Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run Ti Ọdún 2004
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 2004, àwọn ètò tó wà nísàlẹ̀ yìí ni a ó tẹ̀ lé bí a bá ń darí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ TÍ A ÓÒ TI YANṢẸ́ FÚNNI: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run [be-YR], Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun [kl-YR] àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé [fy-YR].
Kí á bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ, ká fi orin, àdúrà àti ọ̀rọ̀ ìkínikáàbọ̀ bẹ̀rẹ̀, kí á sì darí rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí:
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn tàbí alàgbà mìíràn tó tóótun yóò sọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan tí a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Láwọn ìjọ tí kò bá sí alàgbà tó pọ̀ tó, kí wọ́n lo ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó tóótun.) Kí ó fi àwọn ọ̀rọ̀ inú àpótí tó wà lójú ìwé tí a ti yanṣẹ́ fún un kún ọ̀rọ̀ náà, àyàfi bí a bá sọ pé kó má ṣe sọ̀rọ̀ lórí àpótí náà. Kí ó fi àwọn ìdánrawò sílẹ̀, kò sí lára apá tí yóò bójú tó. Ìwọ̀nyí wà fún ìlò ara ẹni àti ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó èyí, a ó sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́ tàbí ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí á fi sọ ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́wàá láìsí pé à ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwùjọ. Ète rẹ̀ ni pé ká sọ̀rọ̀ lórí ibi tí a yàn fúnni, lẹ́sẹ̀ kan náà ká sì pàfiyèsí sí ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀, kí olùbánisọ̀rọ̀ sì tẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí ó lò. A retí pé kí àwọn arákùnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún kíyè sára kí wọ́n má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bó bá ṣe yẹ.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTINÚ BÍBÉLÌ KÍKÀ: Ìṣẹ́jú mẹ́wàá. Kí alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tóótun lo ìṣẹ́jú mẹ́fà àkọ́kọ́ láti fi mú ìsọfúnni náà bá àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ mu. Ó lè sọ̀rọ̀ lórí apá èyíkéyìí lára Bíbélì kíkà tí a yàn fún ọ̀sẹ̀ náà. Èyí kò kàn ní jẹ́ ṣíṣe àkópọ̀ ibi tí a yàn fún kíkà lásán. Olórí ète iṣẹ́ yìí ni láti mú kí àwùjọ mọ ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣe pàtàkì àti ọ̀nà tó gbà ṣe pàtàkì fún wọn. Kí olùbánisọ̀rọ̀ kíyè sára kó má bàa kọjá ìṣẹ́jú mẹ́fà tá a yàn fún ọ̀rọ̀ ìṣáájú. Kí ó rí i dájú pé òun ya ìṣẹ́jú mẹ́rin tó ṣẹ́ kù sọ́tọ̀ fún ìlóhùnsí àwùjọ. Kí ó ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ ṣókí (ní ààbọ̀ ìṣẹ́jú tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀) lórí ohun tí wọ́n gbádùn nínú Bíbélì kíkà náà, kí wọ́n sì sọ àǹfààní inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a yàn sí kíláàsì mìíràn máa lọ síbẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́rin. Arákùnrin ni kó bójú tó ìwé kíkà yìí. Bíbélì ni a óò sábà máa kà. Lẹ́ẹ̀kan lóṣù, a óò fa iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí yọ látinú Ilé Ìṣọ́. Kí akẹ́kọ̀ọ́ náà ka ibi tí a yàn fún un láì nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tàbí kó sọ ọ̀rọ̀ ìparí. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ibi tí a óò yàn fúnni láti kà lè gùn tàbí kó kúrú, àmọ́ ìwé kíkà náà kò ní gbà ju ìṣẹ́jú mẹ́rin lọ tàbí kó dín ní ìṣẹ́jú mẹ́rin. Kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa wo iṣẹ́ tó máa yàn fúnni ṣáájú kó tó yàn án fún akẹ́kọ̀ọ́ kan láti ṣe, kí ó jẹ́ kí iṣẹ́ náà bá ọjọ́ orí àti òye akẹ́kọ̀ọ́ náà mu. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti kàwé lọ́nà tó yéni yékéyéké, kí wọ́n sì ní àwọn ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ bíi, jíjẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, títẹnumọ́ ọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ, yíyí ohùn padà nínú ọ̀rọ̀ sísọ, dídánudúró bó ṣe yẹ àti sísọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe dáni.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. A óò yan ìgbékalẹ̀ kan fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí a fún ní iṣẹ́ yìí tàbí kí wọ́n fúnra wọn yan ọ̀kan lára ìgbékalẹ̀ tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ojú ìwé 82 nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kí akẹ́kọ̀ọ́ lo ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un, kí ó sì mú un bá ọ̀nà tá a lè gbà ṣe iṣẹ́ ìsìn pápá ní ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Bí kò bá sí ìwé kankan tá a tọ́ka sí láti gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní láti ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè láti fi kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ. Àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ pé a tọ́ka àwọn ìwé tí a gbé wọn kà ni ká fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ilé ẹ̀kọ́. Ohun tó yẹ kó jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ ni ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ìsọfúnni náà, bó ṣe mú kí onílé ronú lórí Ìwé Mímọ́ àti bó ṣe mú kó lóye àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú iṣẹ́ náà. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún ní láti mọ̀wéé kà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò yan olùrànlọ́wọ́ kan fún akẹ́kọ̀ọ́ náà.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún ni yóò wá àlàyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un. Bí a kò bá tọ́ka sí ìwé kankan tí a gbé iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ yìí kà, akẹ́kọ̀ọ́ yóò ní láti ṣèwádìí nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ olóòótọ́ àti olóye pèsè láti fi kó iṣẹ́ rẹ̀ jọ. Bí a bá yàn án fún arákùnrin, ó lè sọ ọ́ bí àsọyé, kí ó sì darí ọ̀rọ̀ náà sí àwùjọ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bó bá jẹ́ arábìnrin ni yóò bójú tó o, kí ó ṣe é bí àlàyé tí a ṣe nípa Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lè fún arákùnrin kan ní Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin nígbàkigbà tó bá ri pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé, bí a bá sàmì ìràwọ̀ (*) síwájú ẹṣin ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, àwọn arákùnrin ni kí ẹ yàn án fún, kí wọ́n lè sọ ọ́ bí àsọyé.
