ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/00 ojú ìwé 8
  • Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fúnrúgbìn ní Yanturu, Ṣùgbọ́n Lo Ìfòyemọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ètò Mímú Kí Ìpínkiri Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rọrùn Tí A Ṣe
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Máa Fi Ìmọrírì Àtọkànwá Hàn fún Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 3/00 ojú ìwé 8

Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n

1 Pípín ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́, July 1, 1879, kiri ló bẹ̀rẹ̀ lílo àwọn ìwé wa lọ́nà táa fètò ṣe. Látìgbà yẹn wá, a ti tẹ onírúurú ìwé, a sì ti pín wọn kiri lọ́pọ̀ jaburata.

2 Ètò Ọrẹ Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́: Ní December 1999, a ṣàlàyé pé a óò máa pèsè ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn akéde àti fún àwọn ará ìta tó bá nílò wọn, wọ́n á sì máa fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìwé náà ni, ìyẹn ni pé, a ò ní máa béèrè fún iye owó kan ní pàtó kí wọ́n tó lè rí ìwé wa gbà. Nígbà tí a bá fi ìwé lọ àwọn èèyàn, a óò gba ọrẹ àtinúwá láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ títẹ ìhìn rere jáde tí a ń ṣe kárí ayé. A ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà yóò bù kún ètò yìí.—Fi wé Mátíù 6:33.

3 Bí A Óò Ṣe Máa Ṣe É Lóde Ẹ̀rí: A óò máa lo àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ táa múra sílẹ̀ dáadáa láti ru ìfẹ́ sókè. Bẹ́nì kan ò bá f ìfẹ́ hàn, kò yẹ ká fún un ní ìwé. A ò fẹ́ fi ìwé wa kankan ṣòfò nípa fífún àwọn tí kò f ìfẹ́ hàn. Lọ́wọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, níbi tí onílé bá ti fìfẹ́ hàn, tó sì gbà láti ka ìwé náà, a lè fún un. A fẹ́ lo àwọn ìwé wa lọ́nà ọgbọ́n.

4 Bí o bá ti fi ìwé wa han onílé, o lè sọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí: “Bí ìwọ yóò bá ka ìwé yìí, inú mi á dùn láti fún ẹ.” Ó ṣeé ṣe kí onílé béèrè pé: “Èló lowó ẹ̀?” O lè fèsì pé: “Kì í ṣe ọjà là ń tà. A kì í ta ìwé yìí. Iṣẹ́ táa wá ṣe ládùúgbò yín lónìí náà ni wọ́n ń fínnúfíndọ̀ ṣe ní igba àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n ilẹ̀ yíká ayé láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tó lọ́ sí ìyè. Bóo bá fẹ́ láti fi ọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí, inú mi á dùn láti gbà á.”

5 Nígbà tí o bá ń fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn, o lè béèrè ìbéèrè nípa àpilẹ̀kọ kan pàtó, kí o sì wá sọ pé: “Màá fẹ́ kí o ka ìdáhùn nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti ka ìwé ìròyìn méjèèjì yìí, inú mi á dùn láti fún ẹ.” Bó bá gbà wọ́n, o lè fi kún un pé: “Inú mi dùn pé mo rí ẹ bá sọ ọ̀rọ̀ yìí. Mo ronú pé wàá rí nǹkan kọ́ nínú ìwé wọ̀nyí. Ṣóo tiẹ̀ rí i, màá fẹ́ láti padà wá lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ kí n lè mọ èrò ẹ. Wàá rí i pé èdè méjìléláàádóje [132] la fi ń tẹ Ilé Ìṣọ́, a sì ń pín ẹ̀dà tó jú mílíọ̀nù méjìlélógún [22,000,000] kiri kárí ayé. Ọrẹ àtinúwá nìkan la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí. Bí ìwọ náà bá fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, inú wa á dùn láti gbà á.”

