ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 1/15 ojú ìwé 10-15
  • Ìdùnnú-Ayọ̀ Jehofa Ni Odi-Agbára Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdùnnú-Ayọ̀ Jehofa Ni Odi-Agbára Wa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìdùnnú-Ayọ̀ Ṣáá”
  • Ipò-Ìbátan Pẹ̀lú Ọlọrun Nípasẹ̀ Kristi
  • Òmìnira Ìsìn àti Ìlàlóye
  • Ìrètí Ìjọba àti Ìyè Ayérayé
  • Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Tí A Bùkún
  • Ìgbésí-Ayé Tí Ó Ní Ète Nínú
  • Odi-Agbára Tí Kì í Yẹ̀
  • Ṣiṣẹ́sin Jehofa Pẹ̀lú Ìdùnnú-Ayọ̀ Ọkàn-Àyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ominira Ti Ọlọrun Fi Funni Ń mú Ayọ Wá
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìdùnnú​—Ànímọ́ Rere Tí Ọlọ́run Ń Fúnni
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Ìdùnnú Jèhófà
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 1/15 ojú ìwé 10-15

Ìdùnnú-Ayọ̀ Jehofa Ni Odi-Agbára Wa

“Mímọ́ ni ọjọ́ yìí fún Oluwa wa, ẹ má ṣe kẹ́dùn, nítorí ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa ni odi-agbára yín.”—NEHEMIAH 8:10, NW.

1, 2. (a) Kí ni odi-agbára? (b) Báwo ni Dafidi ṣe fihàn pé òun sá di Jehofa?

JEHOFA jẹ́ odi-agbára tí kò ní àfiwé. Kí sì ni odi-agbára? Ó jẹ́ ibi tí a mọdi sí, ibi àìléwu tàbí ibi tí a ti lè máa wàláàyè nìṣó. Dafidi ti Israeli ìgbàanì ka Ọlọrun sí odi-agbára rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, gbé orin tí Dafidi darí rẹ̀ sí Ẹni Gíga Jùlọ yẹ̀wò “ní ọjọ́ tí Oluwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀, àti lọ́wọ́ Saulu,” ọba Israeli.—Orin Dafidi 18, àkọlé.

2 Dafidi bẹ̀rẹ̀ orin arùmọ̀lára sókè yẹn pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Èmi ó fẹ́ ọ, Oluwa, agbára mi. Oluwa ni àpáta mi, àti [odi-agbára, NW] mi àti olùgbàlà mi: Ọlọrun mi, agbára mi, èmi ó gbẹ́kẹ̀lé e; asà mi, àti ìwo ìgbàlà mi, àti ilé-ìṣọ́ gíga mi.” (Orin Dafidi 18:1, 2) Nígbà tí Ọba Saulu lépa rẹ̀ tí ó sì fi àǹfààní àti ìdábòòbò ti òfin dù ú, Dafidi adúróṣinṣin sá di Jehofa, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣe lè sá wọ inú ibì kan tí a mọdi sí láti lè la àwọn àjálù já.

3. Èéṣe tí àwọn Júù ọjọ́ Esra fi ní ìrírí “yíyọ ayọ̀ ńlá”?

3 Ìdùnnú-ayọ̀ tí Jehofa ń fúnni jẹ́ odi-agbára tí kì í yẹ̀ fún àwọn wọnnì tí ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwàtítọ́ mọ́. (Owe 2:6-8; 10:29) Àmọ́ ṣáá o, láti lè ní ìdùnnú-ayọ̀ tí Ọlọrun ń fúnni, àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Lọ́nà yìí, gbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní Jerusalemu ní 468 B.C.E. yẹ̀wò. Esra akọ̀wé àti àwọn mìíràn gbin òye síni lọ́kàn nípa kíka Òfin lọ́nà tí ó ní ìtumọ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n rọ àwọn ènìyàn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn nǹkan ọlọ́ràá kí ẹ sì mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi apákan ìpín ránṣẹ́ sí ẹni tí a kò pèsè ohunkóhun fún; nítorí pé mímọ́ ni ọjọ́ yìí fún Oluwa wa, ẹ má si ṣe banújẹ́, nítorí ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa ni odi-agbára yín.” Bí àwọn Júù náà ti ń fi ìmọ̀ tí wọ́n ti jèrè sílò tí wọ́n sì ṣe Àjọ Àgọ́ onídùnnú-ayọ̀, ó yọrísí “yíyọ ayọ̀ ńlá.” (Nehemiah 8:1-12, NW) Àwọn wọnnì tí wọ́n ní ‘ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa gẹ́gẹ́ bí odi-agbára wọn’ ti gba okun fún ìjọsìn àti iṣẹ́-ìsìn rẹ̀. Níwọ̀n bí ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa ti jẹ́ odi-agbára wọn, a níláti retí pé kí àwọn ènìyàn Ọlọrun lónìí jẹ́ onídùnnú-ayọ̀ pẹ̀lú. Nígbà náà, kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí a ní fún ìdùnnú-ayọ̀ ní òde-ìwòyí?