ÀKÓKÒ: Kí akẹ́kọ̀ọ́ kankan má ṣe kọjá àkókò, kí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ pàápàá tó ń fúnni nímọ̀ràn má ṣe sọ̀rọ̀ kọjá àkókò. Kí á fọgbọ́n dá Akẹ́kọ̀ọ́ Kejì, Ìkẹta àti Ìkẹrin dúró bí àkókò bá ti pé. Bí àwọn arákùnrin tó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́, irú bí ọ̀rọ̀ lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní tàbí àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì kíkà, bá kọjá àkókò tí a yàn fún wọn, kí á fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́. Kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ máa kíyè sí àkókò wọn dáadáa. Iye àkókò tí a ó fi ṣe gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà jẹ́ ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta, láìní orin àti àdúrà nínú.
ÌMỌ̀RÀN: Ìṣẹ́jú kan. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ kò ní lò ju ìṣẹ́jú kan lọ lẹ́yìn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan láti fi sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró nípa àkíyèsí tó ṣe lórí apá dídára kan lára iṣẹ́ náà. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti kàn sọ pé “o ṣe dáadáa,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ láti pàfiyèsí sí àwọn ìdí pàtàkì tí apá tí ó ṣàkíyèsí nínú iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà fi gbéṣẹ́. Níbàámu pẹ̀lú ohun tí a retí látọ̀dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan, a tún lè fúnni ní ìmọ̀ràn tí ń gbéni ró láfikún sí i lẹ́yìn ìpàdé tàbí nígbà mìíràn.
OLÙRÀNLỌ́WỌ́ AGBANI-NÍMỌ̀RÀN: Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà lè yan alàgbà kan tó dáńgájíá, bí ó bá wà, ní àfikún sí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́, láti jẹ́ olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn. Bí àwọn alàgbà bá pọ̀ nínú ìjọ, nígbà náà alàgbà kọ̀ọ̀kan tó tóótun lè máa ṣe iṣẹ́ yìí lọ́dọọdún. Ojúṣe olùrànlọ́wọ́ agbani-nímọ̀ràn ni láti máa fún àwọn arákùnrin tó ń bójú tó Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kìíní àti kókó pàtàkì látinú Bíbélì ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́, bó bá yẹ bẹ́ẹ̀. Kò pọn dandan kó máa fúnni nímọ̀ràn ní gbogbo ìgbà táwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ bá ṣe iṣẹ́ yìí. Ìṣètò yìí ni a ó tẹ̀ lé ní ọdún 2004, ó sì lè yí padà bó bá yá.
ÌWÉ ÌMỌ̀RÀN Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ: Èyí wà nínú ìwé tá à ń lò fún Ilé Ẹ̀kọ́ náà.
