Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Fi Ran Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì Lọ́wọ́
Fi Ìkànnì Wa Hàn Án: Tó o bá pàdé ẹni tó ń sọ èdè míì tó yàtọ̀ sí tìrẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìwáàsù, mú un lọ sórí Ìkànnì náà, kó o sì fi bó ṣe lè rí àwọn ìsọfúnni lédè tirẹ̀ hàn án. (Àwọn ohun tá a ní lórí ìkànnì náà láwọn èdè kan ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀.)
Fi Èdè Rẹ̀ Hàn Án Lórí Ìkànnì Náà: Ṣí ọ̀kan nínú àwọn ìwé wa tó wà lórí Ìkànnì fún un. Lọ síbi tá a pè ní “Yan Èdè Tó O Fẹ́,” kó o sì ṣí ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? fún un ní èdè tirẹ̀.
Jẹ́ Kó Tẹ́tí sí Àpilẹ̀kọ Tá A Ti Kà Síbẹ̀: Wa àpilẹ̀kọ tá a ti kà síbẹ̀ jáde ní èdè ẹni náà, kó o sì ṣí i fún un kó lè tẹ́tí sí i. Tó o bá ń kọ́ èdè míì, o lè túbọ̀ mọ èdè náà tó o bá ń tẹ́tí sí àwọn ìtẹ̀jáde tá a ti kà síbẹ̀ ní èdè yẹn.—Lọ sí abala “Àwọn Ìtẹ̀jáde,” kó o sì tẹ ìlujá tá a pè ní “Àwọn Ìwé Ńlá Àtàwọn Ìwé Pẹlẹbẹ” tàbí “Àwọn Ìwé Ìròyìn.”
Fi Ìkànnì Wa Wàásù Fáwọn Adití: Tó o bá bá adití pàdé, fi fídíò orí kan nínú Bíbélì hàn án, tàbí ìwé pẹlẹbẹ, àṣàrò kúkúrú tàbí ìtẹ̀jáde míì tá a gbé síbẹ̀ ní èdè àwọn adití.—Lọ sí abala “Àwọn Ìtẹ̀jáde,” kó o tẹ ìlujá tá a pè ní “Èdè Àwọn Adití.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Bó O Ṣe Máa Lò Ó
1 Tẹ àmì ▸ láti gbọ́ àpilẹ̀kọ tá a ti kà síbẹ̀ (tó bá wà ní èdè rẹ) tàbí kó o tẹ èyí tó o bá fẹ́ wà jáde lára àwọn ìtẹ̀jáde tó wà níbẹ̀.
2 O lè yan èdè míì ní ibi tá a pè ní “Yan Èdè Tó O Fẹ́.”
3 O lè tẹ ibi tá a kọ “Lọ Síwájú” sí tàbí kó o yan ìlujá míì lára àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀ kó o lè ka àpilẹ̀kọ tàbí orí míì.