ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/12 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 24

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 24
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 24
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 12/12 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 24

Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 24

Orin 5 àti Àdúrà

□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

jr orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 6 (30 min.)

□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

Bíbélì kíkà: Sekaráyà 9-14 (10 min.)

No. 1: Sekaráyà 11:1-13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

No. 2: A Kò Pàṣẹ fún Àwọn Kristẹni Láti Máa Pa Sábáàtì Mọ́—td 42A (5 min.)

No. 3: Inú Àwọn Ipò Wo La Ti Lè Fi Ohun Tó Wà Nínú Òwe 15:1 Sílò? (5 min.)

□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

Orin 75

30 min: Bá A Ṣe Lè Lo Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìjíròrò tá a gbé ka ojú ìwé 3 sí 6. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tó wà lójú ìwé 4, ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta tó dá lórí ìdílé kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí Ìjọsìn Ìdílé wọn. Olórí ìdílé náà béèrè pé kí wọ́n sọ ohun táwọn lè jíròrò lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, làwọn ọmọ bá tọ́ka sí àwọn kókó kan tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí tá a pè ní “Àwọn Ọ̀dọ́” lórí Ìkànnì wa. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ti ṣe lo Ìkànnì jw.org tàbí bí wọ́n ṣe fẹ́ lò ó nígbà ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìjọsìn ìdílé wọn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tó wà lójú ìwé 5, ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe wọ Ìkànnì náà lórí ẹ̀rọ alágbèéká kó lè dáhùn ìbéèrè tí ẹnì kan bi í nípa ohun tá a gbà gbọ́. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ohun tó wà lójú ìwé 6, ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́rin kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń jíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa àmọ́ tó jẹ́ pé èdè míì lẹni náà ń sọ, tó sì fẹ́ kà. Kí akéde náà fi Ìkànnì jw.org hàn án lórí ẹ̀rọ alágbèéká rẹ̀ tàbí lórí kọ̀ǹpútà ẹni náà. Kí wọ́n jọ wo ìwé àṣàrò kúkúrú Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́ tàbí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ní èdè ẹni náà, kí wọ́n sì jọ jíròrò rẹ̀. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe lo Ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Orin 101 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́