ÀTÚNYẸ̀WÒ ALÁFẸNUSỌ: Ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Ní oṣù méjì-méjì, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ṣáájú èyí, ìjíròrò lórí ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ kan àti àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ lókè ni yóò kọ́kọ́ wáyé. A óò gbé àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ yìí ka àwọn ohun tí a ti jíròrò nínú ilé ẹ̀kọ́ láàárín oṣù méjì tó ṣáájú, títí kan ti ọ̀sẹ̀ tí àtúnyẹ̀wò náà wáyé.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 5 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 1 sí 5 Orin 154
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò (be-YR ojú ìwé 157 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 1: Ṣíṣe Ìlapa Èrò (be-YR ojú ìwé 39 sí 42)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 2:7-25
No. 3: Bí Jèhófà Ṣe Ń Pèsè Oúnjẹ Tẹ̀mí (kl-YR ojú ìwé 162 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 8)
No. 4: aOhun Tí A Lè Kọ́ Látinú Àwọn Àpẹẹrẹ Inú Bíbélì Nípa Ohun Tó Tọ́ Láti Ṣe Tí Àìkò Ṣe É sì Jẹ́ Ẹsẹ
Jan. 12 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 6 sí 10 Orin 215
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Sọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Ṣeé Mú Lò (be-YR ojú ìwé 158 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ìmọ́tótó—Kí Ló Túmọ̀ Sí Gan-an? (w02-YR 2/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 8:1-17
No. 3: Ìdí Tí Irọ́ Pípa Fi Burú
No. 4: Ohun Tí Fífi Ìfẹ́ Wọ Ara Wa Láṣọ Túmọ̀ Sí (kl-YR ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 166 ìpínrọ̀ 14)
Jan. 19 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 11 sí 16 Orin 218
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Jíjẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Bí Ọ̀rọ̀ Náà Ṣe Wúlò (be-YR ojú ìwé 159 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Àwọn Ìlànà Ọlọ́run Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní (w02-YR 2/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 13:1-18
No. 3: Ìjọ Jẹ́ Ibi Ààbò (kl-YR ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 169 ìpínrọ̀ 20)
No. 4: Ìdí Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Sọ Ìrètí Wa Fáwọn Èèyàn
Jan. 26 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 17 sí 20 Orin 106
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Èdè Tó Dára (be-YR ojú ìwé 160 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú (w02-YR 4/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: w02-YR 1/1 ojú ìwé 10 àti 11 ìpínrọ̀ 9 sí 11
No. 3: Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Jésù Tó Wà Nínú Lúùkù 13:24 Túmọ̀ Sí
No. 4: Fara Wé Jésù—Sin Ọlọ́run Títí Láé (kl-YR ojú ìwé 170 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 6)
Feb. 2 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 21 sí 24 Orin 64
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Èdè Tó Ń Tètè Yéni (be-YR ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Bí Akẹ́kọ̀ọ́ Ṣe Lè Múra Iṣẹ́ Ilé Ẹ̀kọ́ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 43 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 21:1-21
No. 3: Àwọn Ìgbésẹ̀ Pàtàkì Tó Ń Sinni Lọ Sí Ìyè (kl-YR ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 9)
No. 4: bÌdí Tó Fi Yẹ Ká Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Ọ̀ràn Ìfẹ́sọ́nà
Feb. 9 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 25 sí 28 Orin 9
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Oríṣiríṣi Ọ̀rọ̀ Tó Bá A Mu Rẹ́gí (be-YR ojú ìwé 161 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 162 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Mímúra Iṣẹ́ Tó Ní Ẹṣin Ọ̀rọ̀ àti Ìgbékalẹ̀ (be-YR ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 46 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 28:1-15
No. 3: Bí A Ṣe Lè Rí Ìbàlẹ̀ Ọkàn Nínú Ayé Oníwàhálà Yìí
No. 4: Ìdí Tí Batisí Fi Pọn Dandan (kl-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 176 ìpínrọ̀ 12)
Feb. 16 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29 sí 31 Orin 160
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọ̀rọ̀ Tó Ń Tani Jí, Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Hàn àti Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé (be-YR ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Ìwà Títọ́ Ń Ṣamọ̀nà Àwọn Adúróṣánṣán (w02-YR 5/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: w02-YR 2/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 10
No. 3: Batisí—Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìgbésí Ayé Rẹ (kl-YR ojú ìwé 176 ìpínrọ̀ 13 sí ojú ìwé 177 ìpínrọ̀ 16)
No. 4: Ìdí Tí Ìwà Rere Fi Jẹ́ Ànímọ́ Tó Ṣe Pàtàkì fún Àwọn Kristẹni
Feb. 23 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 32 sí 35 Orin 1
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Bá Òfin Gírámà Èdè Mu (be-YR ojú ìwé 164 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 165 ìpínrọ̀ 1)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Mar. 1 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 36 sí 39 Orin 49
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ìlapa Èrò (be-YR ojú ìwé 166 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Mímúra Ọ̀rọ̀ Tó O Máa Sọ fún Ìjọ Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 47 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 37:12 sí 28
No. 3: Èé Ṣe Tí Ìfaradà Fi Gbọ́dọ̀ Bá Ìgbàgbọ́ Wa Rìn?
