Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí ẹnì kan bá ti fìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọ̀ ọ́, kí o sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí kò bá sí, a lè lo Iwe Itan Bibeli Mi tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. January: Ìwé èyíkéyìí tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1988 tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Bí ẹ kò bá ní èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí, ẹ béèrè bóyá àwọn ìjọ tó wà nítòsí yín ní ọ̀pọ̀ àwọn ìwé ọlọ́jọ́ pípẹ́ tẹ́ ẹ lè lò. Àwọn ìjọ tí kò bá ní àwọn ìwé tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ lè fi ìwé Mankind’s Search for God lọni.
◼ Àkìbọnú tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí ni “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2004.” Kí ẹ tọ́jú rẹ̀ kí ẹ lè rí i lò jálẹ̀ ọdún 2004.
◼ Bí àwọn àkókò tí ìjọ yín máa ń ṣe ìpàdé yóò bá yí padà ní January 1, kí akọ̀wé ìjọ fi ìyípadà náà tó ẹ̀ka ọ́fíìsì létí nípa fífi fọ́ọ̀mù Congregation Meeting Information and Handbill Request (S-5) ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Bí ẹ bá ń fẹ́ fọ́ọ̀mù yìí tuntun, ẹ lè fi fọ́ọ̀mù ọ̀hún kan náà béèrè fún un. Kí ẹ rí i dájú pé ẹ kọ̀wé béèrè fún fọ́ọ̀mù yìí ní oṣù méjì ó kéré tán, ṣáájú àkókò tí ẹ fẹ́ kó tẹ̀ yín lọ́wọ́.