Fídíò Tó Yẹ Kéèyàn Ronú Lé Lórí Dáadáa
“Fídíò yìí múni ronú jinlẹ̀ gan-an ni!”
“Fídíò náà wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin!”
“Nígbà tí mo wo fídíò náà, ó wọ̀ mí lákínyẹmí ara!”
1 Ṣó ṣèwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà tó o wo fídíò tó sọ nípa báwọn ọ̀dọ́ ṣe lè lọ́rẹ̀ẹ́ gidi, ìyẹn Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ìṣòro bá arákùnrin ọ̀dọ́ kan, kì í sì í ṣe torí nǹkan méjì bí kò ṣe torí àwọn ọ̀rẹ́ tó ń bá rìn. Wọ́n sọ ọ́ dẹni tí òtítọ́ ò jẹ lọ́kàn mọ́, ó sì ṣíwọ́ jíjẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni fídíò tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jáde. Ó wá kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo wo fídíò yẹn, bí mo bá sì ṣe ń wò ó ni mo máa ń yọ omijé lójú. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe ràn mí lọ́wọ́ lásìkò tó yẹ.” Fídíò náà mú kó ṣe ìyípadà ńláǹlà nínú ìgbésí ayé ẹ̀, ó sì yan àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Ó sọ síwájú sí i pé: “Kò síyè méjì pé ẹ mọ ìṣòro tó ń bá àwa ọ̀dọ́ fínra.” Ì bá dáa tẹ́yin òbí àtẹ̀yin ọ̀dọ́ bá lè wo fídíò yìí lẹ́ẹ̀kan sí i nígbà tẹ́ ẹ bá máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín? Lẹ́yìn ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, ẹ dá a dúró kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nínú àwọn ìpínrọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ.
2 Ọ̀rọ̀ Àkọ́sọ: Ta lọ̀rẹ́ gidi?—Òwe 18:24.
3 Àwọn Ohun Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Lè Lọ́rẹ̀ẹ́: Kí ló lè mú kó o gbé èrò pé àwọn ojúgbà ẹ ò gba tìẹ kúrò lọ́kàn? (Fílí. 2:4) Kí nìdí tó fi yẹ kíwọ náà tún ìwà ẹ ṣe, ta ló sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ló máa jẹ́ kó o lọ́rẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí i, ibo lo sì ti máa rí wọn?—2 Kọ́r. 6:13.
4 Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run: Báwo lo ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kí sì nìdí tí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ fi lérè? (Sm. 34:8) Ta lẹni tó wà nípò tó dáa jù láti mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run?
5 Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ́rùnrẹ́rùn: Àwọn wo ni ẹgbẹ́ búburú? (1 Kọ́r. 15:33) Báwo làwọn ọ̀rẹ́ rẹ́rùnrẹ́rùn ṣe lè sọ èèyàn dẹni tó pàdánù ojú rere Ọlọ́run? Ẹ̀kọ́ wo ni àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà kọ́ ẹ?—Jẹ́n. 34:1, 2, 7, 19.
6 Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Òde Òní: Ọ̀nà wo ni yíyà tí Tara ya ara rẹ̀ láṣo gbà kó bá a? Àwíjàre wo ló wí nípa ohun tó sún un tó fi yan àwọn ọ̀dọ́ inú ayé lọ́rẹ̀ẹ́? Inú ewu wo ló ti bá ara ẹ̀? Kí nìdí táwọn òbí ẹ̀ ò fi mọ̀ pé inú ewu ló wà, ìgbà tí wọ́n sì wá mọ̀, kí ni wọ́n ṣe tó ràn án lọ́wọ́ láti padà di ọ̀rẹ́ Jèhófà? Báwo ni arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan ṣe fi hàn pé òun jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi fún Tara? Kí nìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ fi ohun tó wà nínú Òwe 13:20 àti Jeremáyà 17:9 sílò? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Tara kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i?
7 Ìparí: Ẹ̀kọ́ wo ni fídíò yìí kọ́ ẹ? Báwo lo ṣe lè lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?—Sm. 71:17.