Jẹ́ Kí Ayọ̀ Tí Ò Ń Ní Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Pọ̀ Sí I
1 Ǹjẹ́ ò ń rí ayọ̀ tó ń wá látinú wíwàásù ìhìn rere nígbà tí o bá ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Bá ò bá ṣọ́ra, ayé búburú tó yí wa ká lè mú ká máa fà sẹ́yìn láti wàásù, ìyẹn á sì mú ká pàdánù ayọ̀ wa. A tún lè rẹ̀wẹ̀sì báwọn èèyàn ò bá fẹ́ fetí sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ wa. Kí làwọn ìgbésẹ̀ tó múná dóko tá a lè gbé láti fi kún ayọ̀ tá à ń ní nínú iṣẹ́ ìwàásù?
2 Ní Èrò Rere Nípa Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Níní èrò rere nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe èyí ni nípa ríronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ tá a ní láti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 3:9) Bákan náà, Jésù wà pẹ̀lú wa ká bàa lè ṣe iṣẹ́ yìí láṣeparí. (Mát. 28:20) Ó sì ń lo àwọn ògìdìgbó áńgẹ́lì rẹ̀ láti tì wá lẹ́yìn. (Mát. 13:41, 49) Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ká túbọ̀ lọ fọkàn balẹ̀ pé Ọlọ́run ló ń darí ìgbòkègbodò wa. (Ìṣí. 14:6, 7) Nítorí náà, bóyá àwọn èèyàn gbọ́ o tàbí wọn ò gbọ́ o, mímọ̀ pé inú àwọn tó wà lókè ọ̀run ń dùn sí iṣẹ́ tá à ń ṣe ń fún wa láyọ̀ tó pọ̀ gan-an!
3 Múra Sílẹ̀ Dáadáa: Ìmúrasílẹ̀ tó kún rẹ́rẹ́ máa ń fi kún ayọ̀ wa. Gbígbáradì fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ kò yẹ kó là wá lóòógùn lọ títí. Kìkì ìwọ̀nba ìṣẹ́jú díẹ̀ la nílò láti fi ṣàgbéyẹ̀wò kókó tá a lè sọ̀rọ̀ lé lórí látinú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tàbí látinú ìwé tá a fẹ́ fi lọni lóṣù tá a wà. Yan ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan látinú apá náà, “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn,” tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàyẹ̀wò àkìbọnú January 2002, tó sọ nípa “Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá,” tàbí kó o wo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tó gbéṣẹ́ nínú ìwé Reasoning. Bó bá jẹ́ pé àtakò táwọn onílé sábà máa ń ṣe ló ń fà ọ́ sẹ́yìn, múra ìdáhùn kan sílẹ̀ tó o máa fi dá wọn lóhùn lọ́nà tó máa tù wọ́n lára, kó o wá darí àfiyèsí wọn sí kókó kan tó ń fani mọ́ra. Ìwé Reasoning wúlò gan-an fún ṣíṣe èyí. Lílo àwọn àrànṣe wọ̀nyí yóò fún wa ní ìfọ̀kànbalẹ̀ tá a nílò láti máa wàásù tayọ̀tayọ̀.
4 Gbàdúrà Àtọkànwá: Àdúrà ṣe kókó ká bàa lè ní ayọ̀ pípẹ́ títí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ Jèhófà là ń ṣe, a ní láti fi taratara bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ayọ̀ sì jẹ́ ọ̀kan nínú èso tẹ̀mí. (Gál. 5:22) Jèhófà yóò fún wa lókun láti máa wàásù nìṣó. (Fílí. 4:13) Gbígbàdúrà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti lẹ́mìí pé nǹkan á dára nígbà tá a bá ní àwọn ìrírí tí kò bára dé. (Ìṣe 13:52; 1 Pét. 4:13, 14) Bó bá ń ṣe wá bíi pé ẹ̀rù ń bà wá, àdúrà lè ràn wá lọ́wọ́ láti tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa láìṣojo, tí a ó sì ṣe é tọ̀yàyàtọ̀yàyà.—Ìṣe 4:31.
5 Wá Àyè Láti Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀: Ká sòótọ́, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò túbọ̀ fún wa láyọ̀ bá a bá ń rẹ́ni bá sọ̀rọ̀. Yíyí ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ padà kó o bàa lè wàásù láti ilé dé ilé lákòókò tó yàtọ̀, bóyá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, lè mú kí ọ̀pọ̀ sí i tẹ́tí sílẹ̀. O máa ń bá àwọn èèyàn pàdé ní gbogbo ìgbà tó o bá ń rìn lọ ní òpópónà, tó o bá ń lọ nájà, tó o bá wà nínú ọkọ̀ èrò, tàbí tó o bá gbafẹ́ lọ. Kí ló dé tó ò múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kúkúrú kan sílẹ̀ tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, kó o sì lo ìdánúṣe láti bá àwọn tó bá fara hàn bí ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀? Ó sì lè jẹ́ pé àyè máa ń yọ fún ọ níbi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí níléèwé rẹ láti bá àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀ lójoojúmọ́. Àyè láti jẹ́rìí lè ṣí sílẹ̀ nípa wíwulẹ̀ dẹ́nu lé kókó ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ tó lè ru ìfẹ́ wọn sókè. Àwọn àbá tó jíire wà lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002. Èyíkéyìí tó o bá lò nínú àwọn àǹfààní wọ̀nyí lè mú kí ayọ̀ rẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i.
6 Ó mà dára o pé ká máa ṣe àwọn ohun tó lè mú wa láyọ̀ torí pé ayọ̀ ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà! Bí a bá ń bá a nìṣó láti jẹ́ aláyọ̀, a ó gba èrè ńlá nígbà tí iṣẹ́ tá ò tún ní padà ṣe mọ́ láé yìí bá parí. Ìfojúsọ́nà yìí nìkan fúnra rẹ̀ ti tó láti fi kún ayọ̀ tá à ń ní nínú iṣẹ́ ìwàásù.—Mát. 25:21.