6 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó lè má bọ́gbọ́n mu láti sọ pé ọrẹ la fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé tí a ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, onílé kan tó fìfẹ́ hàn lè béèrè pé: “Ṣé ẹ̀ ń fún èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́ ni?” A lè fèsì pé: “Bí o bá fẹ́ láti ka ìtẹ̀jáde yìí, tí o sì fẹ́ ní i, a jẹ́ pé o lè máa mú un lọ. Màá fẹ́ ya ọ̀dọ̀ ẹ lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ká lè jíròrò nípa ohun táa sọ̀rọ̀ lé lórí, kí n sì túbọ̀ sọ fún ẹ nípa iṣẹ́ yìí tí a ń ṣe kárí ayé.” Nígbà tí o bá padà wá ṣèbẹ̀wò láwọn ìgbà mìíràn, o lè sọ fún onílé nípa bí a ṣe ń gbé ìnáwó iṣẹ́ yìí.

7 Tàbí kẹ̀, onílé lè gba ìwé náà lójú ẹsẹ̀ kó sì sọ pé, “O ṣeun.” O lè sọ pé: “Kò tọ́pẹ́. Mo mọ̀ pé wàá gbádùn ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló máa ń ṣe kàyéfì pé báwo la ṣe ń rí owó ná fún iṣẹ́ yìí, níwọ̀n bí a ti ń ṣe é kárí ayé. Ọ̀pọ̀ tó gba àwọn ìtẹ̀jáde wa ló dúpẹ́ fún ohun tí wọ́n á rí kọ́ nínú ẹ̀, wọ́n sì fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn kó lè ṣeé ṣe láti túbọ̀ máa pín ìwé wọ̀nyí kiri. Bí àwọn èèyàn bá ṣe èyí, inú wa máa ń dùn láti gbà á.”

8 Ṣé Ẹni Yẹn Nífẹ̀ẹ́ sí I Lóòótọ́? Ó dájú pé ète wa kì í ṣe pé ká kàn máa pín àwọn ìwé wa kiri ṣáá. A fẹ́ kí àwọn ìwé wọ̀nyí ṣàṣeyọrí ohun tí wọ́n wà fún, ìyẹn ni pé, kí wọ́n ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn àgbàyanu ètè Jèhófà. Ìfiṣòfò láá jẹ́ bí a bá fún àwọn èèyàn tí kò mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí ní ìwé wa. (Héb. 12:16) Bóo ṣe ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri yóò méso jáde bí o bá lè mọ ìgbà tí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí wọn lóòótọ́. Báwo lẹnì kan ṣe ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn? Àmì kan tó dáa ni pé ẹni náà á fi inú rere hàn, á sì múra tán láti bá ẹ jíròrò. Tàbí, bí ẹni náà bá fetí sílẹ̀ nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀, tó ń dáhùn àwọn ìbéèrè tí o bi í, tó sì ń sọ èrò ọkàn rẹ̀, èyí ń fi hàn pé ọkàn rẹ̀ wà níbi ìjíròrò náà. Bó bá bá ẹ sọ̀rọ̀ bí ọmọlúwàbí èèyàn, bí ọ̀rẹ́, ìyẹn ń fi hàn pé ó lẹ́mìí tó dáa. Bó bá ń fọkàn bá Bíbélì tí o ń kà lọ, ó lè jẹ́ ẹ̀rí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà, á dáa pé kí o béèrè bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò bá ka ìwé tí o fún un. Síwájú sí i, o lè sọ pé wàá fẹ́ padà wá kí ẹ lè máa bá ìjíròrò nìṣó. Bó bá gbà bẹ́ẹ̀, ìyẹn tún jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí i. Bí o bá rí ẹ̀rí pé ẹni kan ní ìfẹ́ tòótọ́ bí èyí, ó ṣeé ṣe kí ẹni náà lo ìwé tí o bá fún un dáadáa.

9 Ìyípadà tí a ṣe nínú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe iṣẹ́ wa yìí túbọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé “àwa kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (2 Kọ́r. 2:17) Ó tún jẹ́ ẹ̀rí pé a kì í ṣe apá kan ayé.—Jòh. 17:14.

10 Bí ìparun Bábílónì Ńlá ṣe ń sún mọ́lé, pákáǹleke túbọ̀ ń pọ̀ sí i fún gbogbo ẹ̀sìn ni. Olórí àníyàn wa ni pé kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà kárí ayé, tó jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì, máa bá a nìṣó láìsí ìdíwọ́, kí a sì mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn rí ìgbàlà.—Mát. 24:14; Róòmù 10:13, 14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́