Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ọgbọ́n Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
1, 2. Kí làwọn èèyàn sọ nípa àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?
1 “Láti ọdún 1965 ni mo ti ń ka àwọn ìtẹ̀jáde yín. Mo máa ń yẹ ohun tí mo kà wò nínú Bíbélì mo sì rí i pé gbogbo ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé yín ló bá Bíbélì mu. Ó pẹ́ tó ti máa ń wù mí láti mọ òtítọ́ nípa ẹni tí Ọlọ́run àti Jésù jẹ́, mo wá lè fi gbogbo ẹnu sọ ọ́ pé ìwé yín àti Bíbélì ló jẹ́ kí n rí ìdáhùn tòótọ́.” Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni ọkùnrin kan kọ sí oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú lẹ́tà yìí kan náà ló ti lóun fẹ́ kí ẹnì kan wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
2 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni kì í ṣe abaraá-móore-jẹ bíi ti ọkùnrin yẹn, wọ́n mọrírì àwọn ohun tá a lè fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mát. 24:45) Lọ́dọọdún, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ là ń tẹ̀ jáde láti lè ran àwọn ọlọ́kàn títọ́ èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá “sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ọ̀nà tó bọ́gbọ́n mu wo la wá lè gbà máa lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3. Kí la lè ṣe táwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ò fi ní máa ṣòfò?
3 Má Ṣe Jẹ́ Kó Ṣòfò: Tó bá pẹ́ tá a ti ń gbàwé jọ, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ táá ti wà lọ́wọ́ wa lè ti pọ̀ ju iye tá a nílò lọ. Kí la wá lè ṣe káwọn ìtẹ̀jáde wa ṣíṣeyebíye yìí má bàa máa ṣòfò? Ó yẹ ká máa fọgbọ́n ṣe é nígbà tá a bá ń gbàwé tá a máa lò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Dípò tá a ó fi gba ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde láti fi sóde, a kàn lè gba ẹyọ kan tàbí méjì, ká wá lọ gbà sí i lẹ́yìn tá a bá ti fi èyí tá a kọ́kọ́ gbà sóde. Èyí ò ní jẹ́ kí ilé wa kún tìrìgàngàn fáwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń sẹ́ kù sí wa lọ́wọ́. Bákan náà, bí a bá ṣì ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ò tíì fi sóde nílé, ì bá dáa tá a bá lè dín iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí kù.
4. Kí ni ṣíṣe bí ìjọ kan bá ní àwọn ìtẹ̀jáde tó pọ̀ jù lọ́wọ́?
4 Àwọn Ìwé Tó Bá Pọ̀ Jù Lọ́wọ́: Bí ìjọ bá ní àwọn ìtẹ̀jáde kan tó pọ̀ jù iye tí wọ́n nílò, olùṣekòkárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lè béèrè lọ́wọ́ àwọn ìjọ mìíràn tó wà nítòsí bí wọ́n bá lè lo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ṣẹ́ kù náà. Àwọn akéde sì lè fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ti pẹ́ lọ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa, àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn míì. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ lè fẹ́ láti fi àwọn ìtẹ̀jáde tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ wọ̀nyẹn kún àwọn ìwé tó wà níbi tí wọ́n ń kó àwọn ìtẹ̀jáde tí ètò Ọlọ́run pèsè sí.
5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa?
5 A fẹ́ kí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ṣe àṣeyọrí ohun tá a tìtorí rẹ̀ tẹ̀ ẹ́ jáde, ìyẹn ni láti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ sí i nípa àwọn ohun arabaríbí tí Jèhófà fẹ́ gbé ṣe. Bí Jésù ò ṣe fẹ́ fi oúnjẹ tó ṣẹ́ kù ṣòfò lẹ́yìn tó ti bọ́ ogunlọ́gọ̀ lọ́nà iṣẹ́ ìyanu, ohun tó gbọ́dọ̀ jẹ́ àfojúsùn tiwa náà ni láti fọgbọ́n lo àwọn ìwé wa ṣíṣeyebíye tá à ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó dáa. (Jòh. 6:11-13) Ọ̀rọ̀ agbẹ̀mílà tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa ò lè sún ọkàn àwọn olódodo èèyàn ṣíṣẹ́ nígbà tó bá ṣì wà níbi ìkówèésí wa tàbí nínú àpò ìwé wa. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ lo òye nígbà tá a bá ń gbàwé tá a máa lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ká sì máa lò ó lọ́nà tó ṣe àwọn èèyàn láǹfààní.—Fílí. 4:5.