ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 14-17
  • ÌKÀNNÌ JW.ORG ‘Ẹ̀rí fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ÌKÀNNÌ JW.ORG ‘Ẹ̀rí fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè’
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ó Wúlò Fún Àwa Àtàwọn Ẹlòmíì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—“Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Máa Lo Ìkànnì Wa Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ​—⁠“Ohun Tí Bíbélì Sọ”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 14-17
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

ÌKÀNNÌ JW.ORG ‘Ẹ̀rí fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè’

Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mát. 24:14) Kò sí àní-àní pé ìkànnì jw.org ti di ohun èlò tó ń ṣe bẹbẹ nínú mímú ìhìn rere dé ‘gbogbo orílẹ̀-èdè’ láàárín àkókò kúkúrú tó kù kí òpin dé.

Tọkọtaya míṣọ́nnárì kan tó ń wàásù ní abúlé kan tí wọ́n ti ń pẹja létí òkun ní erékùṣù Solomon Islands pàdé àwọn bàbá àgbàlagbà mẹ́rin kan. Wọ́n rí i pé àwọn bàbá yìí ní fóònù alágbèéká lọ́wọ́, wọ́n wá bi wọ́n bóyá wọ́n mọ Íńtánẹ́ẹ̀tì lò. Wọ́n ní àwọn mọ̀ ọ́n lò. Tọkọtaya yẹn wá kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè dórí ìkànnì jw.org, bí wọ́n ṣe lè débi tí èdè wọn wà, bí wọ́n ṣe lè wa àwọn ìwé ìròyìn àti Bíbélì jáde àti bí wọ́n ṣe lè lo abala tó wà fún àwọn ìdílé àtàwọn ọmọdé. Inú àwọn míṣọ́nnárì yìí máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá ń fi fídíò Gbàdúrà Nígbà Gbogbo han àwọn ọmọ kéékèèké lóde ẹ̀rí. Nígbà tí wọ́n fi fídíò yẹn han àwọn ọmọ kan lọ́jọ́ kan, inú àwọn ọmọ náà dùn débi pé ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sáré kiri tí wọ́n sì ń kọrin pé, “Nígbà gbogbo mo lè gbàdúrà . . .”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìlú Ulaanbaatar, lórílẹ̀-èdè Mòǹgólíà

Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ là ń rí gbà ní oríléeṣẹ́ wa ní New York nílẹ̀ Amẹ́ríkà, díẹ̀ lára wọn rèé:

“Èmi àti ọkọ mi kó lọ sí orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, a sì ń kọ́ èdè Sípáníìṣì kó lè ṣeé ṣe fún wa láti wàásù fún àwọn tá a bá bá pàdé. Nígbàkigbà tí mo bá ti lọ sórí ìkànnì jw.org, mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà torí pé ìkànnì náà ti ràn mí lọ́wọ́ láti fetí sílẹ̀ kí n sì rí ẹ̀kọ́ kọ́. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà níbẹ̀ lónírúurú èdè, àwọn ìwé ìròyìn, ìwé ńlá, orin àti eré. Ẹ ṣeun, ẹ kú iṣẹ́ takuntakun, mo gba tiyín gan-an ni.”—D.H., láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò.

