Inú Wọn Dùn Sí I Gan-an!
1 Àwọn ìdílé Kristẹni níbi gbogbo ti fi ìdùnnú àtọkànwá wọn hàn sí fídíò náà, Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Bàbá kan ní Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé lẹ́yìn tí àwọn ọmọkùnrin òun ti wo fídíò náà tán, ṣe ni wọ́n rọra jókòó jẹ́ẹ́, torí pé gbogbo ẹ̀kọ́ tí fídíò náà kọ́ wọn ló wọ̀ wọ́n lọ́kàn, tó sì yé wọn yékéyéké! Ìròyìn kan tó wá láti Màláwì sọ pé àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin àti arábìnrin tó wà lórílẹ̀-èdè náà mọ ìjẹ́pàtàkì fídíò yìí pẹ̀lú, nítorí pé irú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ látọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà wọn níléèwé ni fídíò náà fi hàn. Bàbá kan ní Jámánì sọ báyìí pé: “Fídíò yìí gan-an ni ìdáhùn sí àdúrà mi.” Ọ̀dọ́mọbìnrin kan sọ pé: “Ẹ ṣeun fún bẹ́ ẹ ṣe tún rán mi létí pé Jèhófà bìkítà nípa mi.” Alàgbà kan ní New Zealand sọ pé: “Òun ló pe orí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wa tí kò tíì pé ogún ọdún wálé láti tún máa rìn lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.” Arábìnrin kan tó ti ṣègbéyàwó wò ó tán, ló bá sọ pé: “Ó mà wù mí o pé kí gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú òtítọ́ wo fídíò yìí, kó sì sún wọn láti sọ òtítọ́ di tiwọn!” Ẹ̀yin ìdílé, ẹ ò ṣe tún fídíò yìí wò lẹ́ẹ̀kan sí i? Bẹ́ ẹ bá ti wò ó tán, kẹ́ ẹ wá jíròrò àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí.
2 Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀: Ta ni ọ̀rẹ́ tòótọ́?—Òwe 18:24.
3 Àwọn Ohun Tó Lè Ṣèdíwọ́ fún Níní Ọ̀rẹ́: Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa ronú pé àwọn ẹlòmíì pa ọ́ tì? (Fílí. 2:4) Èé ṣe tó fi yẹ kó o máa sapá láti mú kí ìwà rẹ túbọ̀ sunwọ̀n sí i, ta ló sì lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí? Kí ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i, ibo lo sì ti lè rí wọn?—2 Kọ́r. 6:13.
4 Ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Pẹ̀lú Ọlọ́run: Báwo lo ṣe lè ní àjọṣe pẹ̀lú Jèhófà, èé sì ti ṣe tí èyí fi yẹ bẹ́ẹ̀? (Sm. 34:8) Ta ló wà ní ipò tó dára jù lọ láti mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run túbọ̀ lókun sí i?
5 Àwọn Ọ̀rẹ́ Burúkú: Àwọn wo ni ẹgbẹ́ búburú? (1 Kọ́r. 15:33) Báwo làwọn ọ̀rẹ́ burúkú ṣe lè mú kéèyàn kàgbákò nípa tẹ̀mí? Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú ìtàn tí Bíbélì sọ nípa Dínà?—Jẹ́n. 34:1, 2, 7, 19.
6 Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Òde Òní: Ipa wo ni ìdánìkanwà ní lórí ọ̀dọ́mọbìnrin náà, Tara? Báwo ló ṣe dá ara rẹ̀ láre pé kò sóhun tó burú nínú bí òun ṣe ń bá àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ayé kẹ́gbẹ́? Kí làwọn nǹkan eléwu tí wọ́n fojú rẹ̀ mọ̀? Kí ni kò jẹ́ kí àwọn òbí rẹ̀ mọ inú ewu tó wà, àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe bá a lò nígbà tí wọ́n ń ràn án lọ́wọ́ láti kọ́fẹ padà nípa tẹ̀mí? Báwo ni arábìnrin aṣáájú ọ̀nà kan ṣe fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ lòún jẹ́ fún Tara? Èé ṣe tí àwa Kristẹni fi gbọ́dọ̀ kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 13:20 àti Jeremáyà 17:9? Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni Tara kọ́?
7 Ìparí: Kí làwọn ẹ̀kọ́ tó o ti kọ́ nínú fídíò yìí? Báwo lo ṣe lè fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?—Sm. 71:17.