari,” nigba ti ó jẹ́ pe lákòókò kan naa wọn san “awọn ohun ti Ọlọrun fun Ọlọrun.”—Romu 13:1-7; Luku 20:25.
13. Bawo ni awọn Ẹlẹrii Jehofa ṣe fi ayọ̀ hàn nigba ti a tú wọn silẹ kuro ninu ìnilára?
13 Bí ó ti wù kí ó rí, bí awọn ènìyàn aláṣẹ bá gbìyànjú lati ká iṣẹ́ aigbọdọmaṣe sí Ọlọrun yii lọ́wọ́kò, awọn Ẹlẹrii Jehofa yoo dáhùn gẹgẹbi awọn apọsteli ti ṣe: “Awa kò gbọdọ má gbọ ti Ọlọrun ju ti ènìyàn lọ.” Nigba ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, lẹhin tí awọn olùṣàkóso naa ti tú awọn apọsteli silẹ, awọn wọnyi “lọkúrò . . . wọn ńyọ̀.” Bawo ni wọn ṣe fi ayọ̀ naa hàn? “Ní ojoojumọ ní tẹmpili ati ní ilé [dé ilé], wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni ati lati waasu Jesu Kristi.” (Iṣe 5:27-32, 41, 42) Bẹẹ gẹgẹ, awọn Ẹlẹrii Jehofa lóde-òní maa ńyọ̀ nigba ti wọn bá jèrè òmìnira pupọ sii lati maa ba iṣẹ́-òjíṣẹ́ wọn niṣo. Ní ọpọlọpọ ilẹ̀ níbití Jehofa ti ṣí ọ̀nà silẹ, wọn fi ayọ̀ kikọyọyọ hàn nipa fífúnni ní ìjẹ́rìí mímúnádóko sí orukọ ati Ijọba Jehofa tí ńbọ̀ nipasẹ Kristi Jesu.—Fiwera pẹlu Iṣe 20:20, 21, 24; 23:11; 28:16, 23.
Fífaradà Pẹlu Ayọ̀
14. Bawo ni ayọ̀ yii tí ó jẹ́ èso ti ẹ̀mí ṣe tayọ eyi tí a túmọ̀ ninu ìwé atúmọ̀-ọ̀rọ̀?
14 Kinni ayọ̀ kikọyọyọ yii tí awọn Kristian tootọ ńnírìírí rẹ̀? Ó jinlẹ̀ pupọ ó sì wàpẹ́títí ju ìdùnnù-ayọ̀ alaiduro pẹ tí ajagunmólú kan ninu Eré-ìdárayá Olympic ní. Ó jẹ́ èso ẹ̀mí mimọ Ọlọrun, tí Ọlọrun ńfifún awọn wọnni tí wọn “gbọ́ tirẹ̀.” (Iṣe 5:32) Ìwé atúmọ̀ èdè naa Webster túmọ̀ ayọ̀ gẹgẹbi eyi tí ó ‘jinlẹ̀ jù inúdídùn, ó tàn fún ayọ̀ tabi fi imọlara ẹni hàn ju ìdùnnú lọ.’ Fun Kristian, ayọ̀ ní itumọ tí ó jinlẹ pupọ síi paapaa. Bi o ti jẹ pe o sopọ timọtimọ mọ ìgbàgbọ́ wa, oun jẹ́ ànímọ́ alágbára, ti ńfúnnilókun. “Ayọ̀ Jehofa ni odi agbára yin.” (Nehemaya 8:10, NW) Ayọ̀ Jehofa, eyi tí awọn ènìyàn Ọlọrun mú dàgbà, tayọ ìtara ayọ̀ oréfèé tí awọn ènìyàn ńrí lati inú adùn ti ara, ti ayé.—Galatia 5:19-23.
15. (a) Ninu ìrírí awọn Kristian olùṣòtítọ́, bawo ni ayọ ti ṣe dapọ mọ́ ìfaradà? (b) Tọ́kasí awọn ẹsẹ iwe mimọ tí ńfúnni ni ìdánilójú afunnilokun ti pípa ayọ̀ mọ́?
