ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 9/1 ojú ìwé 27-31
  • Ẹ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Yín Fún Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Yín Fún Ọlọ́run
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
  • Kí La Lè Tọrọ Lọ́wọ́ Ọlọ́run?
  • Ǹjẹ́ A Lè Gbàdúrà Tá A Bá Dẹ́ṣẹ̀?
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Ń Dáhùn Àdúrà
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Bí O Ṣe Lè Súnmọ́ Ọlọrun
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Ni Àdúrà Rẹ Ń Sọ Nípa Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 9/1 ojú ìwé 27-31

Ẹ Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Yín Fún Ọlọ́run

“Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.”—FÍLÍPÌ 4:6.

1. Ta ni a láǹfààní láti bá sọ̀rọ̀, kí sì nìdí tíyẹn fi jọni lójú gan-an?

TÓ O bá kọ̀wé sí olórí orílẹ̀-èdè rẹ pé o fẹ́ wá bá a sọ̀rọ̀, irú èsì wo lo rò pé o máa rí gbà? O lè rí èsì tó dáa gbà látọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ kò dájú pé wọ́n á fún ọ láyè láti bá alákòóso náà fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní ti Alákòóso gíga jù lọ lórí gbogbo ayé, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run. A láǹfààní láti bá a sọ̀rọ̀ láti ibikíbi tá a bá wà, a sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ nígbàkigbà tó bá wù wá. Kò sígbà tí àdúrà tó ṣètẹ́wọ́gbà kò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Òwe 15:29) Ìyẹn mà ga lọ́lá o! Ǹjẹ́ kò yẹ ká mọrírì àǹfààní tá a ní yìí, kíyẹn sì mú ká máa gbàdúrà sí Ẹni tí Bíbélì pè ní “olùgbọ́ àdúrà” yìí déédéé?—Sáàmù 65:2.

2. Kí lẹnì kan gbọ́dọ̀ ní kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà rẹ̀?

2 Àmọ́, àwọn kan lè máa béèrè pé, ‘Irú àwọn àdúrà wo ni Ọlọ́run máa ń gbọ́?’ Bíbélì ṣàlàyé ohun pàtàkì kan tó yẹ kéèyàn ní kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà rẹ̀, ó sọ pé: “Láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wù ú dáadáa, nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá gbọ́dọ̀ gbà gbọ́ pé ó ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ohun pàtàkì kan téèyàn gbọ́dọ̀ ní kó tó lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ ni ìgbàgbọ́. Ọlọ́run múra tán láti gbọ́ àdúrà àwọn tó ń tọ̀ ọ́ wá, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ kí wọ́n sì máa fi òótọ́ inú àti ọkàn tó dáa ṣe àwọn iṣẹ́ tí inú Ọlọ́run dùn sí.

3. (a) Gẹ́gẹ́ bí àdúrà àwọn olóòótọ́ ìgbàanì ti fi hàn, àwọn nǹkan wo la lè mẹ́nu kàn nínú àdúrà wa? (b) Irú àwọn àdúrà wo la lè gbà?

3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílípì 4:6, 7) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa àwọn tó gbàdúrà sí Ọlọ́run nítorí ẹ̀dùn ọkàn wọn. Lára irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Hánà, Èlíjà, Hesekáyà, àti Dáníẹ́lì. (1 Sámúẹ́lì 2:1-10; 1 Àwọn Ọba 18:36, 37; 2 Àwọn Ọba 19:15-19; Dáníẹ́lì 9:3-21) Ó yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn. Tún ṣàkíyèsí pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé onírúurú àdúrà ló wà. Ó mẹ́nu kan ìdúpẹ́, ìyẹn ni àdúrà tá a fi ń dúpẹ́ oore tí Ọlọ́run ń ṣe fún wa. A tún lè fi ìyìn fún Ọlọ́run lákòókò tá a bá ń gba àdúrà yìí. Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ ni kéèyàn máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ Ọlọ́run tọkàntọkàn. A sì tún lè tọrọ nǹkan tàbí ká béèrè ohun kan pàtó. (Lúùkù 11:2, 3) Inú Bàbá wa ọ̀run máa ń dùn láti gbọ́ èyíkéyìí tá a bá gbà sí i nínú àwọn àdúrà wọ̀nyí.

4. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà mọ ohun tá a nílò, síbẹ̀ kí nìdí tó fi yẹ ká máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀?