No. 4: Ohun Tó Túmọ̀ Sí Láti Gbé Níbàámu Pẹ̀lú Ìyàsímímọ́ àti Batisí Rẹ (kl-YR ojú ìwé 178 ìpínrọ̀ 17 sí ojú ìwé 180 ìpínrọ̀ 22)
Mar. 8 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 40 sí 42 Orin 205
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Títo Èrò Rẹ Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 3 si ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Mímúra Apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Àwọn Ọ̀rọ̀ Mìíràn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 42:1-20
No. 3: Bí A Ṣe Lè Ní Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà
No. 4: Mímúra Sílẹ̀ Nísinsìnyí De “Iyè Tòótọ́ Gidi” (kl-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 182 ìpínrọ̀ 5)
Mar. 15 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 43 sí 46 Orin 67
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ìlapa Èrò Rẹ Lọ́jú Pọ̀ (be-YR ojú ìwé 168 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 169 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Ìgbà Wo Ni Jèhófà Máa Ń Bù Kún Ìsapá Tí A Fi Taratara Ṣe? (w02-YR 8/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 43:1-18
No. 3: Lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì—Párádísè Ilẹ̀-Ayé Kan (kl-YR ojú ìwé 182 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 11)
No. 4: Báwo La Ṣe Lè Fi Ọrọ̀ Àìṣòdodo Yan Ọ̀rẹ́?
Mar. 22 Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 47 sí 50 Orin 187
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 170 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Tẹ́wọ́ Gba Ẹbọ Ébẹ́lì Tí Kò Tẹ́wọ́ Gba Ẹbọ Kéènì? (w02-YR 8/1 ojú ìwé 28)
No. 2: Jẹ́nẹ́sísì 47:1-17
No. 3: Àlááfíà Níbi Gbogbo àti Àjíǹde Àwọn Òkú (kl-YR ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Ìdí Tó Fi Jẹ́ Pé Ìbẹ̀rù Jèhófà Ni Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ọgbọ́n
Mar. 29 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 1 sí 6 Orin 52
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Lẹ́sẹẹsẹ (be-YR ojú ìwé 171 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 172 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Báwo Ní Agbára Láti Ronú Ṣe Lè Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ọ? (w02-YR 8/15 ojú ìwé 21 sí 24)
No. 2: w02-YR 2/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 11
No. 3: Ojú Tí Jèhófà Fi Wo Ìgbéraga
No. 4: Ohun Tí Ìjẹ́pípé Yóò Túmọ̀ Sí àti Bí A Ṣe Lè Gbádùn Rẹ̀ (kl-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 191 ìpínrọ̀ 25)
Apr. 5 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 7 sí 10 Orin 61
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Kìkì Ọ̀rọ̀ Tí Ó Bá Yẹ Nìkan Ni Kí O Lò (be-YR ojú ìwé 173 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Mímúra Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn Sílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Ẹ́kísódù 8:1-19
No. 3: Ìdílé Wà Nínú Yánpọnyánrin (fy-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 14)
No. 4: Ìdí Tí Ìrètí Fi Dà Bí “Ìdákọ̀ró fún Ọkàn”
Apr. 12 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 11 sí 14 Orin 87
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 174 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Àwọn Ìpinnu Tí Alásọyé Yóò Ṣe (be-YR ojú ìwé 54 ìpínrọ̀ 2 sí 4 àti àpótí ojú ìwé 55)
No. 2: Ẹ́kísódù 12:1-16
No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Gba Ìbáwí Tí Jèhófà fún Wa?
No. 4: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 23)
Apr. 19 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 15 sí 18 Orin 171
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yàgò fún Àwọn Ọ̀fìn Tó Wà Nínú Sísọ̀rọ̀ Láìgbáralé Àkọsílẹ̀ (be-YR ojú ìwé 175 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 177 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Irú Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àdánwò? (w02-YR 9/1 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: w02-YR 3/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 11
No. 3: Ǹjẹ́ O Ti Ṣe Tán Láti Ṣègbéyàwó? (fy-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: cÌdí Tó Fi Yẹ Kí Ìgbéyàwó Wà Pẹ́ Títí
Apr. 26 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 19 sí 22 Orin 59
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Nígbà Tí Àwọn Èèyàn Bá Ní Ká Ṣàlàyé Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 177 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 178 ìpínrọ̀ 3)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
May 3 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 23 sí 26 Orin 13
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ̀rọ̀ Bí Ẹní Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ (be-YR ojú ìwé 179 àti 180)
No. 1: Kọ́ Bí A Ṣe Ń Jẹ́ Olùkọ́ Tó Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 56 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Ẹ́kísódù 23:1-17
No. 3: Báwo Ni Jèhófà Ṣe Lè Ran Ẹnì Kan Lọ́wọ́ Láti Jáwọ́ Nínú Àṣà Tí Kò Dára?
No. 4: Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Mọ Ara Rẹ, Kó O Má sì Tan Ara Rẹ Jẹ (fy-YR ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10)
May 10 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 27 sí 29 Orin 28
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìró Ohùn (be-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: “Fi Ìyàtọ̀” Hàn (be-YR ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Ẹ́kísódù 28:29-43
No. 3: Àwọn Ànímọ́ Tó Yẹ Kí Ó Wà Lára Alábàáṣègbéyàwó Kan (fy-YR ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 11 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 15)
No. 4: Ìdí Tí Kò Fi Dára Ká Ní Ẹ̀mí Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà
May 17 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 30 sí 33 Orin 93
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Darí Afẹ́fẹ́ Tí Ò Ń Mí Sínú Sóde Bó Ṣe Tọ́ (be-YR ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 1 àti àpótí ojú ìwé 182)
No. 1: Mú Kí Àwọn Olùgbọ́ Rẹ Ronú (be-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Ẹ́kísódù 30:1-21
No. 3: Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Oníwà Tútù?
