Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ó Wúlò Fún Àwa Àtàwọn Ẹlòmíì
Jésù pàṣẹ fún wa pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) Ká bàa lè ‘ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún,’ ètò Ọlọ́run ti sọ àwọn Ìkànnì wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì (ìyẹn watchtower.org, jw-media.org àti jw.org) di ẹyọ kan ṣoṣo. Ìkànnì kan ṣoṣo tá a ti wá tún ṣe lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ yìí la pè ní Ìkànnì jw.org báyìí.—2 Tím 4:5.
“Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Tí A Ń Gbé”: Nǹkan bí ìdá kan nínú mẹ́tà àwọn èèyàn tó wà láyé ló ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó ti wá di ọ̀nà pàtàkì tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rí ìsọfúnni gbà, ní pàtàkì àwọn ọ̀dọ́. Ìkànnì wa yìí máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè wọn. Ó tún ń jẹ́ kí wọ́n mọ ètò Ọlọ́run, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti béèrè pé ká máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn. Torí náà, ó máa ṣeé ṣe láti mú ìhìn rere náà dé àwọn ibi táwọn èèyàn ò ti fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.
“Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè”: Kó lè ṣeé ṣe láti wàásù fún “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” a gbọ́dọ̀ fi onírúurú èdè sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn èèyàn. Ó rọrùn fún àwọn tó bá lọ sórí Ìkànnì jw.org láti rí ìsọfúnni ní nǹkan bí irinwó [400] èdè. Kò sí Ìkànnì míì tó ní ìsọfúnni ní onírúurú èdè tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Ẹ Máa Lò Ó Dáadáa: Yàtọ̀ sí pé a tún Ìkànnì jw.org yìí ṣe ká lè máa fi jẹ́rìí fáwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a tún ṣe é fún àǹfààní àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàápàá. Tó o bá láǹfààní láti máa lọ sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, a rọ̀ ẹ́ pé kó o máa lọ sórí Ìkànnì jw.org kó o lè mọ̀ ọ́n lò. Àwọn àbá nípa bó o ṣe lè lò ó la kọ sísàlẹ̀ yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bó O Ṣe Máa Lò Ó
1 Lórí kọ̀ǹpútà rẹ, tẹ www.jw.org síbi tí wọ́n ń kọ àdírẹ́sì Ìkànnì téèyàn bá fẹ́ lọ sí.
2 O lè tẹ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀, abala tàbí èyíkéyìí lára àwọn ìlujá tó wà níbẹ̀ kó lè gbé ẹ lọ síbi tó o bá fẹ́.
3 O tún lè lọ sórí Ìkànnì www.jw.org lórí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ, tó bá jẹ́ èyí tó o lè fi wọ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Gbogbo ohun tí wọ́n ń rí lórí kọ̀ǹpútà nìwọ náà máa rí.