ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/02 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 4/02 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 8

Orin 39

13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Fún olúkúlùkù níṣìírí pé kí wọ́n wo fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? láti múra sílẹ̀ fún ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ April 22. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 8, ṣe àwọn àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ April 15 àti Jí! May 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ń pani lẹ́nu mọ́, irú bíi, “Mo ní ìsìn tèmi.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ewé 10.

12 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Ẹ . . . Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn.”a Lẹ́yìn ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn, fọ̀rọ̀ wá akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wò, kí wọ́n sọ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i.

Orin 157 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 15

Orin 101

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Bá a Nìṣó Ní Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣe àpérò pẹ̀lú olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ kan, aṣáájú ọ̀nà kan àti akéde kan. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàtúnyẹ̀wò ìṣètò Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́, gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé rẹ̀ ní ojú ewé 8 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù September 1998. Lẹ́yìn náà, kí ó jíròrò pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ipa tí wọ́n ń kó nínú ìṣètò náà àti bí ìṣètò náà ṣe gbéṣẹ́ sí. Àwọn nǹkan wo ni kálukú wọn ti ṣe láti fi mú kó kẹ́sẹ járí? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn wá rọ gbogbo akéde láti jẹ́ kí òun mọ̀ bí wọ́n bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. A tún lè ṣètò láti túbọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwọn tá a ti ràn lọ́wọ́ tẹ́lẹ̀, kí wọ́n lè túbọ̀ dáńgájíá nínú apá mìíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.

20 min: “Lẹ́tà Tí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Kọ.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, kí o sì ṣàlàyé bí ìsọfúnni yìí ṣe lè fún gbogbo wa níṣìírí.

Orin 199 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 22

Orin 90

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ewé 8, jẹ́ kí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ May 1 lọni, kí arábìnrin kan sì fi hàn bí a ṣe lè fi Jí! May 8 lọni. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, tún gbólóhùn kan tàbí méjì tí wọ́n kọ́kọ́ lò nínú àṣefihàn náà sọ, èyí tó mú kí onílé fẹ́ láti tẹ́tí sí wọn.

10 min: Máa Dé Lákòókò! Àsọyé. Àwọn ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa ṣe pàtàkì gidigidi, ó sì yẹ kí wọ́n ní “ìgbà tí a yàn kalẹ̀” fún wọn. (Oníw. 3:1) A fẹ́ láti jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ látinú àwọn ètò tá a ṣe fún ìjọsìn wa sí Ọlọ́run. A ní láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìpàdé ìjọ àti ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá gbàrà tí àkókò tá a fi wọ́n sí bá ti tó. Jèhófà kò fi àwọn ohun tó ń ṣe falẹ̀ rí. (Háb. 2:3) Ṣé a nílò àtúnṣe lórí kókó yìí? Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè mú kí èyíkéyìí lára wa pẹ́ lẹ́yìn. Àmọ́, bá a bá ṣètò àwọn ìgbòkègbodò wa dáadáa, a ò ní di apẹ́lẹ́yìn, a ò ní máa dé lẹ́yìn orin àti àdúrà tá a fi bẹ̀rẹ̀ ìpàdé tàbí lẹ́yìn tí ètò fún iṣẹ́ ìsìn pápá ti parí. Ṣàlàyé àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn àṣà tó dára, èyí tó máa jẹ́ ká lè máa pésẹ̀ fún gbogbo ìgbòkègbodò tẹ̀mí lákòókò.—Wo Ilé-ìṣọ́nà June 15, 1990, ojú ewé 29.

25 min: “Inú Wọn Dùn Sí I Gan-an!”b Ní ìpínrọ̀ kìíní, jẹ́ kí àwọn ará sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa fídíò Young People Ask—How Can I Make Real Friends? Lẹ́yìn náà, bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ ní tààràtà nípa lílo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbéèrè tó wà ní ìpínrọ̀ 2 sí 7. Ní oṣù June, a óò gbé fídíò Our Whole Association of Brothers yẹ̀ wò. Ní àfidípò, jíròrò “Kòṣeémánìí Lètò Àjọ Jèhófà,” látinú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2000, ojú ewé 30 àti 31.

Orin 191 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 29

Orin 162

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù April sílẹ̀.

20 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, Iṣẹ́ Tí Ń Gbẹ̀mí Là Ni!”c Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà sílò.

15 min:  Jíròrò “Máa Bá A Nìṣó Láti Jàǹfààní Nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!” Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì kí àwọn akéde máa mú ìwé ìròyìn lọ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i kí wọ́n sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.

Orin 28 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní May 6

Orin 141

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

10 min: Wíwéwèé Sílẹ̀ fún Àkókò Ìsinmi Ilé Ẹ̀kọ́. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ gbogbo àwọn ìgbòkègbodò tá a sábà máa ń lo àkókò ìsinmi fún: lílọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe, ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣíṣe àwọn àtúnṣe tó bá pọn dandan láyìíká ilé àti, bó bá ṣeé ṣe, lílo àkókò ìsinmi láti rìnrìn àjò tàbí láti ṣe eré ìtura. Ké sí àwọn ará bíi mélòó kan láti sọ bí wọ́n ti wéwèé láti lo àkókò ìsinmi wọn, àti bí wọ́n ṣe máa rí i dájú pé wọ́n á máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ìpàdé ìjọ, àti iṣẹ́ ìsìn pápá nìṣó, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ máa rìnrìn àjò lọ síbòmíràn. Bí ìjọ yín bá ní àwọn àgbègbè tí a kì í sábàá ṣe, sọ àwọn ètò tí ẹ̀ ń ṣe láti jẹ́rìí kúnnákúnná láwọn àgbègbè ọ̀hún. Rán gbogbo àwùjọ létí láti máa rí i pé olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wọn ń rí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn gbà, yálà wọ́n wà nítòsí tàbí wọ́n rìnrìn àjò.

25 min: “Báwo Làwọn Ìdílé Kristẹni Ṣe Lè Dúró Sán-ún Nípa Tẹ̀mí?”d Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ náà, sọ àwọn ìrírí gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ February 15, 1999, ojú ewé 10 sí 12.

Orin 17 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, lẹ́yìn náà kí o jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, lẹ́yìn náà kí o jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, lẹ́yìn náà kí o jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, lẹ́yìn náà kí o jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́