15 Gbé awọn arakunrin wa ní Ukraine yẹ̀wò. Nigba ti ‘awọn aláṣẹ onípò gígajù’ lé ẹgbẹẹgbẹrun awọn wọnyi kúrò lọ sí Siberia ní ibẹrẹ awọn ọdun 1950, wọn jìyà ìnira ńláǹlà. Lẹhin naa, nigba ti awọn aláṣẹ fi ìdáríjì ọba fun wọn, wọn kún fun ọpẹ́, ṣugbọn kii ṣe gbogbo wọn ni wọn padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn. Eeṣe? Làálàá wọn ní Ìlà-oòrùn rán wọn létí Jakọbu 1:2-4: “Ẹyin ara mi, nigbati ẹyin bá bọ́ sínú onírúurú ìdánwò, ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ayọ̀; kí ẹ sì mọ̀ pe, ìdánwò ìgbàgbọ́ yin ńṣiṣẹ́ sùúrù.” Wọn fẹ́ lati maa baalọ ní fífaradà ninu ìkórè aláyọ̀ yẹn, ayọ̀ wo ni ó sì jẹ́ ní apejọpọ awọn Ẹlẹrii Jehofa lẹnu aipẹ yii ní Poland lati kí awọn Ẹlẹrii kaabọ lati ibi ti o jinna bii àgbègbè Ìlà-oòrùn etíkun Pacific. Ìfaradà ati ayọ̀ ti lọ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ lati pèsè ìṣùpọ̀-èso yii. Nitootọ, gbogbo awa tí a faradà á ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa pẹlu ayọ̀ lè wipe: “Ṣugbọn emi yoo maa yọ̀ ninu Oluwa [“Jehofa,” NW], emi yoo maa yọ̀ ninu Ọlọrun ìgbàlà mi. Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun ni agbára mi.”—Habakuku 3:18, 19; Matiu 5:11, 12.
16. Bawo ni awọn apẹẹrẹ rere Jeremaya ati Jobu ṣe fun wa níṣìírí ninu iṣẹ́ pápá wa?
16 Ṣugbọn, bawo ni awa ṣe lè pa ayọ̀ wa mọ nigba ti a bá njẹrii láàárín awọn alátakò olórí kunkun? Ranti pe awọn wolii Ọlọrun pa oju-iwoye aláyọ̀ mọ ninu awọn ipò tí wọn farajọ eyi. Jeremaya sọ nigbati ó wà lábẹ̀ àdánwò pe: “Nigbati a rí ọ̀rọ̀ rẹ, emi sì jẹ wọn, ọ̀rọ̀ rẹ sì jẹ́ inúdídùn mi, nitori orukọ rẹ ni a fi ńpè mi, iwọ Oluwa [“Jehofa,” NW], Ọlọrun awọn ọmọ ogun!” (Jeremaya 15:16) Iru àǹfààní wo ni ó jẹ́ lati jẹ́ ẹni tí a pè ní orukọ Jehofa ati lati jẹ́rìí sí orukọ yẹn! Ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn funraawa ati ìkópa kíkún ninu awọn ipade Kristian maa ńgbé wa ró lati maa yọ̀ niṣo ninu otitọ. Ayọ̀ wa yoo farahàn ninu ìṣesí wa ninu pápá ati nipa ẹ̀rín músẹ́ Ijọba wa. Àní lábẹ́ àdánwò mímúná pàápàá, Jobu lè sọ nipa awọn elénìní rẹ̀ pe: “Emi sì rẹ́rìn-ín sí wọn nigbati wọn kò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni wọn kò lè mú rẹ̀wẹ̀sì.” (Jobu 29:24) Gẹgẹ bi Jobu oluṣotitọ, awa kò nilati soríkodò nigbati awọn alátakò bá fi wá ṣẹ̀sín. Maa rẹ́rìn-ín! Ìrísí ojú wa lè fi ayọ̀ wa hàn kí a sì tipa bayii rí awọn tí yoo fetisilẹ.
17. Bawo ni ìfaradà pẹlu ayọ̀ ṣe lè so èso?
17 Gẹgẹ bi a ti ńkárí àgbègbè-ìpínlẹ̀ wa leralera, ìfaradà ati ayọ̀ wa lè ṣí awọn ènìyàn tí wọn ní ìtẹ̀sí lọna òdodo lórí kí ó sì fun wọn ní ìṣírí lati ṣàyẹ̀wò ireti ológo naa tí a ní. Ẹ wo ayọ̀ ti ó jẹ́ lati darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹlu wọn déédéé! Bi wọn sì ti ńgba awọn otitọ iyebíye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọkan, ẹ wo ìmọ̀lára ayọ̀ tí a ní bi wọn ti wa di awọn alábàákẹ́gbẹ́ wa ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa nikẹhin! Nigba naa awa lè sọ, gẹgẹbi apọsteli Pọọlu ti wi fun awọn onígbàgbọ́ titun ní ọjọ́ rẹ̀ pe: “Nitori kinni ireti wa, tabi ayọ̀ wa, tabi adé ìṣògo wa? Kì ha ṣe ẹyin ni niwaju Jesu Oluwa wa ní àbọ̀ rẹ̀? Nitori ẹyin ni ògo ati ayọ̀ wa.” (1 Tẹsalonika 2:19, 20) Nitootọ, ayọ̀ tí ńtẹ́nilọ́rùn ni a lè rí ninu ṣíṣamọ̀nà awọn ẹni titun sí otitọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati ninu ríràn wọn lọwọ lati di awọn Ẹlẹrii olùṣèyàsímímọ́, tí a baptisi.