“Ìdùnnú-Ayọ̀ Ṣáá”

4. Kí ni orísun ìdùnnú-ayọ̀ títayọ fún àwọn ènìyàn Jehofa?

4 Ìdí títayọ fún ayọ̀ ni ìpèsè tí Jehofa ń ṣe fún ìpéjọpọ̀. Àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú ìdùnnú-ayọ̀ wá fún wọn lónìí, gan-an gẹ́gẹ́ bí àjọ̀dún ọdọọdún tí àwọn ọmọ Israeli ń ṣe ti mú ìdùnnú-ayọ̀ wá sínú ọkàn-àyà wọn. A sọ fún àwọn ènìyàn Israeli pé: “Ijọ́ méje ni kí ìwọ kí ó fi ṣe àjọ [ti àgọ́] sí OLUWA Ọlọrun rẹ ni ibi tí OLUWA yóò yàn: nítorí ti OLUWA Ọlọrun rẹ yóò bùsí i fún ọ ní gbogbo àsunkún rẹ, àti nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, nítorí náà kí ìwọ kí ó máa ní [ìdùnnú-ayọ̀ ṣáá, NW].” (Deuteronomi 16:13-15) Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n “máa ní ìdùnnú-ayọ̀ ṣáá.” Bákan náà ni ó rí fún àwọn Kristian, nítorí tí aposteli Paulu rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo ninu Oluwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i dájúdájú emi yoo wí pé, Ẹ máa yọ̀!”—Filippi 4:4, NW.

5. (a) Kí ni ìdùnnú-ayọ̀, báwo sì ni àwọn Kristian ṣe ń rí i gbà? (b) Báwo ni a ṣe lè ní ìdùnnú-ayọ̀ láìka àwọn àdánwò sí?

5 Níwọ̀n bí Jehofa ti fẹ́ kí a ní ìdùnnú-ayọ̀, ó ń fún wa ní ìdùnnú-ayọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn èso ẹ̀mí mímọ́ rẹ. (Galatia 5:22, 23) Kí sì ni ìdùnnú-ayọ̀?  Ó jẹ́ èrò-ìmọ̀lára tí ó gbádùnmọ́ni tí ń jẹyọ láti inú ríretí tàbí níní ohun rere. Ìdùnnú-ayọ̀ jẹ́ ipò ayọ̀ tòótọ́, àní ayọ̀ àṣeyọrí pàápàá. Èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun yìí ń mú wa dúró lábẹ́ àdánwò. “Nítorí ìdùnnú-ayọ̀ tí a gbéka iwájú rẹ̀ [Jesu] farada òpó igi oró, ó tẹ́ḿbẹ́lú ìtìjú, ó sì ti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.” (Heberu 12:2, NW) Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ̀wé pé: “Ẹ ka gbogbo rẹ̀ sí ìdùnnú-ayọ̀, ẹ̀yin ará mi, nígbà tí ẹ bá ń bá onírúurú àdánwò pàdé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti mọ̀ nítòótọ́ pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ yín yii tí a ti dánwò ń ṣiṣẹ́ yọrí sí ìfaradà.” Ṣùgbọ́n bí a kò bá mọ ohun tí a lè ṣe nípa àdánwò pàtó kan ńkọ́? Nígbà náà a lè fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà fún ọgbọ́n láti bá a lò. Ṣíṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n ti ọ̀run ń ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú àwọn ìṣòro tàbí láti kojú àwọn àdánwò tí ń bá a nìṣó láì pàdánù ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa.—Jakọbu 1:2-8, NW.

