ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/11 ojú ìwé 2
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Máa Fi Ìmọrírì Àtọkànwá Hàn fún Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ọgbọ́n Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 12/11 ojú ìwé 2

Àpótí Ìbéèrè

◼ Báwo la ṣe lè mọ̀ tó bá yẹ ká fún ẹnì kan ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́?

Ohun pàtàkì tá a gbọ́dọ̀ kíyè sí ni bóyá onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Tó bá fi ìfẹ́ hàn lóòótọ́, a lè fún un ní ìwé ìròyìn méjì, ìwé pẹlẹbẹ kan, ìwé ńlá kan tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí tá a bá fi ń lọni. Ohun tá a máa ṣe náà nìyí kódà tá a bá kíyè sí i pé kò lówó tó lè fi ṣe ọrẹ fún iṣẹ́ kárí ayé. (Jóòbù 34:19; Ìṣí. 22:17) Àmọ́, a kò ní fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ṣíṣeyebíye sílẹ̀ fún àwọn tí kò mọyì wọn.—Mát. 7:6.

Báwo ni onílé kan ṣe lè fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa? Tó bá ṣe tán láti dá sí ọ̀rọ̀ tá à ń bá a sọ, ìyẹn fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. A lè gbà pé ó nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò wa tó bá fetí sílẹ̀ nígbà tá à ń bá a sọ̀rọ̀, tó ń dáhùn ìbéèrè tá a bi í, tó sì ń sọ èrò rẹ̀. A lè gbà pé ó fọwọ́ gidi mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó bá ń fojú bá ẹsẹ Bíbélì tá à ń kà lọ. Ó sábà máa ń dára pé kí a béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bóyá ó máa ka ìwé tá a fẹ́ fún un. Àwọn akéde ní láti lo làákàyè láti mọ̀ bóyá ẹnì kan fìfẹ́ hàn ní ti gidi. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà, kò ní bọ́gbọ́n mu pé ká kàn máa há àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ tàbí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa fún ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa. Tí kò bá dá wa lójú pé ẹnì kan ní ojúlówó ìfẹ́, ohun tó máa dára jù ni pé ká fún onítọ̀hún ní ìwé ìkésíni tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú.

Bákan náà, kì í ṣe bí iye owó tí akéde kan fi ṣètìlẹ́yìn ṣe pọ̀ tó tàbí bó ṣe kéré tó ló máa pinnu iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó máa gbà, àmọ́ ohun tó máa pinnu rẹ̀ ni bí iye ìwé tó máa fẹ́ láti lò ní òde ẹ̀rí ti pọ̀ tó. Nígbà tá a bá fi owó sínú àpótí ọrẹ, kì í ṣe owó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ là ń san o, àmọ́ ńṣe là ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Láìka bá a ṣe lówó lọ́wọ́ sí, ìmọrírì tá a ní ló máa mú ká fi owó ṣe ìtìlẹ́yìn fún ire Ìjọba Ọlọ́run látinú àìní wa, kì í ṣe látinú àṣẹ́kùsílẹ̀ wa. (Máàkù 12:41-44; 2 Kọ́r. 9:7) Ìmọrírì kan náà yìí ló máa mú ká gba ìwọ̀nba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a nílò, kó má bàa jẹ́ pé à ń lo àwọn ohun tí ètò Ọlọ́run fún wa nílòkulò.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 2]

Àwọn akéde ní láti lo làákàyè láti mọ̀ bóyá ẹnì kan fìfẹ́ hàn ní ti gidi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́