Máa Gbàdúrà fún Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà
1 Jésù tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́kàn pé wọ́n nílò ìbùkún Jèhófà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Mát. 9:37, 38) Àdúrà ìyìn àti ìdúpẹ́ àtọkànwá, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àtinúwá wa ń fi hàn pé a gbára lé Jèhófà pátápátá fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀. (Fílí. 4:6, 7) Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé kí a máa gba “gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀,” èyí sì kan àwọn àdúrà táa ń gbà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—Éfé. 6:18.
2 A ń yin Jèhófà nínú àdúrà wa nítorí àwọn ànímọ́ àti àṣeyọrí rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́. A tún ń yìn ín gẹ́gẹ́ bí Olùfúnni ní ìhìn rere táa ń wàásù. Ó yẹ ká máa yìn ín torí pé òun nìkan ló ń mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kẹ́sẹ járí.—Sm. 127:1.
3 Àdúrà ìdúpẹ́ wa ń fi ìmọrírì hàn fún òye tí Jèhófà ti fún wa nípa ìfẹ́ àti ète rẹ̀. Kì í ha ṣe àǹfààní ló jẹ́ láti ṣàjọpín òtítọ́ Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn? A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún gbogbo ohun tí à ń gbé ṣe nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.—Sm. 107:8; Éfé. 5:20.
4 Lọ́nà tó bá a mu gẹ́ẹ́, a máa ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Jèhófà láti rí àwọn èèyàn tí yóò tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táa fi ń lọ̀ wọ́n, a sì ń béèrè fún ìrànlọ́wọ́ kí a lè mú òtítọ́ dé inú ọkàn-àyà wọn. Nípa bíbéèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀, a ń fi hàn pé a gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa sèso.—1 Kọ́r. 3:5-7.
5 Arábìnrin kan nímọ̀lára pé obìnrin kan tí ń bẹ ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn òun kì í ka Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níwọ̀n bí kò ti fẹ́ káwọn ìwé ìròyìn ṣíṣeyebíye wọ̀nyí di àkódànù, ó bẹ Jèhófà pé bí obìnrin náà kì í báá kà wọ́n, kí ó kọ̀ láti gbà wọ́n. Nígbà tí arábìnrin náà padà débẹ̀, ọkọ obìnrin náà sọ pé: “O ṣeun fún mímú ìwé ìròyìn wọ̀nyí wá déédéé. Mò ń kà wọ́n, mo si fẹ́ràn wọn gan-an ni.”
6 Pẹ̀lú àrọwà tó fẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn tó sì jẹ́ àtinúwá, a lè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìwà àgunlá àti ìṣáátá tí àwọn èèyàn ń hù, kí a sì borí ìbẹ̀rù ènìyàn, kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti máa fi àìṣojo wàásù fáwọn ẹlòmíràn. (Ìṣe 4:31) Bí a bá ń bá a nìṣó láti máa gba “gbogbo oríṣi àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀” bí a ti ń fi tìgbọràn-tìgbọràn ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wa nìṣó, ìdánilójú wà pé Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́.—1 Jòh. 3:22.