Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 2
Orin 109 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 19 ìpínrọ̀ 18 sí 23 àti àpótí tó wà lójú ìwé 198 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 8-10 (8 min.)
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 8:13-27 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ta Ló Kọ Bíbélì?—igw ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1 sí 5 (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Ṣègbọràn sí Ọ̀rọ̀ Jésù Tó Wà ní Mátíù 22:21 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa “sìnrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú títóbi jù lọ.”—Ìṣe 20:19.
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù February. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fèsì Tí Ẹni Tó O Fẹ́ Wàásù fún Bá Ń Bínú.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin tuntun “Fún Wa Ní Ìgboyà” àti Àdúrà
Ìránnilétí: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́kọ́ gbọ́ orin yìí lẹ́ẹ̀kan. Lẹ́yìn náà, kí àwọn ará kọ orin tuntun yìí.