No. 4: Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Gbé Yẹ̀ Wò Ṣáájú Ká Tó Wọnú Àdéhùn Tó Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 16 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 19)
May 24 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 34 sí 37 Orin 86
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Dẹ Àwọn Iṣan Tó Le (be-YR ojú ìwé 184 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 185 ìpínrọ̀ 2 àti àpótí ojú ìwé 184)
No. 1: Sọ Bí Wọ́n Ṣe Lè Lò Ó, Kí O sì Fi Àpẹẹrẹ Lélẹ̀ (be-YR ojú ìwé 60 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Ẹ́kísódù 36:1-18
No. 3: Ẹ Jẹ́ Kí Ìfẹ́sọ́nà Yín Lọ́lá, Kí Ẹ sì Wò Ré Kọjá Ọjọ́ Ìgbéyàwó (fy-YR ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 23)
No. 4: Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Olóòótọ́ Nínú Àwọn Ọ̀ràn Tó Kéré?
May 31 Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 38 sí 40 Orin 202
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé Ire Àwọn Ẹlòmíràn Ń Jẹ Ọ́ Lógún (be-YR ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I (be-YR ojú ìwé 62 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: w02-YR 5/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 6
No. 3: Báwo Ní Lílóye Ọ̀rọ̀ Inú 1 Jòhánù 3:19, 20 Ṣe Lè Tu Ẹnì Kan Nínú?
No. 4: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Ran Ọ̀ Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí (fy-YR ojú ìwé 26, àpótí àtúnyẹ̀wò)
June 7 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 1 sí 5 Orin 123
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Tẹ́tí Sílẹ̀ Bẹ̀lẹ̀jẹ́ (be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 1: Bí A Ṣe Lè Máa Bá Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ Lọ (be-YR ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 65 ìpínrọ̀ 4)
No. 2: Léfítíkù 3:1-17
No. 3: Kọ́kọ́rọ́ Àkọ́kọ́ sí Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: Kí Ló Burú Nínú Ìbẹ́mìílò?
June 14 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 6 sí 9 Orin 121
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú (be-YR ojú ìwé 187 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Fòye Mọ Èrò Ọkàn Ẹni Tó Béèrè Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 66 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 68 ìpínrọ̀ 1)
No. 2: Léfítíkù 7:1-19
No. 3: Báwo La Ṣe Lè Kọ́ Bí A Óò Ṣe Kórìíra Ohun Búburú?
No. 4: Kọ́kọ́rọ́ Kejì sí Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 10)
June 21 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 10 sí 13 Orin 183
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣèrànwọ́ fún Wọn Nípa Ti Ara (be-YR ojú ìwé 188 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 189 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Mọ Bí Ó Ṣe Yẹ Kí O Dáhùn (be-YR ojú ìwé 68 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 70 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Léfítíkù 11:1-25
No. 3: Ipò Orí Ọkùnrin Gbọ́dọ̀ Dà Bíi Ti Kristi (fy-YR ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 11 sí ojú ìwé 33 ìpínrọ̀ 15)
No. 4: Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Rírẹ́ni Jẹ àti Jíjíwèé Wò
June 28 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 14 sí 16 Orin 216
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bíbọ̀wọ̀fúnni (be-YR ojú ìwé 190 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 191 ìpínrọ̀ 1)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
July 5 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 17 sí 20 Orin 54
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Yíyẹ́nisí (be-YR ojú ìwé 191 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Fífi Lẹ́tà Báni Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 71 sí 73)
No. 2: Léfítíkù 17:1-16
No. 3: Gbẹ́kẹ̀ Lé Ètò Àjọ Jèhófà
No. 4: Bí Aya Ṣe Lè Jẹ́ Àṣekún fún Ọkọ Rẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 34 ìpínrọ̀ 16 sí ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 19)
July 12 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 21 sí 24 Orin 138
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Bá Àwùjọ Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 193 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Máa Tẹ̀ Síwájú (be-YR ojú ìwé 74 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 3)
No. 2: Léfítíkù 22:1-16
No. 3: Ohun Tí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Tó Dán Mọ́rán Túmọ̀ Sí Ní Ti Gidi (fy-YR ojú ìwé 35 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 38 ìpínrọ̀ 26)
No. 4: Ṣé Ọlọ́run Ẹ̀yà Júù Ni Jèhófà?
