Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 27, 2007. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ July 2 sí August 27, 2007.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa àti nínú ìjọ? [be-YR ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
2. Ká tó lè fi hàn pé ohun tá à ń sọ dá wa lójú, kí lohun tó ṣe pàtàkì pé ká ṣe? [be-YR ojú ìwé 196 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
3. Àwọn àbá wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ ọlọgbọ́n nígbà tá a bá ń wàásù? [be-YR ojú ìwé 198 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 1]
4. Báwo ni jíjẹ́ ọlọgbọ́n ṣe kan mímọ ìgbà tó yẹ́ ká fèsì ọ̀rọ̀ tí onílé bá sọ? (Owe 25:11) [be-YR ojú ìwé 199 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
5. Báwo la ṣe lè sọ̀rọ̀ lọ́nà táwọn ará á fi rí ẹ̀kọ́ kọ́? [be-YR ojú ìwé 203 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 204 ìpínrọ̀ 1]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Àwọn nǹkan pàtàkì mẹ́rin wo ni Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? [w99-YR 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 3]
7. Kí ni ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì téèyàn gbọ́dọ̀ ní kó tó lè fara da ìrẹ́jẹ? [w05-YR 6/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4]
8. Kí la rí kọ́ nínú bí Jésù ṣe dá àwọn Sadusí lóhùn ìbéèrè tí wọ́n bi í nípa àjíǹde? (Lúùkù 20:37, 38) [be-YR ojú ìwé 66 ìpínrọ̀ 4]
9. Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tàbí onígbàgbọ́ bíi tìẹ bá bi ẹ́ nípa ohun tó yẹ kóun ṣe nínú irú ipò kan, báwo ló ṣe yẹ kó o dá a lóhùn? [be-YR ojú ìwé 69 ìpínrọ̀ 4 àti 5]
10. Kí ló túmọ̀ sí láti “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú” wa ṣiṣẹ́? (Éfé. 4:23) [be-YR ojú ìwé 74 ìpínrọ̀ 4]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ní Ìsíkíẹ́lì 9:2-4, ta ni ọkùnrin tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ dúró fún, kí sì ni ‘àmì iwájú orí’ túmọ̀ sí? [w88-YR 9/15 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 18]
12. Lọ́nà wo làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù gbà dà bí “àwọn wòlíì arìndìn, tí wọ́n ń tọ ẹ̀mí ara wọn lẹ́yìn” gẹ́gẹ́ bí Ìsíkíẹ́lì 13:3 ṣe ṣàpèjúwe wọn? [w99-YR 10/1 ojú ìwé 13]
13. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ń pa “òwe” tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 18:2 yìí, kí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbìyànjú láti ṣe, báwo nìyẹn sì ṣe kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì náà pé á máa jíhìn ohun tá a bá ṣe? [w88-YR 9/15 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 10]
14. Ọ̀nà wo ni Ìsíkíẹ́lì gbà di “aláìlèsọ̀rọ̀” tàbí ẹni tó “yadi,” lákòókò tí wọ́n gbógun ti Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì pa á run? (Ìsík. 24:27; 33:22) [w03-YR 12/1 ojú ìwé 29]
15. Ta ni “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù,” ìgbà wo ló sì gbégbèésẹ̀ láti pa àwọn èèyàn Jèhófà run? (Ìsík. 38:2, 16) [w97-YR 3/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 3]