Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹ Máa Ṣọ́nà!, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la ó lò. Ká sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀. Gbogbo àwọn tá a fún ní ìwé ni ká ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn ká sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Báwọn kan bá sọ pé àwọn ti ní ìwé náà, ẹ ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún wọn láti jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè jàǹfààní ìwé náà. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o bá a sọ, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?, jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀, kó o sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Níwọ̀n bí oṣù September ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ A óò fẹ́ káwọn alàgbà ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Ilé-ìṣọ́nà April 15, 1991, ojú ìwé 21 sí 23, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ tàbí tí wọ́n yọ ara wọn lẹ́gbẹ́, tí wọ́n lè fẹ́ ká gba àwọn padà.
◼ Àwọn kan tí béèrè bóyá ó bójú mu láti ṣe àpèjẹ ìgbéyàwó nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí nínú ọgbà ibi tí wọ́n kọ́ ọ sí. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún àpèjẹ ìgbéyàwó èyíkéyìí, nítorí pé ìyẹn ò ní buyì kún gbọ̀ngàn náà gẹ́gẹ́ bí ibi ìjọsìn. Ile-Iṣọ Na [Gẹ̀ẹ́sì] ti September 15, 1956, ojú ìwé 571, ìpínrọ̀ 12, sọ pé: “Àsọyé ìgbéyàwó lè wáyé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àkókò tí kò forí gbárí pẹ̀lú àwọn ètò míì tó jẹ́ ti ìjọ. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àpèjẹ tó máa ń wáyé lẹ́yìn ìgbéyàwó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí pé kì í ṣe gbọ̀ngàn àríyá.” Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i pé ká lo Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí àyíká rẹ̀ fún àpèjẹ ìgbéyàwó. Ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 120 sí 123, la àwọn ohun tá a gbọ́dọ̀ máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún lẹ́sẹẹsẹ, ó sì tún ṣàlàyé bó ṣe yẹ ká máa bójú tó o.