Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 24
Orin 50 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 16 ìpínrọ̀ 10 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 28-31 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 30:15–31:8 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Gbogbo Kristẹni Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Òjíṣẹ́—td 37A (5 min.)
No. 3: Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn—lr orí 40 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Máa Lo Ìkànnì Wa Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—‘Ohun Tí Bíbélì Sọ.’” Ìjíròrò. Sọ díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tá a dáhùn tó wà nínú abala yìí lórí Ìkànnì wa. (Lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ.) Ní ṣókí, fi ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú abala “Ohun Tí Bíbélì Sọ” ṣe àṣefihàn. Ní kí àwọn ará dábàá àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo abala yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.
5 min: “Mi Ò Kì Í Bá A Nílé!” Ìjíròrò. Sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká má ṣe jẹ́ kó sú wa tó bá ṣòro fún wa láti bá ẹni tá a bá sọ̀rọ̀ nílé nígbà tá a pa dà lọ.—Mát. 28:19, 20; Máàkù 4:14, 15; 1 Kọ́r. 3:6.
15 min: “Ìwé Ìwádìí Tuntun.” Àsọyé. Ṣe àtúnyẹ̀wò ìtọ́ni nípa “Bí O Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìwádìí” tó wà níbi ọ̀rọ̀ ìṣáájú Ìwé Ìwádìí. Sọ àwọn nǹkan tó wà nínú ìwé tuntun yìí. Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀ bó ṣe ń lo Ìwé Ìwádìí.
Orin 69 àti Àdúrà