July 19 Bíbélì kíkà: Léfítíkù 25 sí 27 Orin 7
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Fífi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 194 ìpínrọ̀ 1 ojú ìwé 195 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Lo Ẹ̀bùn Rẹ (be-YR ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 77 ìpínrọ̀ 2)
No. 2: Léfítíkù 25:1-19
No. 3: Bí Ìpániláyà Yóò Ṣe Dópin
No. 4: Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Lè Mú Kó O Gbádùn Ìgbéyàwó Aláyọ̀, Tó Wà Pẹ́ Títí (fy-YR ojú ìwé 38, àpótí àtúnyẹ̀wò)
July 26 Bíbélì kíkà: Númérì 1 sí 3 Orin 30
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Dáni Lójú (be-YR ojú ìwé 195 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 196 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Jowú? (w02-YR 10/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: w02-YR 6/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 9
No. 3: Ṣe Bí O Ti Mọ (fy-YR ojú ìwé 39 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 41 ìpínrọ̀ 6)
No. 4: Ǹjẹ́ Ó Burú Ká Máa Ṣọ̀fọ̀ Àwọn Èèyàn Wa Tó Ti Kú?
Aug. 2 Bíbélì kíkà: Númérì 4 sí 6 Orin 128
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lo Ọgbọ́n Inú Síbẹ̀ Dúró Lórí Òtítọ́ (be-YR ojú ìwé 197 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Báwo La Ṣe Lè Lo Ìgbésí Ayé Wa Lọ́nà Tí Inú Jèhófà Dùn Sí (w02-YR 11/15 ojú ìwé 20 sí 23)
No. 2: Númérì 6:1-17
No. 3: Báwo Ni Bíbélì Ṣe Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Má Ṣe Máa Kórìíra Ara Wọn Mọ́?
No. 4: Iṣẹ́ Ìtọ́jú Ilé Jẹ́ Ojúṣe Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 42 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 44 ìpínrọ̀ 11)
Aug. 9 Bíbélì kíkà: Númérì 7 sí 9 Orin 35
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tí A Bá Ń Wàásù (be-YR ojú ìwé 197 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Ǹjẹ́ Ìwà Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ Lè Tán Láé? (w02-YR 1/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Númérì 8:1-19
No. 3: Ìdí Tí Jèhófà Fi Béèrè Pé Ká Wà Ní Mímọ́ Tónítóní (fy-YR ojú ìwé 45 ìpínrọ̀ 12 sí ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 20)
No. 4: Ta Ni Aṣòdì sí Kristi?
Aug. 16 Bíbélì kíkà: Númérì 10 sí 13 Orin 203
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Ọ̀rọ̀ Tó Yẹ ní Àkókò Tí Ó Tọ́ (be-YR ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Gbẹ́kẹ̀ Lè Jèhófà—Ọlọ́run Tó Jẹ́ Ẹni Gidi (w02-YR 1/15 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: Númérì 12:1-16
No. 3: Bí Ọlọ́run Bá Gbẹ̀san, Ǹjẹ́ Ó Ta Ko Jíjẹ́ Tó Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́?
No. 4: Ipa Tí Ìgbóríyìn àti Ìmoore Lè Kó Nínú Ìdílé (fy-YR ojú ìwé 49 ìpínrọ̀ 21 sí ojú ìwé 50 ìpínrọ̀ 22)
Aug. 23 Bíbélì kíkà: Númérì 14 sí 16 Orin 207
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ọgbọ́n Inú Nígbà Tí A Bá Wà Pẹ̀lú Ìdílé Wa Àtàwọn Mìíràn (be-YR ojú ìwé 200 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 201 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Àwọn Ọmọ Ìyá Kan Náà Tí Ìwà Wọ́n Yàtọ̀ Síra (w02-YR 1/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: w02-YR 7/15 ojú ìwé 23 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 19
No. 3: Ojú Tí Bíbélì Fi Wo Àwọn Ọmọ àti Ojúṣe Òbí (fy-YR ojú ìwé 51 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 52 ìpínrọ̀ 5)
No. 4: dÌdí Tí Àwa Kristẹni Fi Kórìíra Ìwà Ipá
Aug. 30 Bíbélì kíkà: Númérì 17 sí 21 Orin 150
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sọ Ohun Tó Ń Gbéni Ró Tó sì Ṣàǹfààní (be-YR ojú ìwé 202 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 2)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Sept. 6 Bíbélì kíkà: Númérì 22 sí 25 Orin 22
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sọ̀rọ̀ Lọ́nà Tí Wọ́n Yóò Fi Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ (be-YR ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 204 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Kí Nìdí Ti Ayé Ìgbàanì Fi Ṣègbé? (w02-YR 3/1 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: Númérì 22:1-19
No. 3: Ohun Tí Fífún Àwọn Ọmọ Lóhun Tí Wọ́n Nílò Túmọ̀ Sí (fy-YR ojú ìwé 53 ìpínrọ̀ 6 sí ojú ìwé 55 ìpínrọ̀ 9)
No. 4: eÌdí Tó Fi Yẹ Kí Àwọn Òbí Kristẹni Máa Kàwé Sí Àwọn Ọmọ Wọn Létí
Sept. 13 Bíbélì kíkà: Númérì 26 sí 29 Orin 71
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Nígbà Tí A Bá Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa (be-YR ojú ìwé 204 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 205 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Bí Ìṣòro Jíjẹ́ Aláàbọ̀ Ara Kò Ṣe Ní Sí Mọ́ (w02-YR 5/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Númérì 29:1-19
No. 3: Gbin Òtítọ́ Sínú Ọmọ Rẹ (fy-YR ojú ìwé 55 ìpínrọ̀ 10 sí ojú ìwé 57 ìpínrọ̀ 15)
No. 4: Ọ̀nà Wo Làwọn Ìlérí Ọlọ́run Gbà Di Bẹ́ẹ̀ Ni Nípasẹ̀ Jésù Kristi?
