Bó O Bá Nílò Ìtẹ̀jáde Ti Èdè Ilẹ̀ Òkèèrè Ní Kíákíá
Nígbà míì, a máa ń bá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ìtẹ̀jáde wa ní èdè ilẹ̀ òkèèrè pàdé, ó sì lè jẹ́ pé a ò ní irú ìtẹ̀jáde bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ wa. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé bí Íńtánẹ́ẹ̀tì bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, tó o sì ní ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, o lè tẹ àwọn ìwé wa jáde ní nǹkan bí irinwó [400] èdè? Bó o ṣe máa ṣe é nìyí:
• Lọ sí ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org.
• Ní apá ọ̀tún ojúde ìkànnì náà, ìyẹn home page, wàá rí àwọn èdè mélòó kan tá a tò síbẹ̀. Tẹ àwòrán àgbáyé tó wà níbẹ̀ kó o lè rí gbogbo èdè tá a fi síbẹ̀.
• Yan èdè tó o fẹ́. Wàá rí àwọn ìtẹ̀jáde tó o lè tẹ̀ jáde lédè náà, ìyẹn àwọn bí ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn àpilẹ̀kọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èdè tó o yàn la fi kọ àwọn ìtẹ̀jáde tó o máa rí, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí èdè tá a fi kọ àkòrí ìtẹ̀jáde náà bá ṣòro fún ẹ láti kà.
• Yan ìtẹ̀jáde tó o bá fẹ́, ó máa gbé ìtẹ̀jáde náà wá sórí ẹ̀rọ fún ẹ kó o lè tẹ̀ ẹ́ jáde.
Àwọn ìtẹ̀jáde mélòó kan ló wà lórí ìkànnì wa, o lè gba àwọn ìtẹ̀jáde míì tó o bá nílò nípasẹ̀ ìjọ. Bó bá ti dá ẹ lójú pé onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé wa, ohun tó máa dáa jù ni pé kó o béèrè fún àwọn ìwé náà nínú ìjọ.