4 Àwọn kan lè béèrè pé, ‘Ṣé Jèhófà ò ti mọ gbogbo ohun tá a nílò tẹ́lẹ̀ ni?’ Ó dájú pé ó ti mọ̀ ọ́. (Mátíù 6:8, 32) Kí wá nìdí tó tún fi fẹ́ ká máa sọ àwọn nǹkan tá a nílò fóun? Àpẹẹrẹ kan rèé: Onílé ìtajà kan lè fẹ́ fún àwọn kan lára àwọn oníbàárà rẹ̀ lẹ́bùn. Àmọ́ àwọn oníbàárà náà gbọ́dọ̀ wá sọ́dọ̀ onílé ìtajà yìí kí wọ́n tó lè rí ẹ̀bùn náà gbà. Táwọn kan bá kọ̀ tí wọ́n ò wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó túmọ̀ sí pé wọn ò mọrírì ẹ̀bùn ọ̀hún nìyẹn. Bákan náà, tá ò bá sọ àwọn ohun tá a nílò fún Ọlọ́run nínú àdúrà, ó túmọ̀ sí pé a ò mọrírì àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè fún wa nìyẹn. Jésù sọ pé: “Ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà.” (Jòhánù 16:24) Ṣíṣe èyí ló máa fi hàn pé a gbọ́kàn wa lé Ọlọ́run.

Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbàdúrà ní orúkọ Jésù?

5 Jèhófà ò gbé àwọn òfin kàn-ń-pá kan kalẹ̀ lórí bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà. Síbẹ̀, a ní láti mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run, Bíbélì sì ṣàlàyé èyí fún wa. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi.” (Jòhánù 16:23) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù, ká gbà pé Jésù ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí ìbùkún Ọlọ́run ń gbà dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn.

6. Ṣé ó pọn dandan ká kúnlẹ̀ tàbí ká dúró nígbà tá a bá fẹ́ gbàdúrà?

6 Ṣé ó pọn dandan ká kúnlẹ̀ tàbí ká dúró tá a bá fẹ́ gbàdúrà? Bíbélì ò sọ pàtó bó ṣe yẹ ká ṣe nígbà tá a bá ń gbàdúrà kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ wa. (1 Àwọn Ọba 8:22; Nehemáyà 8:6; Máàkù 11:25; Lúùkù 22:41) Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé ká fi òótọ́ inú àti ọkàn tó dáa gbàdúrà sí Ọlọ́run.—Jóẹ́lì 2:12, 13.

7. (a) Kí ni ìtumọ̀ “àmín”? (b) Ọ̀nà tó tọ́ wo là ń gbà lò ó nínú àdúrà?

7 Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa sọ pé “àmín” lẹ́yìn àdúrà wa? Ìwé Mímọ́ fi hàn pé èyí jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti parí àdúrà wa, àgàgà nígbà tá a bá ń gbàdúrà níwájú àwùjọ. (Sáàmù 72:19; 89:52) Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù náà ʼa·menʹ ni, “bẹ́ẹ̀ ni kó rí.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ tí McClintock àti Strong ṣe jáde ṣàlàyé pé ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ṣe “Àmín” lẹ́yìn àdúrà ni “láti fi hàn pé a fara mọ́ ohun tá a sọ nínú àdúrà náà àti pé a fẹ́ kí àdúrà ọ̀hún ṣẹ.” Nípa bẹ́ẹ̀, tẹ́ni tó gbàdúrà bá fi òótọ́ inú ṣe “Àmín” lẹ́yìn àdúrà rẹ̀, ó fi hàn pé ohun tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yẹn ti ọkàn òun wá. Nígbà tí Kristẹni kan tó ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà bá fi ọ̀rọ̀ yìí parí àdúrà rẹ̀, àwọn tó tẹ́tí sí àdúrà náà lè ṣe “Àmín” nínú ọkàn wọn tàbí kí wọ́n sọ ọ́ jáde láti fi hàn pé tọkàntọkàn làwọn fara mọ́ ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán náà.—1 Kọ́ríńtì 14:16.

8. Báwo làwọn àdúrà wa kan ṣe lè dà bí àwọn àdúrà tí Jékọ́bù tàbí Ábúráhámù gbà, kí lèyí sì ń fi hàn nípa wa?

8 Àwọn ìgbà mìíràn wà tí Ọlọ́run á fẹ́ ká fi hàn pé ohun tá à ń gbàdúrà fún jẹ wá lọ́kàn gan-an. A lè ní láti ṣe bíi ti Jékọ́bù ayé ìgbàanì, tó fi gbogbo òru bá áńgẹ́lì kan jìjàkadì kó lè rí ìbùkún gbà. (Jẹ́nẹ́sísì 32:24-26) Àwọn ipò kan sì lè gba pé ká ṣe bíi ti Ábúráhámù, tó ń bẹ Jèhófà ṣáá nítorí Lọ́ọ̀tì àtàwọn mìíràn tó jẹ́ olódodo, tó ṣeé ṣe kí wọ́n wà ní Sódómù. (Jẹ́nẹ́sísì 18:22-33) Àwa náà lè ní láti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà nípa àwọn ohun kan tó ṣeyebíye fún wa gan-an. Ká máa bẹ̀ ẹ́ nítorí pé Ọlọ́run tí kì í ṣègbè ni, ó sì jẹ́ onínúure àti aláàánú.

