Máa Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Tuntun Tó Sọ̀rọ̀ Nípa Ìkànnì
Àkọlé ìwé àṣàrò kúkúrú náà ni Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? Àwọn ìbéèrè mẹ́ta ló wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Tó o bá láǹfààní láti bá ẹnìkan sọ̀rọ̀, o lè ní kí ẹni náà sọ ìbéèrè tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn jù lọ lára àwọn ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Lẹ́yìn náà, fi ìdáhùn hàn-án ní abala Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ lórí Ìkànnì wa. Ibẹ̀ náà ló ti máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Àti kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?
Máa mú ìwé àṣàrò kúkúrú yìí dání nígbà gbogbo kó o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ tá a máa gbádùn lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.