ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/03 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 10/03 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní October 27, 2003. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ September 1 sí ọ̀sẹ̀ October 27, 2003. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Kí ni ìmọ̀ràn tó wà nínú 1 Tímótì 2:9 láti ṣe ara ẹni lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú “aṣọ tí ó wà létòlétò” túmọ̀ sí àti pé báwo lèyí ṣe lè nípa lórí àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe lórí pèpéle tàbí nínú iṣẹ́ ìsìn pápá? [be-YR ojú ìwé 132, ìpínrọ̀ 4 àti 5]

2. Báwo ni àwọn ìlànà Bíbélì tó wà nínú 1 Jòhánù 2:15-17, Éfésù 2:2, àti Róòmù 15:3 ṣe yẹ kó nípa lórí ìrísí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan? [be-YR ojú ìwé 133, ìpínrọ̀ 2 sí 4]

3. Kí nìdí tí ìbàlẹ̀ ọkàn fi ṣe pàtàkì, báwo la ṣe lè di ẹni tí ọkàn rẹ̀ máa ń balẹ̀ nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lórí pèpéle tàbí tó bá wà lóde ẹ̀rí? [be-YR ojú ìwé 135 àpótí; ojú ìwé 136 ìpínrọ̀ 5, àpótí]

4. Gẹ́gẹ́ bí “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́,” báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti lílo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́? (Ìṣí. 3:14) [be-YR ojú ìwé 143 àti 144 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

5. Báwo la ṣe lè túbọ̀ já fáfá sí i ní ti lílo Bíbélì? (Títù 1:9) [be-YR ojú ìwé 144 ìpínrọ̀ 1, àpótí]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Kí ni ohun tí ìkẹ́kọ̀ọ́ ní nínú, kí sì ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé? [be-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 4]

7. Ní ìbámu pẹ̀lú Jákọ́bù 1:5, 6, kí ló pọn dandan nígbà tí a bá dojú kọ ìpinnu tó ṣe pàtàkì? [w01-YR 9/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 4]

8. Kí nìdí tí níní Bíbélì nìkan tàbí kéèyàn sáà ti gbà pé Ọlọ́run mí sí i ò fi tó? [w01-YR 10/1 ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 1]

9. Ní ọ̀nà wo ni ‘ẹni tí ó ń mú ìròyìn búburú wá’ gbà jẹ́ arìndìn? (Òwe 10:18) [w01-YR 9/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3]

10. Kí ni ohun náà gan-an tó máa mú ayé aláyọ̀ wá? [w01-YR 10/15 ojú ìwé 7, ìpínrọ̀ 1 àti 2]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Bẹ́ẹ̀ Kọ́: Nínú 1 Kọ́ríńtì 2:9, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà pèsè sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún fún àwọn ènìyàn rẹ̀ olóòótọ́. Ṣàlàyé. [ip-2-YR, àpótí tó wà ní ojú ìwé 336]

12. Irú àwọn ìdẹwò wo ni ọ̀rọ̀ tí a kọ sílẹ̀ nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13 ń sọ, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń “ṣe ọ̀nà àbájáde”? [w91-YR 10/1 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 11 sí 14]

13. Báwo ni àpẹẹrẹ ìwà ọ̀làwọ́ tí Jésù ní ṣe ń nípa lórí àwa Kristẹni? (2 Kọ́r. 8:9) [w92-YR 1/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 10]

14. Báwo ni Òfin ṣe di ‘akọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi’? (Gál. 3:24) [w02-YR 6/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 11]

15. Kí ni “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé” tí a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ká má bàa di ẹni tí a mú ṣáko lọ? (Kól. 2:8)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́