Ayọ̀ Tí Ńgbẹ́mìíró
18. Kinni yoo ràn wa lọwọ lati kojú oniruuru awọn àdánwò òde-òní?
18 Ninu igbesi-aye wa ojoojumọ, ọpọlọpọ ipò lè beere fun ìfaradà. Àìsàn ara, ìsoríkọ́, ati ìnira ti ìṣúnná owó wulẹ jẹ́ diẹ ninu wọn. Bawo ni Kristian ṣe lè pa ayọ̀ rẹ̀ mọ́ kí ó baa lè kojú irú awọn àdánwò bẹẹ? Eyi ni a lè ṣe nipa lílọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fun ìtùnú ati ìtọ́sọ́nà. Kíkà iwe saamu tabi fifetisilẹ sí kíkà rẹ̀ lè pèsè ìtura lọpọlọpọ ní àkókò àdánwò. Sì ṣàkíyèsí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n Dafidi: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa [“Jehofa,” NW], oun ni yoo sì mú ọ dúró: oun kì yoo jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ lae.” (Saamu 55:22) Nitootọ Jehofa jẹ́ “Olùgbọ́ adura.”—Saamu 65:2, NW.
19. Bíi Dafidi ati Pọọlu, ìgbọ́kànlé wo ni awa lè ní?
19 Ètò-àjọ Jehofa, nipasẹ awọn ìtẹ̀jáde ati awọn alàgbà ijọ rẹ̀, dúró ni sẹpẹ nigbagbogbo lati ràn wa lọwọ, lati ṣiṣẹ kára lati dojukọ awọn iṣoro wa bi a ti jẹ ẹda-eniyan alailera. Dafidi fọ̀yàyà gbaninímọ̀ràn pe: “Fi ọ̀nà rẹ lé Oluwa [“Jehofa,” NW] lọwọ; gbẹkẹle e pẹlu; oun yoo sì mú un ṣẹ.” Oun tún lè wipe: “Emi ti wà ní èwe, emi sì dàgbà; emi kò tíì ríi kí a kọ olódodo silẹ, tabi kí irú-ọmọ rẹ kí ó maa ṣagbe ounjẹ.” Ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu ijọ Kristian, awa yoo mọ̀ dájú pe “lati ọwọ́ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá ni ìgbàlà awọn olódodo; oun ni aabo wọn ní ìgbà ìpọ́njú.” (Saamu 37:5, 25, 39) Ẹ jẹ́ kí a maa tẹle ìmọ̀ràn Pọọlu nigbagbogbo: “Nitori eyi ni àárẹ̀ kò ṣe mu wa; . . . niwọn bi a ko ti wo ohun ti a nri, bikoṣe ohun ti a ko ri: nitori ohun ti a nri ni ti igba isinsinyi; ṣugbọn ohun ti a ko ri ni ti ayeraye.”—2 Kọrinti 4:16-18.
20. Kinni a rí pẹlu ojú ìgbàgbọ́, bawo sì ni eyi ṣe ńsún wa ṣiṣẹ?
20 Pẹlu ojú ìgbàgbọ́ wa, awa lè rí ètò-ìgbékalẹ̀ titun ti Jehofa gan-an niwaju. Ẹ wo ayọ̀ aláìlẹ́gbẹ́ ati ibukun ti yoo wà níbẹ̀! (Saamu 37:34; 72:1, 7; 145:16) Ní imurasilẹ fun àkókò ológo yẹn, ẹ jẹ́ kí a kọbiarasí awọn ọ̀rọ̀ Saamu 100:2 (NW): “Ṣiṣẹ́sìn Jehofa pẹlu inu didun. Wá sí iwájú rẹ̀ pẹlu igbe ayọ̀.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Niti “ìlọ́lájù ẹya iran Aryan,” The New York Times ti February 17, 1940, fa ọ̀rọ̀ oludari onisin Katọlik kan ti Georgetown University yọ ní wiwipe “oun ti gbọ́ tí Adolf Hitler wipe Ilẹ̀-ọba Mímọ́ ti Romu, tí ó jẹ́ ilẹ̀-ọba ti Germany, ni a gbọdọ tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀.” Ṣugbọn òpìtàn William L. Shirer ṣàpèjúwe àbájáde naa: “Hitler ṣògo pe Ìjọba Germany Kẹta eyi tí a bí ní January 30, 1933, yoo wapẹtiti fun ẹgbẹ̀rún ọdun, ati ní ede isọrọ Nazi a tọ́kasí i níye-ìgbà gẹgẹbi ‘Ìjọba Germany Ẹlẹgbẹrun Ọdun.’ Ó wà fun ọdun mejila ati oṣu mẹrin.”
Ní Ṣíṣàtúnyẹ̀wò:
◻ Ìṣẹ́gun aláyọ̀ wo lori ẹtanu ẹya iran ni a ri lonii?
◻ Kinni ó mú awọn ènìyàn Ọlọrun igbaani kọrin kí wọn sì ho fun ayọ̀?
◻ Bawo ni ayọ̀ tootọ ṣe pọ̀síi ní awọn àkókò òde-òní?
◻ Bawo ni ìfaradà ati ayọ̀ ṣe nlọ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́?
◻ Ní ọ̀nà wo ni awa lè gbà ti ayọ̀ wa lẹ́hìn dúró?