6. Ipò-ìbátan wo ni ó wà láàárín ìdùnnú-ayọ̀ àti ìjọsìn tòótọ́?

6 Ìdùnnú-ayọ̀ tí Jehofa ń fúnni ń fún wa lókun láti gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Nehemiah àti Esra nìyẹn. Àwọn Júù ìgbà yẹn tí wọ́n ní ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa gẹ́gẹ́ bí odi-agbára wọn ni a fún lókun láti lè mú ire ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀síwájú. Bí wọ́n sì ṣe ń gbé ìjọsìn Jehofa lárugẹ, ìdùnnú-ayọ̀ wọn ń pọ̀ síi. Bákan náà ni ó rí lónìí. Gẹ́gẹ́ bí olùjọ́sìn Jehofa, a ní ìdí fún yíyọ ayọ̀ ńlá. Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a gbé díẹ̀ síi lára ìdí púpọ̀ mìíràn tí a ní fún ìdùnnú-ayọ̀ yẹ̀wò.

Ipò-Ìbátan Pẹ̀lú Ọlọrun Nípasẹ̀ Kristi

7. Níti Jehofa, ìdí wo ni àwọn Kristian ní fún ìdùnnú-ayọ̀?

7 Ipò-ìbátan wa tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa ń mú kí a jẹ́ ènìyàn tí ó láyọ̀ jùlọ lórí ilẹ̀-ayé. Ṣáájú kí a tó di Kristian, a jẹ́ apákan ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn aláìṣòdodo tí ó ‘wà ninu òkùnkùn níti èrò-orí, tí a sì sọ di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọrun.’ (Efesu 4:18, NW) Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé a kò sọ wá di àjèjì sí Jehofa mọ́! Àmọ́ ṣáá o, ó gba ìsapá láti dúró nínú ojúrere rẹ̀. A gbọ́dọ̀ ‘máa bá a lọ ninu ìgbàgbọ́, tí a fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ naa kí a sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin kí a má sì ṣí wa nípò kúrò ninu ìrètí ìhìnrere yẹn.’ (Kolosse 1:21-23, NW) A lè yọ̀ pé Jehofa fà wá súnmọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ Jesu fúnraarẹ̀ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Johannu 6:44, NW) Bí a bá mọrírì ipò-ìbátan wa tí ó ṣeyebíye pẹ̀lú Ọlọrun nípasẹ̀ Kristi nítòótọ́, àwa yóò dènà ohunkóhun tí ó lè bà á jẹ́.

8. Báwo ni Jesu ṣe fikún ipò ìdùnnú-ayọ̀ wa?

8 Ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jesu jẹ́ ohun ńlá kan tí ó lè fa ìdùnnú-ayọ̀ nítorí pé èyí ni ohun tí ó mú kí ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Ọlọrun ṣeé ṣe. Nípa ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó mọ̀ọ́mọ̀ tọ̀, Adamu babańlá wa mú ikú wá sórí gbogbo aráyé. Bí ó ti wù kí ó rí, aposteli Paulu ṣàlàyé pé: “Ṣugbọn Ọlọrun dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa níti pé, nígbà tí awa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” Paulu tún kọ̀wé pé: “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ aṣemáṣe kan ìyọrísí naa fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ ìdálẹ́bi, bákan naa pẹlu ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìṣe ìdáláre kan ìyọrísí naa fún onírúurú ènìyàn gbogbo jẹ́ pípolongo wọn ní olódodo fún ìyè. Nitori gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan naa pẹlu ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a óò sọ di olódodo.” (Romu 5:8, 18, 19, NW) Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí a ní ìdùnnú-ayọ̀ tó pé ó tẹ́ Jehofa Ọlọrun lọ́rùn láti ra àwọn àtọmọdọ́mọ Adamu tí wọ́n bá lo irú ìpèsè onífẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀ padà!

