Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—“Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà”
Apá kan wà lórí ìkànnì jw.org/yo tá a pè ní “Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà” tó wà fún àwọn ọmọdé. Abẹ́ abala “Ẹ̀kọ́ Bíbélì” ló wà. Àwọn orin, fídíò àti àwọn eré wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ o ti lo apá yìí rí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ? Tó o bá ń bá òbí tó ní àwọn ọmọ kékeré ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè fi apá yìí hàn án? Èyí sì lè mú kó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan míì tó wà lórí Ìkànnì wa.
Nígbà tí arákùnrin kan ń pín Ìròyìn Ìjọba No. 38, ó fún obìnrin kan ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Obìnrin náà láwọn ọmọ kéékèèké tí wọ́n fẹ́ mọ ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Arákùnrin náà wá jíròrò ohun tó wà nínú ìwé àṣàrò kúkúrú náà pẹ̀lú rẹ̀ ní ṣókí, ó sì fi àdírẹ́sì Ìkànnì wa tó wà lẹ́yìn ìwé náà hàn án. Torí pé obìnrin náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, arákùnrin yìí lo àǹfààní yẹn láti fi ọ̀kan lára àwọn fídíò Kọ́lá han obìnrin náà àtàwọn ọmọ rẹ̀ látorí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ̀.
Arábìnrin kan sọ fún obìnrin kan tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà, tó ní àwọn ọmọ kéékèèké nípa Ìkànnì wa àtàwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ fún àwọn ìdílé. Obìnrin náà àtàwọn ọmọ rẹ̀ wo ìkànnì jw.org. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, obìnrin yìí sọ fún arábìnrin wa pé ńṣe làwọn ọmọ òun ń kọrin “Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà” ní gbogbo ibi tí wọ́n bá wà nínú ilé, ìyẹn ọ̀kan lárá àwọn orin tó wà ní apá tá a pè ní “Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà.”
Di ojúlùmọ̀ apá yìí lórí ìkànnì jw.org, wa ọ̀kan lára àwọn fídíò, orin tàbí àwọn eré tó wà níbẹ̀ jáde, kó o sì gbé e sórí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá lè lo abala orí ìkànnì jw.org yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ẹ ò rí i pé ohun èlò tó wúlò gan-an, tó sì ń jẹ́ ká lè sìnrú fún Olúwa ni ìkànnì jw.org jẹ́!—Ìṣe 20:19.