Kí La Lè Tọrọ Lọ́wọ́ Ọlọ́run?

9. Kí ló yẹ kó ká wa lára jù lọ nígbà tá a bá ń gbàdúrà?

9 Rántí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ohun gbogbo . . . kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílípì 4:6) Nítorí náà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn nígbèésí ayé wa la lè sọ lákòókò tá a bá ń dá gbàdúrà. Àmọ́, ìfẹ́ Jèhófà ló gbọ́dọ̀ ká wa lára ju ohunkóhun mìíràn lọ nínú àdúrà wa. Dáníẹ́lì fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú èyí. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń jìyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Dáníẹ́lì bẹ Jèhófà pé kó fi àánú hàn sí wọn, ó ní: “Má ṣe jáfara, nítorí tìrẹ, Ọlọ́run mi, nítorí orúkọ rẹ.” (Dáníẹ́lì 9:15-19) Ǹjẹ́ àwọn àdúrà tiwa náà máa ń fi hàn pé sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kí ìfẹ́ rẹ̀ sì di ṣíṣe lohun tó ká wa lára jù lọ?

10. Báwo la ṣe mọ̀ pé ó bójú mu láti gbàdúrà nípa àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa?

10 Àmọ́ ṣá o, ó tún dáa ká máa gbàdúrà nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ara wa. Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe bíi ti onísáàmù, ká gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ ká lè lóye àwọn nǹkan tẹ̀mí tó jinlẹ̀ gan-an. Ó gbàdúrà pé: “Mú mi lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́, kí n sì lè máa fi gbogbo ọkàn-àyà pa á mọ́.” (Sáàmù 119:33, 34; Kólósè 1:9, 10) Jésù “ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ pẹ̀lú sí Ẹni tí ó lè gbà á là kúrò nínú ikú.” (Hébérù 5:7) Ohun tó ṣe yìí fi hàn pé ó bójú mu kéèyàn máa gbàdúrà fún okun nígbà tó bá dojú kọ ewu tàbí àdánwò. Nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ, ó fi ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan kún un, ìyẹn àwọn nǹkan bí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti oúnjẹ òòjọ́.

11. Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní kó sínú ìdẹwò?

11 Nínú àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ yẹn, Jésù fi ẹ̀bẹ̀ yìí kún un pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:9-13) Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò.” (Mátíù 26:41) Àdúrà ṣe pàtàkì gan-an nígbà tá a bá ń dojú kọ ìdẹwò. Ohun kan lè fẹ́ sún wa ṣe ohun tó lòdì sí ìlànà Bíbélì níbi iṣẹ́ tàbí nílé ìwé. Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lè pè wá láti wá bá wọn ṣe àwọn ohun kan tí kò tọ́ sí Kristẹni. Wọ́n lè ní ká ṣe ohun kan tó lòdì sí àwọn ìlànà òdodo. Ní irú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, ohun tó dára láti ṣe ni pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká gbàdúrà kí ìdẹwò tóó dé àti nígbà tá a bá dojú kọ ìdẹwò náà, ká bẹ Ọlọ́run kó ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa ṣubú.

12. Àwọn ohun tó ń múni ṣàníyàn wo ló lè mú ká gbàdúrà, kí ló sì yẹ ká retí pé Jèhófà á ṣe?

12 Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní máa ń bára wọn nínú onírúurú pákáǹleke àti hílàhílo. Àìsàn àti ìdààmú ọkàn ni olórí ohun tó ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣàníyàn. Ìwà ipá téèyàn ń rí lọ́tùn-ún lósì ń máyé súni. Ìṣòro àìrówóná ń mú kó ṣòro láti gbọ́ bùkátà. Ẹ ò rí i pé ìtùnú ńlá ló jẹ́ láti mọ̀ pé Jèhófà ń tẹ́tí sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń mú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí tọ̀ ọ́ wá nínú àdúrà! Sáàmù 102:17 sọ nípa Jèhófà pé: “Ó dájú pé òun yóò yíjú sí àdúrà àwọn tí a kó gbogbo nǹkan ìní wọn lọ, kì yóò sì tẹ́ńbẹ́lú àdúrà wọn.”