Òmìnira Ìsìn àti Ìlàlóye

9. Lójú ìwòye ti ìsìn èéṣe tí a fi jẹ́ onídùnnú-ayọ̀?

9 Òmìnira kúrò nínú Babiloni Ńlá, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé, jẹ́ ìdí mìíràn láti ní ìdùnnú-ayọ̀. Òtítọ́ àtọ̀runwá ni ó tú wa sílẹ̀ lómìnira. (Johannu 8:32) Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìsìn kárùwà yìí sì túmọ̀ sí pé a kò lọ́wọ́ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a kò ní ìrírí àwọn ìyọnu rẹ̀, kí a sì parí rẹ̀ sí ìparun pẹ̀lú rẹ̀. (Ìṣípayá 18:1-8) Kò sí ohun ìbànújẹ́ kankan nínú mímóríbọ́ kúrò nínú gbogbo ìyẹn!

10. Ìlàlóye wo ni a ń gbádùn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jehofa?

10 Lílóye àti fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé jẹ́ okùnfà fún yíyọ ayọ̀ ńlá. Bí a ti wà lómìnira kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí ìsìn, a ń gbádùn òye-inú tí ó túbọ̀ ń mọ́gaara síi nípa tẹ̀mí èyí tí Bàbá wa ọ̀run ń pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọgbọ́n-inú ẹru.” (Matteu 24:45-47, NW) Nínú gbogbo ènìyàn tí ń gbé lórí ilẹ̀-ayé, kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gedegbe fún Jehofa ni wọ́n ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti òye tí ń pèsè ìtẹ́lọ́rùn tí ó jẹ́ ti Ọ̀rọ̀ àti ìfẹ́-inú rẹ̀. Bí Paulu ṣe sọ ni ó rí: “Nitori awa ni Ọlọrun ti ṣí wọn [àwọn ohun tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀] payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, nitori ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní awọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun pàápàá.” (1 Korinti 2:9, 10, NW) A lè kún fún ọpẹ́ kí a sì kún fún ìdùnnú-ayọ̀ pé a ń gbádùn òye tí ń tẹ̀síwájú síi èyí tí a mẹ́nukàn nínú ọ̀rọ̀ ìwé Owe 4:18 pé: “Ipa-ọ̀nà àwọn olóòótọ́ dàbí títàn ìmọ́lẹ̀, tí ó ń tàn síwájú àti síwájú títí di ọ̀sángangan.”

Ìrètí Ìjọba àti Ìyè Ayérayé

11. Báwo ni a ti ṣe ṣàjọpín ìrètí Ìjọba onídùnnú-ayọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?

11 Ìrètí Ìjọba wa ń mú wa ní ìdùnnú-ayọ̀ pẹ̀lú. (Matteu 6:9, 10) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa, a ti ń pòkìkí tipẹ́tipẹ́ pé Ìjọba Ọlọrun ní ìrètí kanṣoṣo fún gbogbo aráyé. Fún àpẹẹrẹ, gbé ọdún 1931 yẹ̀wò, nígbà tí a tẹ́wọ́gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa nípa ìgbèròpinnu tí a fi tìdùnnú-ayọ̀ tìdùnnú-ayọ̀ tẹ́wọ́gbà ní gbangba ní àwọn àpéjọpọ̀ 51 káàkiri ayé. (Isaiah 43:10-12) Ìgbèròpinnu yẹn àti ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ tí ó ṣe pàtàkì tí J. F. Rutherford (ààrẹ Watch Tower Society nígbà náà) sọ ni a tẹ̀jáde nínú ìwé-pẹlẹbẹ náà The Kingdom, the Hope of the World. A tún fi ìgbèròpinnu mìíràn tí a tẹ́wọ́gbà ní àpéjọpọ̀ yẹn pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan tí ń fẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan Kristẹndọm fún ìpẹ̀yìndà rẹ̀ àti fún fífojú tẹ́ḿbẹ́lú ìmọ̀ràn Jehofa. Ó tún pòkìkí pé: “Ìjọba Ọlọrun ni ìrètí aráyé, kò sì sí ìrètí mìíràn.” Láàárín oṣù díẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti pín ẹ̀dà ìwé-pẹlẹbẹ yìí tí ó lé ní million márùn-ún ní gbogbo apá ilẹ̀-ayé. Láti ìgbà náà wá a ti ń fi ìgbà gbogbo tẹnumọ́ ọn pé Ìjọba náà ni ìrètí kanṣoṣo fún aráyé.

