Orin 74
Ìdùnnú Jèhófà
1. Àmì táa ńrí yìí ń kéde ’jọba náà.
A ńsọ ìhìn náà fáráyé.
Ẹ gbórí yín sókè, kẹ́ẹ wo ìgbàlà;
Ìdáǹdè yín kù sí dẹ̀dẹ̀!
(ÈGBÈ)
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Gbóhùn sókè, kọrin ayọ̀.
Yọ̀ nínú ìrètí, dúpẹ́ oore rẹ̀,
Aráyé ẹ yìn ín, ẹ gbée ga.
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Gbogbo èèyàn yóò moókọ rẹ̀.
Aó máa fayọ̀ sin Ọlọ́run Ọba wa,
Pẹ̀lú ìfọkànsìn tí ó pé.
2. Ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ Jèhófà, ẹ máa wòó.
Ẹ má bẹ̀rù, ó lágbára.
Ẹ dìde, ẹ kọrin kó dún bí ààrá;
Orin ayọ̀ sí Ọlọ́run!
(ÈGBÈ)
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Gbóhùn sókè, kọrin ayọ̀.
Yọ̀ nínú ìrètí, dúpẹ́ oore rẹ̀,
Aráyé ẹ yìn ín, ẹ gbée ga.
Ìdùnnú Jèhófà lagbára wa.
Gbogbo èèyàn yóò moókọ rẹ̀.
Aó máa fayọ̀ sin Ọlọ́run Ọba wa,
Pẹ̀lú ìfọkànsìn tí ó pé.
(Tún wo 1 Kíró. 16:27; Sm. 112:4; Lúùkù 21:28; Jòh. 8:32.)