13. (a) Àwọn ọ̀ràn ara ẹni wo ló yẹ ká máa sọ nínú àdúrà? (b) Sọ àpẹẹrẹ kan nípa irú àdúrà bẹ́ẹ̀.

13 Ní ti gidi, ọ̀ràn èyíkéyìí tó bá ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà àti àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ kókó pàtàkì tó yẹ ká sọ nípa rẹ̀ nínú àdúrà wa. (1 Jòhánù 5:14) Tó o bá fẹ́ ṣèpinnu nípa ìgbéyàwó tàbí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, tàbí nípa bó o ṣe lè túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, má bẹ̀rù rárá láti sọ ọ̀rọ̀ náà fún Ọlọ́run, kó o sọ pé kó tọ́ ẹ sọ́nà. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Philippines fẹ́ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Àmọ́, kò níṣẹ́ tó lè máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Ó ní: “Ní ọjọ́ Sátidé kan, mo dìídì gbàdúrà sí Jèhófà nípa iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Nígbà tó yá tí mo jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn, mo fi ìwé lọ ọmọbìnrin kan tí kò tíì pé ẹni ogún ọdún. Ohun tí mi ò retí rárá ni ọmọbìnrin náà sọ, ó ní: ‘Tójú bá ti ń mọ́ láàárọ̀ Monday, ọ̀nà ilé ìwé mi ni kó o gbà lọ.’ Mo bi í pé, ‘Kí nìdí?’ Ó ṣàlàyé pé àyè iṣẹ́ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ níbẹ̀, wọ́n sì ń wẹ́ni tí wọ́n máa gbà síṣẹ́ ọ̀hún kíákíá. Bí mo ṣe lọ nìyẹn o, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n sì gbà mí síṣẹ́ náà. Bí àlá lọ̀rọ̀ náà rí.” Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí káàkiri ayé làwọn nǹkan bí èyí ti ṣẹlẹ̀ sí. Nítorí náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún Ọlọ́run nínú àdúrà.

Ǹjẹ́ A Lè Gbàdúrà Tá A Bá Dẹ́ṣẹ̀?

14, 15. (a) Kí nìdí téèyàn ò fi gbọ́dọ̀ kọ̀ láti gbàdúrà béèyàn tiẹ̀ dẹ́ṣẹ̀? (b) Yàtọ̀ sí àdúrà téèyàn gbà fúnra rẹ̀, nǹkan míì wo ló máa ran èèyàn lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

14 Báwo ni àdúrà ṣe lè ṣèrànwọ́ téèyàn bá dẹ́ṣẹ̀? Àwọn kan tó dẹ́ṣẹ̀ ò gbàdúrà mọ́ nítorí ìtìjú. Ká sòótọ́, ìyẹn ò bọ́gbọ́n mu rárá. Àpèjúwe kan rèé: Àwọn tó ń wa ọkọ̀ òfuurufú mọ̀ pé táwọn bá ṣìnà, àwọn lè bá àwọn tó ń darí ọkọ̀ òfuurufú ọ̀hún nísàlẹ̀ sọ̀rọ̀ kí wọ́n sì ran àwọn lọ́wọ́. Tẹ́ni tó ń wakọ̀ òfuurufú náà bá kọ̀ láti kàn sáwọn tó ń darí ọkọ̀ náà nísàlẹ̀ nítorí ìtìjú pé adúrú òun ṣìnà ńkọ́? Ìyẹn lè yọrí sí jàǹbá ńlá! Lọ́nà kan náà, ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ tó wá ń tijú láti gbàdúrà sí Ọlọ́run lè túbọ̀ kó ara rẹ̀ síyọnu. Ìtìjú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tá a dá ò gbọ́dọ̀ mú ká kọ̀ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀. Kódà, Ọlọ́run ké sí gbogbo àwọn tó ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá pé kí wọ́n gbàdúrà sóun. Wòlíì Aísáyà rọ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ nígbà ayé rẹ̀ pé kí wọ́n ké pe Jèhófà, “nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.” (Aísáyà 55:6, 7) Àmọ́ ṣá o, kéèyàn tó lè ‘tu Jèhófà lójú,’ onítọ̀hún gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nípa jíjáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà kó sì ronú pìwà dà tọkàntọkàn.—Sáàmù 119:58; Dáníẹ́lì 9:13.

15 Ìdí mìíràn tún wà tí àdúrà fi ṣe pàtàkì gan-an nígbà téèyàn bá dẹ́ṣẹ̀. Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí, ó ní: “Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, . . . Jèhófà yóò sì gbé e dìde.” (Jákọ́bù 5:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni o, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ fúnra rẹ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Jèhófà nínú àdúrà, àmọ́ ó tún yẹ kó pe àwọn àgbà ọkùnrin láti gbàdúrà fóun. Ìyẹn ni yóò jẹ́ kí àjọṣe àárín òun àti Jèhófà tún padà dán mọ́rán.

Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Ń Dáhùn Àdúrà

16, 17. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà? (b) Àwọn ìrírí wo ló fi hàn pé àdúrà àti iṣẹ́ ìwàásù jọ ń rìn pọ̀ ni?

16 Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa ń dáhùn àwọn àdúrà? Ó lè dáhùn àwọn kan lójú ẹsẹ̀ kéèyàn sì rí i pé ó ti dáhùn wọn. (2 Àwọn Ọba 20:1-6) Àwọn mìíràn lè gba àkókò díẹ̀, èèyàn sì lè má mọ ìgbà tí Ọlọ́run dáhùn wọn. Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a rí nínú àpèjúwe Jésù nípa opó tó ń padà wá sọ́dọ̀ adájọ́ kan lemọ́lemọ́, ó lè pọn dandan pé ká gbàdúrà sí Ọlọ́run léraléra nígbà míì. (Lúùkù 18:1-8) Bó ti wù kó rí, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé tá a bá gba àdúrà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, Jèhófà kò ní sọ fún wa láé pé: “Yé dà mí láàmú.”—Lúùkù 11:5-9.

17 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn Jèhófà ti rí i pé Jèhófà dáhùn àdúrà wọn. Èyí sábà máa ń hàn kedere nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn arábìnrin méjì nílùú Philippines ń pín àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní apá ibì kan tó wà ní àdádó lórílẹ̀-èdè náà. Nígbà tí wọ́n mú ìwé àṣàrò kúkúrú fún obìnrin kan, omi lé ròrò lójú rẹ̀. Ó ní: “Lóru àná, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan tó máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí mi, mo sì rò pé ìdáhùn àdúrà mi rèé.” Kété lẹ́yìn ìgbà yẹn ni obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní apá ibòmíràn ní gúúsù ìlà oòrùn Éṣíà, ẹ̀rù máa ń ba Kristẹni arákùnrin kan láti wàásù ní ilé kan tó ṣòro wọ̀ nítorí pé ààbò ibẹ̀ ga. Àmọ́, ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì fi ìgboyà wọnú ilé náà. Ó kan ilẹ̀kùn ọ̀kan lára ibi táwọn èèyàn ń gbé níbẹ̀, obìnrin kan sì jáde sí i. Nígbà tí arákùnrin yìí ṣàlàyé ìdí tóun fi wá, ńṣe lóbìnrin náà bú sẹ́kún. Ó ní òun ti ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun sì ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti rí wọn. Tayọ̀tayọ̀ ni arákùnrin náà fi ràn án lọ́wọ́ láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè náà.

18. (a) Kí ló yẹ ká ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dáhùn àdúrà wa? (b) Kí ló yẹ kó dá wa lójú pé a óò máa gbádùn rẹ̀ tá a bá ń lo gbogbo àǹfààní tá a ní láti gbàdúrà sí Ọlọ́run?

18 Àǹfààní àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àdúrà jẹ́. Jèhófà múra tán láti fetí sáwọn àdúrà wa kó sì dáhùn wọn. (Aísáyà 30:18, 19) Síbẹ̀, a ní láti kíyè sí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà dáhùn àwọn àdúrà wa. Ó lè máà jẹ́ gbogbo ìgbà ló máa dáhùn wọn bá a ṣe fẹ́. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé láti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ká sì fògo fún un nígbàkigbà tá a bá rí i pé ó tọ́ wa sọ́nà. (1 Tẹsalóníkà 5:18) Láfikún sí i, ẹ jẹ́ ká máa rántí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nígbà gbogbo, èyí tó sọ pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” Bẹ́ẹ̀ ni o, lo gbogbo àǹfààní tó o ní láti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á máa gbádùn ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí Ọlọ́run bá gbọ́ àdúrà wọn, ó ní: “Àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”—Fílípì 4:6, 7.

Ǹjẹ́ O Lè Dáhùn?

• Irú àwọn àdúrà wo la lè gbà?

• Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

• Kí làwọn nǹkan tá a lè gbàdúrà nípa rẹ̀?

• Ipa wo ni àdúrà ń kó nígbà tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àdúrà àtọkànwá ń ràn wá lọ́wọ́ ká má bà a kó sínú ìdẹwò

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àdúrà la fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, òun la fi ń sọ àwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa fún un, tá a sì fi ń jẹ́ kó mọ àwọn ohun tá a nílò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́