“Mi ò ríran kàwé mọ́, àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ ìkànnì yín gan-an nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà níbẹ̀ tí mo lè tẹ́tí sí. Mò ń rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ má ṣe jẹ́ kó rẹ̀ yín, ẹ jọ̀wọ́ ẹ túbọ̀ máa ka àwọn ìwé yín sórí ẹ̀rọ torí pé mo lè gbọ́ wọn látàárọ̀ ṣúlẹ̀.”—K.G., láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Mo fẹ́ràn ìkànnì jw.org gan-an ni! Ó dùn-ún lò, ó sì ti mú kí ìtara tí mo fi ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ sí i. Ẹni ọdún méjìléláàádọ́rin [72] ni mí, ọdún kẹtàdínláàádọ́ta [47] rèé tí mo ṣèrìbọmi, ó sì ti ju ọgbọ̀n [30] ọdún lọ tí mo ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Mo ní ọmọ mẹ́sàn-án tó ti ṣèrìbọmi mo sì ní ọmọ-ọmọ mẹ́rìndínlógún [16] àti ọmọ-ọmọ-ọmọ mẹ́ta. Ìran mẹ́rin ló ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nínú ìdílé wa. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ tẹ̀mí tó ń bọ́ sákòókò yìí.”—M.T., láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Aago mẹ́rin òru ni mò ń kọ lẹ́tà yìí. Mi ò kì ń sábà rí oorun sùn torí pé mo ní àrùn kan tó máa ń jẹ́ kí iṣan ara mi le gbagidi tó sì ń pọ́n mi lójú lọ́pọ̀lọpọ̀ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ọ̀wọ́n kárí ayé. Síbẹ̀, Jèhófà ò yé bójú tó wa nípa tẹ̀mí, ìdí sì rèé tí mo fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Mo sábà máa ń fi ojú inú wo nǹkan, ìdí nìyí tó fi jọ pé torí tèmi gan-an ni wọ́n fi ṣètò ìkànnì náà lọ́nà tó fani mọ́ra. Mo mọrírì àwọn àtẹ ìsọfúnni, fídíò, àtàwọn fọ́tò tí wọ́n gbé síbẹ̀ pẹ̀lú àlàyé tó ṣe kedere.”—B.B., láti orílẹ̀-èdè New Zealand.

“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gan-an ni. Dókítà ni mí ní àdádó kan ní orílẹ̀-èdè Sri Lanka, mi ò kì ń rí ìwé ìròyìn yín gbà ní èdè mi níbí. Àmọ́, ìkànnì yín ti sọ ìgbà dẹ̀rọ̀ fún mi. Mò ń rí àwọn ìwé yín wà jáde ní èdè mi, mo sì ń kà wọ́n. Ìkànnì yín wà lára àwọn ẹ̀bùn pàtàkì tí Jèhófà fi ta àwọn èèyàn bíi tèmi lọ́rẹ.”—N.F., láti orílẹ̀-èdè Sri Lanka.

“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún iṣẹ́ ńlá tẹ́ ẹ̀ ń ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn lè mọ Jèhófà. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máa bá wa gbé fídíò púpọ̀ sí i sórí jw.org. Àwọn fídíò yẹn ti ran èmi àti ìdílé wa lọ́wọ́ ká lè yanjú àwọn ìṣòro wa. Èyí tó ràn mí lọ́wọ́ jù lọ ni fídíò Gbara Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Yọ Ẹ́ Lẹ́nu —Láì Bá Wọn Jà. Ẹ ṣeun gan-an ẹ kú iṣẹ́ o.”—Y.S., ọmọ ọdún mẹ́sàn-án, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà. Ìkànnì jw.org ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni, pàápàá jù lọ, abala ‘Àwọn Ọ̀dọ́.’ Mo tún fẹ́ràn àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. Mo ní àbúrò obìnrin mẹ́ta, mo sì ń rí iṣẹ́ táwọn fídíò náà ń ṣe lára wọn. Bí mi ò tiẹ̀ sí nítòsí yín, ẹgbẹ́ ará tó wà níṣọ̀kan ni wá, torí ìfẹ́ tá a jọ ní sí Jèhófà. Ẹ ṣé o.”—A.B., láti orílẹ̀-èdè Peru.

Ìsọfúnni Nípa Ìkànnì JW.ORG

  • 316 Èdè ló wà lórí Ìkànnì náà

  • 220,000+ Ni iye ojú ewé tó wà níbẹ̀

  • 600 Ni iye èdè tẹ́ ẹ ti lè rí ìtẹ̀jáde wà níbẹ̀

  • 130 Èèyàn ló ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójúmọ́ láti ohun tó lé ní 230 orílẹ̀-èdè

  • 5,000,000+ Ni iye ìgbà táwọn èèyàn ń wo fídíò níbẹ̀ lóṣù

  • 1,500,000 Ìtẹ̀jáde làwọn èèyàn ń wà lójúmọ́

  • 900,000+ Ni iye àwọn tó ń wọ Ìkànnì náà lójúmọ́ láti 230 ilẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́