Sept. 20 Bíbélì kíkà: Númérì 30 sí 32 Orin 51
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Àsọtúnsọ Láti Tẹnu Mọ́ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 206 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Gbin Òdodo, Kí O sì Ká Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run (w02-YR 7/15 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Númérì 30:1-16
No. 3: Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Àwọn Ọ̀nà Jèhófà (fy-YR ojú ìwé 58 ìpínrọ̀ 16 sí ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 19)
No. 4: fÌdí Tó Fi Yẹ Ká Yẹra fún Àwọn Ohun Tó Ń Rùfẹ́ Ìṣekúṣe Sókè
Sept. 27 Bíbélì kíkà: Númérì 33 sí 36 Orin 100
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sísọ Àsọtúnsọ Ní Òde Ẹ̀rí àti Nígbà Tí A Bá Ń Sọ Àsọyé (be-YR ojú ìwé 207 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 208 ìpínrọ̀ 3)
No. 1: Báwo Làwọn Ẹni Mímọ́ Tòótọ́ Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́? (w02-YR 9/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: w02-YR 8/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 19
No. 3: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Láti Máa Bá Àwọn Ọmọ Wí Lónírúurú Ọ̀nà (fy-YR ojú ìwé 59 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 23)
No. 4: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Yẹra fun Kíkẹ́ Ara Ẹni Bà Jẹ́
Oct. 4 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 1 sí 3 Orin 191
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣàlàyé Ẹṣin Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 209 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ìmọ̀ Pípéye Nípa Ọlọ́run Ń Tù Wá Nínú (w02-YR 10/1 ojú ìwé 5 sí 7)
No. 2: Diutarónómì 1:1-18
No. 3: Ohun Tí Sísọ Òtítọ́ Di Tìrẹ Túmọ̀ Sí
No. 4: Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ìpalára (fy-YR ojú ìwé 61 ìpínrọ̀ 24 sí ojú ìwé 63 ìpínrọ̀ 28)
Oct. 11 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 4 sí 6 Orin 181
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lílo Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Tó Bá A Mu (be-YR ojú ìwé 210 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 211 ìpínrọ̀ 1 àti àpótí tó wà lójú ìwé 211)
No. 1: Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Nikodémù (w02-YR 2/1 ojú ìwé 8 sí 12)
No. 2: Diutarónómì 4:1-14
No. 3: Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Sí Àyè Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Sílẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 66 ìpínrọ̀ 7)
No. 4: Kí Ló Wé Mọ́ “Gbígbé Èrò Inú Ka Ẹ̀mí”?
Oct. 18 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 7 sí 10 Orin 78
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Mú Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere (be-YR ojú ìwé 212 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 1)
No. 1: Fi Ọkàn àti Èrò Inú Rẹ Wá Ọlọ́run (w02-YR 4/1 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: w02-YR 8/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6
No. 3: Fi Ìjẹ́pàtàkì Ìwà Rere àti Ohun Tẹ̀mí Kọ́ Àwọn Ọmọ (fy-YR ojú ìwé 67 ìpínrọ̀ 8 sí ojú ìwé 70 ìpínrọ̀ 14)
No. 4: gOjú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àwọn Apẹ̀yìndà
Oct. 25 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 11 sí 13 Orin 57
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Má Ṣe Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Rẹ Pọ̀ Jù (be-YR ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 2 si ojú ìwé 214 ìpínrọ̀ 5)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
Nov. 1 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 14 sí 18 Orin 26
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 215 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 216 ìpínrọ̀ 5)
No. 1: Ìṣòro Aráyé Kò Ní Í Pẹ́ Dópin! (w02-YR 6/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Diutarónómì 14:1-23
No. 3: Ìdí Tí Ìbáwí àti Ọ̀wọ̀ Fi Ṣe Pàtàkì (fy-YR ojú ìwé 71 ìpínrọ̀ 15 sí ojú ìwé 72 ìpínrọ̀ 18)
No. 4: Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí Kristẹni Fi Ohun Tí Ò Pọn Dandan Dí Ara Rẹ̀ Lọ́wọ́
Nov. 8 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 19 sí 22 Orin 182
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Bí A Ṣe Lè Gba Àfiyèsí Àwọn Èèyàn Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 217 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Jọ́sìn Ọlọ́run “Ní Ẹ̀mí” (w02-YR 7/1 ojú ìwé 5 sí 8)
No. 2: Diutarónómì 21:1-17
No. 3: Mú Kí Àwọn Ọmọ Mọ Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Iṣẹ́ àti Eré (fy-YR ojú ìwé 72 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 25)
No. 4: Báwo Ní Àpẹẹrẹ Àwọn Èèyàn Inú Bíbélì Ṣe Lè Mú Ká Borí Ìrẹ̀wẹ̀sì?