12. Ìfojúsọ́nà fún ìyè tí ń múni kún fún ìdùnnú-ayọ̀ wo ni a gbé ka iwájú àwọn wọnnì tí ń ṣiṣẹ́sin Jehofa?

12 Àwa pẹ̀lú kún fún ayọ̀, nítorí ìfojúsọ́nà ti ìyè ayérayé lábẹ́ àkóso Ìjọba. “Agbo kékeré” ti àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní ìrètí ti ọ̀run tí ń fún wọn ní ìdùnnú-ayọ̀. Aposteli Peteru kọ̀wé pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọrun ati Baba Oluwa wa Jesu Kristi, nitori ní ìbámu pẹlu àánú ńlá rẹ̀ ó fún wa ní ìbí titun kan sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jesu Kristi kúrò ninu òkú, sí ogún kan tí ó jẹ́ aláìlèdíbàjẹ́ ati aláìlẹ́gbin ati aláìlèṣá. A fi í pamọ́ ní awọn ọ̀run de ẹ̀yin.” (Luku 12:32, NW; 1 Peteru 1:3, 4, NW) Lónìí, ọ̀pọ̀ jaburata lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fojúsọ́nà fún ìyè àìnípẹ̀kun nínú Paradise láàárín ilẹ̀-àkóso Ìjọba náà. (Luku 23:43, Johannu 17:3) Kò sí àwọn ènìyàn mìíràn lórí ilẹ̀-ayé tí wọ́n ní ohunkóhun tí a lè fiwé ìfojúsọ́nà wa tí ń mú ìdùnnú-ayọ̀ wá. Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí a ṣìkẹ́ rẹ̀ tó!

Ẹgbẹ́-Àwọn-Ará Tí A Bùkún

13. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo ẹgbẹ́-àwọn-ará wa jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè?

13 Jíjẹ́ apákan kìkì ẹgbẹ́-àwọn-ará jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun tẹ́wọ́gbà tún jẹ́ orísun mìíràn fún ìdùnnú-ayọ̀ ńlá. Ó múniláyọ̀ pé, a ní àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ fífanilọ́kàn mọ́ra jùlọ lórí ilẹ̀-ayé. Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀ tọ́ka sí ọjọ́ wa ó sì sọ pé: “Èmi ó sì mi gbogbo orílẹ̀-èdè jìgìjìgì, àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra ti gbogbo orílẹ̀-èdè sì gbọ́dọ̀ wọlé; èmi ó sì fi ògo kún ilé yìí.” (Haggai 2:7, NW) Òtítọ́ ni pé, gbogbo Kristian jẹ́ aláìpé. Bí ó ti wù kí ó rí, Jehofa ti fa irú àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ mọ́ra nípasẹ̀ Jesu Kristi. (Johannu 14:6) Níwọ̀n bí Jehofa ti fa àwọn ènìyàn tí òun kà sí ẹni fífanilọ́kànmọ́ra mọ́ ara rẹ̀, ìdùnnú-ayọ̀ wa yóò máa pọ̀ síi bí a bá fi ìfẹ́ ará hàn sí wọn, tí a buyì fún wọn lọ́nà gíga, tí a fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn nínú ìlépa ti oníwà-bí-Ọlọrun, tí a gbé wọn ró nínú àwọn àdánwò wọn, tí a sì gbàdúrà nítorí wọn.

14. Ìṣírí wo ni a lè rí gbà láti inú 1 Peteru 5:5-11?

