Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Máa Lò Ó Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
Máa Sọ Fún Àwọn Èèyàn Pé Kí Wọ́n Lọ Sórí Ìkànnì Wa: Àwọn kan tí kì í fẹ́ gba àwọn ìtẹ̀jáde wa, tí wọn kì í sì í fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ máa ń lọ sórí Ìkànnì jw.org láti wádìí nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè ara wọn. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa sọ fáwọn èèyàn nípa Ìkànnì yìí ní gbogbo ìgbà tá a bá rí i pé ó yẹ.
Máa Fi Dáhùn Ìbéèrè: Nígbà míì àwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa tàbí àwọn ojúlùmọ̀ wa lè béèrè ìbéèrè nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Fi ìdáhùn sí ìbéèrè wọn hàn wọ́n lórí Ìkànnì wa lójú ẹsẹ̀ látorí ẹ̀rọ alágbèéká tàbí kọ̀ǹpútà. Àmọ́, á dáa kẹ́ ẹ ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá wà níbẹ̀ jáde látinú Bíbélì. Bí kò bá sí ẹ̀rọ tẹ́ ẹ lè fi lo Íńtánẹ́ẹ̀tì nítòsí, ṣàlàyé fún ẹni náà nípa bó ṣe lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ̀ lórí Ìkànnì jw.org.—Lọ sí abala “Ẹ̀kọ́ Bíbélì,” kó o tẹ ìlujá tá a pè ní “Ohun Tí Bíbélì Sọ.” Tàbí abala “Nípa Wa,” kó o sì wo “Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè.”
Fi Àpilẹ̀kọ Tàbí Ìtẹ̀jáde Ránṣẹ́ sí Ẹni Tó O Mọ̀: O lè fi ìtẹ̀jáde tó o bá wà jáde látorí Ìkànnì náà ránṣẹ́ sáwọn èèyàn nípasẹ̀ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà. O tún lè wa ohùn tá a ti gbà sílẹ̀ jáde látorí Ìkànnì náà, kó o sì gbé e sórí àwo CD. Ìgbàkigbà tó o bá fún ẹni tí kò tíì ṣèrìbọmi ní odindi ìtẹ̀jáde wa tó o wà jáde lórí ẹ̀rọ, yálà ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé ìròyìn, o lè ròyìn rẹ̀ bí ìwé tó o fi sóde. Àmọ́ ṣá o, má ṣe fi ìtẹ̀jáde ránṣẹ́ lọ́nà tí ẹni tó rí i gbà kò fi ní rí orúkọ rẹ. Má ṣe fi ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ èèyàn papọ̀. Má sì ṣe gbé e sórí Ìkànnì èyíkéyìí míì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.—Lọ sí abala tá a pè ní “Àwọn Ìtẹ̀jáde.”
Fi Ìròyìn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Han Àwọn Èèyàn: Èyí á mú kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn míì túbọ̀ mọyì bí iṣẹ́ wa ṣe gbòòrò tó. Wọ́n á sì túbọ̀ mọ̀ nípa ìṣọ̀kan tó wà láàárín wa kárí ayé. (Sm. 133:1)—Lọ sí abala “Ìròyìn.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bó O Ṣe Máa Lò Ó
1 Lọ sí abala tá a pè ní “Àwọn Ìtẹ̀jáde,” kó o sì yan èyí tó o bá fẹ́ wà jáde lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà níbẹ̀.
2 Tẹ ibi tá a kọ MP3 sí, yóò sì gbé àkòrí gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀ jáde. Tẹ àkòrí èyí tó o bá fẹ́ lára àwọn àpilẹ̀kọ náà, kó o lè wà á jáde tàbí kó o tẹ àmì ▸ láti tẹ́tí sí i látorí Ìkànnì náà.
3 Yan èdè míì tó bá jẹ́ pé ìtẹ̀jáde tó wà ní èdè yẹn lo fẹ́ wà jáde.