Máa Lo Ìkànnì Wa Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—“Ohun Tí Bíbélì Sọ”
Apá kan wà nínú ìkànnì jw.org tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ,” abẹ́ abala “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” ló wà. Tá a bá dojúlùmọ̀ àwọn ìbéèrè yìí táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè dáadáa, a lè ní kí àwọn onílé tó bá bi wá ní ìbéèrè lọ sórí Ìkànnì wa láti rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Bákan náà, a lè fi àwọn ìbéèrè yìí bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lóde ẹ̀rí. A lè yan ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ká wá ní kí onílé sọ èrò rẹ̀ nípa ìbéèrè náà, lẹ́yìn náà, ká lo àlàyé inú àpilẹ̀kọ tó wà lórí ìkànnì jw.org láti jẹ́ kó mọ ohun tí Bíbélì sọ. Ká wá sọ ibi tá a ti rí àlàyé tá a ṣe fún un tàbí ká fi ibi tá a ti rí i hàn án. Ohun mí ì tá a tún lè ṣe ni pé ká jẹ́ kí onílé ka ìdáhùn ìbéèrè náà tààràtà látorí Ìkànnì. Ìyàwó alábòójútó arìnrìn-àjò kan ti lo ìkànnì jw.org dáadáa lẹnu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ohun tó máa ń sọ ni pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń béèrè pé, ‘Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?’ Ṣé wàá fẹ́ mọ ìdáhùn ìbéèrè náà láàárín ìṣẹ́jú àáyá mọ́kànléláàádọ́ta [51]?” Lẹ́yìn náà, yóò jẹ́ kí ẹni náà gbọ́ ìdáhùn ìbéèrè tá a kà sórí ẹ̀rọ, èyí tó wà jáde, tó sì gbé sórí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ̀. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, yóò fi orí 11 ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni han onílé.