Nov. 15 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 23 sí 27 Orin 162
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Sọ Kókó Tó O Fẹ́ Sọ̀rọ̀ Lè Lórí Nígbà Tó O Bá Ń Nasẹ̀ Ọ̀rọ̀ (be-YR ojú ìwé 217 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 219 ìpínrọ̀ 2)
No. 1: Rírìn ní Ipa Ọ̀nà Jèhófà Ń Mú Èrè Wá (w02-YR 7/1 ojú ìwé 28 sí 30)
No. 2: Diutarónómì 24:1-16
No. 3: Bá A Ṣe Lè Dá Àwọn Tí Ọlọ́run Wà Lẹ́yìn Wọn Mọ̀
No. 4: Yíya Ọlọ̀tẹ̀ Ọmọ àti Ohun Tó Ń Fà Á (fy-YR ojú ìwé 76 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 79 ìpínrọ̀ 8)
Nov. 22 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 28 sí 31 Orin 32
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko (be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
No. 1: Ṣé Ìgbàgbọ́ Nínú Ohun Asán Ló Ń Darí Ìgbésí Ayé Rẹ? (w02-YR 8/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Diutarónómì 29:1-18
No. 3: Má Ṣe Gbọ̀jẹ̀gẹ́, Má sì Le Koko Jù (fy-YR ojú ìwé 80 ìpínrọ̀ 9 sí ojú ìwé 81 ìpínrọ̀ 13)
No. 4: Ìdí Tí Àwa Kristẹni Fi Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Amẹ̀tọ́mọ̀wà
Nov. 29 Bíbélì kíkà: Diutarónómì 32 sí 34 Orin 41
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Fi Sọ́kàn (be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 4)
No. 1: Ṣé Wàá Pa Ìwà Títọ́ Ẹ Mọ́? (w02-YR 8/15 ojú ìwé 25 sí 28)
No. 2: w02-YR 10/15 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 10 sí 13
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Ya Orúkọ Ọlọ́run Sí Mímọ́
No. 4: Ṣíṣe Àwọn Ohun Pàtàkì Tí Ọmọ Rẹ Nílò Lè Mú Kó Máà Ya Ọlọ̀tẹ̀ (fy-YR ojú ìwé 82 ìpínrọ̀ 14 sí ojú ìwé 84 ìpínrọ̀ 18)
Dec. 6 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 1 sí 5 Orin 40
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Lóde Ẹ̀rí (be-YR ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 222 ìpínrọ̀ 6)
No. 1: Ta Ló Yẹ Kó O Jẹ́ Adúróṣinṣin Sí? (w02-YR 8/15 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jóṣúà 4:1-14
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tí A Lè Gbà Ran Ọmọ Kan Tí Ó Ṣàṣìṣe Lọ́wọ́ (fy-YR ojú ìwé 85 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 87 ìpínrọ̀ 23)
No. 4: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Kristẹni Máa Ṣayẹyẹ Kérésìmesì?
Dec. 13 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 6 sí 8 Orin 213
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ọ̀rọ̀ Tó Jóòótọ́ Délẹ̀ (be-YR ojú ìwé 223 ìpínrọ̀ 1 sí 5)
No. 1: Títọrọ Àforíjì—Ọ̀nà Tó Gbéṣẹ́ Jù Lọ Láti Wá Àlàáfíà (w02-YR 11/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jóṣúà 6:10-23
No. 3: Kí Nìdí Tí A Fi Ń Bá A Lọ Láti Máa Wàásù Láti Ilé Dé Ilé?
No. 4: Bíbá Ọlọ̀tẹ̀ Paraku Lò (fy-YR ojú ìwé 87 ìpínrọ̀ 24 sí ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 27)
Dec. 20 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 9 sí 11 Orin 135
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ẹni Tó “Ń Di Ọ̀rọ̀ Ṣíṣeégbíyèlé Mú Ṣinṣin” (be-YR ojú ìwé 224 ìpínrọ̀ 1 sí 4)
No. 1: Fún Ọwọ́ Rẹ Lókun (w02-YR 12/1 ojú ìwé 30 sí 31)
No. 2: w02-YR 11/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 19 sí ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 23
No. 3: Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́ Agbára Ìdarí Apanirun (fy-YR ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 92 ìpínrọ̀ 7)
No. 4: hOhun Tó Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Ẹni Àlàáfíà
Dec. 27 Bíbélì kíkà: Jóṣúà 12 sí 15 Orin 210
Ànímọ́ Ọ̀rọ̀ Sísọ: Ṣíṣèwádìí Nípa Bí Ìsọfúnni Tó O Rí Ṣe Jóòótọ́ Sí (be-YR ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 1 sí 3)
Àtúnyẹ̀wò Aláfẹnusọ
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
b Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
c Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
d Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
e Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
f Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
g Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.
h Arákùnrin ni kí a yan iṣẹ́ yìí fún.