14 Gbogbo èyí ni yóò fi kún ìdùnnú-ayọ̀ wa. Níti tòótọ́, ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa ni odi-agbára ẹgbẹ́-àwọn-ará wa nípa tẹ̀mí jákèjádò ilẹ̀-ayé. Bẹ́ẹ̀ni, gbogbo wa ni a ń jìyà inúnibíni àti àwọn ipò lílekoko mìíràn. Ṣùgbọ́n èyí níláti so wá papọ̀ kí ó sì mú kí a nímọ̀lára ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí apákan ojúlówó ètò-àjọ kanṣoṣo ti Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé. Gẹ́gẹ́ bí Peteru ti wí, a níláti rẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun, ní kíkó gbogbo àníyàn wa lé e pẹ̀lú ìmọ̀ náà pé òun bìkítà fún wa. A níláti kíyèsára nítorí pé Èṣù ń wá wa láti pa jẹ, ṣùgbọ́n kì í ṣe àwa nìkan, nítorí Peteru fikún un pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in ninu ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé awọn ohun kan naa ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí ninu gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin yín ninu ayé.” Ẹgbẹ́-àwọn-ará onídùnnú-ayọ̀ jákèjádò ayé yìí kì yóò wólulẹ̀ láé, nítorí tí a ní ìdánilójú pé ‘lẹ́yìn tí a bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọrun yóò parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa oun yoo sì fìdí wa múlẹ̀ gbọn-in yoo sì mú wa lókunlágbára.’ (1 Peteru 5:5-11, NW) Ìwọ náà rò ó wò ná. Ẹgbẹ́-àwọn-ará wa onídùnnú-ayọ̀ yóò wà títí láéláé!

Ìgbésí-Ayé Tí Ó Ní Ète Nínú

15. Èéṣe tí a fi lè sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ìgbésí-ayé tí ó ní ète nínú?

15 Ìdùnnú-ayọ̀ jẹ́ tiwa nínú ayé onídààmú yìí nítorí pé a ní ìgbésí-ayé tí ó ní ète nínú. A fi iṣẹ́-òjíṣẹ́ kan lé wa lọ́wọ́ tí ń mú àwa àti àwọn ẹlòmíràn láyọ̀. (Romu 10:10) Dájúdájú àǹfààní tí ń mú ìdùnnú-ayọ̀ wá ni ó jẹ́ láti jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọrun. Níti èyí, Paulu wí pé: “Kí . . . ni Apollo jẹ́? Bẹ́ẹ̀ ni, kí ni Paulu jẹ́? Awọn òjíṣẹ́ tí ẹ tipasẹ̀ wọn di onígbàgbọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti yọ̀ǹda fún olúkúlùkù. Emi gbìn, Apollo bomirin, ṣugbọn Ọlọrun ń mú kí ó máa dàgbà; tí ó fi jẹ́ pé kì í ṣe ẹni tí ń gbìn ni ó jẹ́ nǹkankan tabi ẹni tí ń bomirin, bíkòṣe Ọlọrun tí ń mú kí ó dàgbà. Wàyí o ẹni tí ń gbìn ati ẹni tí ń bomirin jẹ́ ọ̀kan, ṣugbọn ẹni kọ̀ọ̀kan yoo gba èrè-ẹ̀san tirẹ̀ ní ìbámu pẹlu òpò tirẹ̀. Nitori awa jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹlu Ọlọrun. Ẹ̀yin ènìyàn jẹ́ pápá Ọlọrun tí a ń ro lọ́wọ́, ilé Ọlọrun.”—1 Korinti 3:5-9, NW.

16, 17. Àwọn àpẹẹrẹ wo ni a lè rí fàyọ láti fihàn pé àwọn ènìyàn Jehofa ní ìgbésí-ayé onídùnnú-ayọ̀ tí ó ní ète nínú?

16 A lè fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ yọ láti fihàn pé fífi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sin Jehofa ń yọrí sí ìgbésí-ayé tí ó ní ète nínú tí ń fi ìdùnnú-ayọ̀ kún inú wa. Àpẹẹrẹ kan ni gbólóhùn yìí jẹ́: “Mo wò yíká Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó kún fọ́fọ́ [ní ọjọ́ ayẹyẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀] mo sì rí mẹ́jọ lára mẹ́ḿbà ìdílé mi tí wọ́n pésẹ̀ síbẹ̀, títíkan èmi àti aya mi àti mẹ́ta lára àwọn ọmọ wa àti àwọn alábàáṣègbéyàwó wọn. . . . Níti gidi èmi àti aya mi ti ní ìgbésí-ayé aláyọ̀, tí ó ní ète nínú, nínú iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun.”

17 Ó tún múni lọ́kàn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ láti mọ̀ pé ẹnì kan lè dáwọ́lé ìgbésí-ayé tí ó kún fún ète gidi nínú iṣẹ́-ìsìn Jehofa láìka ọjọ́ orí rẹ̀ sí. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan tí ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bibeli ní ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ẹni ọdún 102. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ète onídùnnú-ayọ̀ parí ìgbésí-ayé rẹ̀, ‘ní bíbẹ̀rù Ọlọrun tòótọ́ àti pípa òfin rẹ̀ mọ́.’—Oniwasu 12:13.

