Fífi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè
1. Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ ìjọ fi nílò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lédè àjèjì?
1 Ní ibi púpọ̀, a ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí àwọn èèyàn tó ti ilẹ̀ ibòmíràn wá ní ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí máa ń tètè lóye òtítọ́ náà nígbà tá a bá fi èdè àbínibí wọn kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ètò wo ló wà láti rí i pé àwọn olùfìfẹ́hàn rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a gbé ka Bíbélì gbà ní èdè tí wọ́n lóye jù lọ?
2. Báwo ló ṣe yẹ kí a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà tí ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ kan náà?
2 Ìgbà Tó Yẹ Ká Fi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni: Nígbà tí ìjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ kan náà, kí àwọn alàgbà ìjọ wọ̀nyí fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alábòójútó iṣẹ́-ìsìn láti ṣe ètò kan tí àwọn ìjọ náà jọ fọwọ́ sí, kí a bàa lè jẹ́rìí kúnnákúnná fún àwùjọ kọ̀ọ̀kan tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà táwọn akéde bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, wọn kì í sábà fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lédè táwọn tó wà nínú ìjọ mìíràn ń sọ lọni. Àmọ́ ṣá o, nígbà táwọn akéde bá ń wàásù láìjẹ́ bí àṣà tàbí ní àwọn ibi tí àwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí, wọ́n lè fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lédè táwọn tó wà lágbègbè náà ń sọ lọni.
3. Ìgbà wo ló yẹ kí ìjọ gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní èdè àjèjì sọ́wọ́?
3 Ìgbà Tó Yẹ Kí Ìjọ Gba Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Sọ́wọ́: Kí la lè ṣe nígbà táwọn èèyàn tó pọ̀ díẹ̀ tó ń sọ èdè àjèjì bá wà lágbègbè kan, àmọ́ tí kò sí ìjọ kankan tó ń sọ èdè ọ̀hún? Nínú àwọn ipò wọ̀nyí, ìjọ lè gba díẹ̀ lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní èdè náà sọ́wọ́, irú bí àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè àti Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run àti ìwé Ìmọ̀. Àwọn akéde lè fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí lọni nígbàkigbà tí wọ́n bá bá àwọn èèyàn tó lè kà á pàdé.
4. Báwo la ṣe lè rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tí ìjọ ò ní lọ́wọ́ gbà?
4 Bí A Ṣe Lè Kọ̀wé Béèrè fún Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́: Bí ìjọ ò bá ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tí olùfìfẹ́hàn kan lè kà, báwo la ṣe lè rí ìwé tó wà lédè náà gbà? Kí àwọn akéde wádìí lẹ́nu ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa irú àwọn ìwé tó wà lọ́wọ́ kí a bàa lè kọ̀wé béèrè fún èyí tí wọ́n nílò pa pọ̀ mọ́ ti ìjọ nígbà tá a bá tún fẹ́ kọ̀wé béèrè fún ìwé.
5. Kí nìdí tí a fi ń fáwọn èèyàn ní ìtẹ̀jáde Kristẹni?
5 Ǹjẹ́ kí a máa lo àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni lọ́nà tó gbéṣẹ́ láti ran “gbogbo onírúurú ènìyàn” lọ́wọ́, láìka èdè tí wọ́n ń sọ sí, ‘láti wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, kí a sì gbà wọ́n là.’—1 Tím. 2:3, 4.