ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/12 ojú ìwé 2
  • Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ṣé Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ṣeé Gbára Lé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 12/12 ojú ìwé 2

Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ

1. Kí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2013? Kí sì nìdí tá a fi ṣètò àpéjọ náà?

1 Àwọn ohun tó lè pa ẹ̀rí ọkàn wa kú ti pọ̀ gan-an báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìdí nìyẹn tá a fi pe ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ àkànṣe wa ti ọdún 2013 ní “Máa Ṣọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ.” Oṣù February 2013 ni àpéjọ náà máa bẹ̀rẹ̀. (1 Tím. 1:19) A ṣètò àpéjọ yìí kó lè mú kí olúkúlùkù wa fọwọ́ pàtàkì mú bá a ṣe ń lo ẹ̀rí ọkàn wa tó jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu tí Ẹlẹ́dàá wa fún wa.

2. Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo la máa dáhùn ní àpéjọ náà?

2 Wá Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Yìí: Ní àpéjọ náà, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì méje yìí nípa ẹ̀rí ọkàn:

• Àwọn nǹkan wo ló lè wu ẹ̀rí ọkàn léwu?

• Báwo la ṣe lè kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa?

• Kí la lè ṣe tí ọrùn wa fi máa mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ èèyàn gbogbo?

• Tá a bá ń jẹ́ kí ìlànà Bíbélì máa darí ìrònú àti ìṣe wa, irú èèyàn wo nìyẹn ń fi hàn pé a jẹ́?

• Báwo la ṣe lè yẹra fún ṣíṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn àwọn ẹlòmíì?

• Ẹ̀yin ọ̀dọ́, kí lẹ lè ṣe tẹ́ ò fi ní bọ́hùn táwọn èèyàn bá ń rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ ṣe ohun tí kò tọ́?

• Ìbùkún wo ni àwọn tó bá ń jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run máa darí ẹ̀rí ọkàn wọn máa rí?

3. Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú àpéjọ náà?

3 Jèhófà lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè mọ ohun tá a lè ṣe sí àwọn ìgbésẹ̀ tí Sátánì ń gbé láti ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn wa. Baba wa ọ̀run ń sọ fún wa nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísá. 30:21) Àpéjọ àkànṣe yìí jẹ́ ọkàn lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fún wa ní ìtọ́ni yìí. Torí náà, ṣe ètò bó o ṣe máa pésẹ̀ sí àpéjọ yìí látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Fetí sílẹ̀ dáadáa, kó o sì máa ronú nípa bó o ṣe máa fi ìtọ́ni tó o bá rí gbà sílò. Jíròrò ọ̀rọ̀ nípa àpéjọ náà pẹ̀lú ìdílé rẹ. Tá a bá ń fi ìtọ́ni tá a gbọ́ sílò, yóò fún wa lókun ká lè máa “di ẹ̀rí-ọkàn rere mú.” Ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí adùn ayé tó ń kọjá lọ yìí gbà wá lọ́kàn.—1 Pét. 3:16.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́