Ohun Tó Lè Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣiṣẹ́ sin aráàlú nípa títan ìhìn rere kálẹ̀. (Fílí. 2:17) Kí èyí lè ṣeé ṣe, àwọn ìwé pẹlẹbẹ tí a sábà máa ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwé àṣàrò kúkúrú àtàwọn àpilẹ̀kọ ní ogún èdè la ti fi sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì báyìí. Àdírẹ́sì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni: www.watchtower.org. A ò ṣètò ibùdó ìsọfúnni yìí fún pínpín àwọn ìtẹ̀jáde lọ́ọ́lọ́ọ́ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìdí tí a fi ṣètò rẹ̀ ni láti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún gbogbo àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí láti ní ìsọfúnni pípéye nípa ohun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ni látinú Bíbélì.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ti fi ohun pàtàkì kan sí ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láfikún sí i. Èyí ni ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? tó wà ní okòó-lé-nígba [220] èdè. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde January 1 àti January 8, 2004, a ti ń kọ àdírẹ́sì ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sí ojú ewé tó gbẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní gbogbo èdè.
Báwo lo ṣe lè lo àdírẹ́sì orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yìí? Ó ṣeé ṣe kó o pàdé ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn, àmọ́ tó jẹ́ pé èdè mìíràn nìkan ló gbọ́. Bó bá jẹ́ ẹni tó máa ń ṣàyẹ̀wò ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè tọ́ka sí àdírẹ́sì ibùdó ìsọfúnni wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, èyí tó wà lójú ewé tó gbẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún un láti ṣàyẹ̀wò ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ní èdè ìbílẹ̀ rẹ̀, títí dìgbà tí wàá fi lè padà wá láti fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè rẹ̀. Tàbí kẹ̀, o lè sọ fún ìjọ tàbí àwùjọ tó ń bójú tó èdè ẹni náà pé kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ wò.