Odi-Agbára Tí Kì í Yẹ̀

18. Kí ni a lè ṣe láti borí àìnírètí àti láti mú ìdùnnú-ayọ̀ wa pọ̀ síi?

18 Ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa jẹ́ odi-agbára tí kì í yẹ̀ fún àwọn olùṣòtítọ́. Síbẹ̀, níní ìdùnnú-ayọ̀ yìí kò túmọ̀ sí pé a kò lè ní wákàtí ìbànújẹ́ láé irú èyí tí ó sún Jesu láti sọ ní Getsemane pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, àní títí dé ikú.” (Marku 14:32-34, NW) Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé jíjuwọ́ tí a juwọ́sílẹ̀ fún ìlépa onímọtara-ẹni-nìkan ti yọrí sí ìsọ̀rètínù. Nígbà náà ẹ jẹ́ kí a yí ọ̀nà ìgbésí-ayé wa padà. Bí ìdùnnú-ayọ̀ wa bá ti dínkù nítorí pé a ń gbé àwọn ẹrù-iṣẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu lọ́nà àìmọtara-ẹni-nìkan, bóyá a lè ṣe àtúnṣebọ̀sípò tí yóò mú pákáǹleke wa fúyẹ́ tí yóò sì mú kí a jèrè ẹ̀mí onídùnnú-ayọ̀ wa padà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Jehofa yóò fi ìdùnnú-ayọ̀ bùkún wa bí a bá ń wá ọ̀nà láti ṣe ohun tí ó wù ú nípa fífi tokunra-tokunra gbéjàko ẹran ara ẹlẹ́ṣẹ̀, aye burúkú, àti Èṣù.—Galatia 5:24; 6:14; Jakọbu 4:7.

19. Ojú wo ni ó yẹ kí a fi wo àǹfààní èyíkéyìí tí a bá ní nínú ètò-àjọ Ọlọrun?

19 Fún àwọn ìdí tí a ti jíròrò, àti fún ọ̀pọ̀ ìdí mìíràn, a ní ìdùnnú-ayọ̀ ńlá. Yálà a jẹ́ akéde ìjọ tàbí a ń nípìn-ín nínú irú iṣẹ́-ìsìn alákòókò kíkún kan, gbogbo wa lè ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ Oluwa, ó sì dájú pé èyí yóò fikún ìdùnnú-ayọ̀ wa. (1 Korinti 15:58) Àǹfààní yòówù kí a ní nínú ètò-àjọ Jehofa, ẹ jẹ́ kí a máa ṣọpẹ́ nítorí wọn kí a sì máa fi tìdùnnú-ayọ̀ tìdùnnú-ayọ̀ báa nìṣó láti ṣe iṣẹ́-ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ sí Ọlọrun wa tí ó nífẹ̀ẹ́, tí ó sì jẹ́ aláyọ̀.—1 Timoteu 1:11.

20. Kí ni àǹfààní títóbi jùlọ tí a ní, kí sì ni a lè ní ìdánilójú rẹ̀?

20 Ní pàtàkì jùlọ a ní ìdí láti yọ̀ nínú àǹfààní wa ti jíjẹ́ orúkọ ńlá Jehofa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ni, aláìpé ni wá a sì ń dojúkọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdánwò, ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a máa fi àwọn ìbùkún àgbàyanu wa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jehofa sọ́kàn. Ẹ sì rántí pé, Bàbá wa ọ̀run ọ̀wọ́n kì yóò já wa kulẹ̀ láé. A lè ní ìdánilójú pé a óò máa bùkún wa nígbà gbogbo bí ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa bá jẹ́ odi-agbára wa.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Fèsì?

◻ Kí ni “ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa”?

◻ Báwo ni àwọn Kristian ṣe ń rí ìdùnnú-ayọ̀ tòótọ́ gbà?

◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìdí tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ń ní ìdùnnú-ayọ̀?

◻ Èéṣe tí ìdùnnú-ayọ̀ Jehofa fi jẹ́ odi-agbára tí kì í yẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́