ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb17 February ojú ìwé 4
  • Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ìmọrírì Àtọkànwá Hàn fún Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Ẹ Jẹ́ Ká Máa Fi Ọgbọ́n Lo Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpótí Ìbéèrè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Fífi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni ní Ìpínlẹ̀ Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
mwb17 February ojú ìwé 4
Obìnrin kan tẹ́tí sílẹ̀ bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! lọ̀ ọ́

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fọgbọ́n Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa

Jésù kọ́ wa pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mt 10:8) À ṣì ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yẹn títí dòní, ìdí nìyẹn tá a fi ń fún àwọn èèyàn ní Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde wa láìdáye lé e. (2Kọ 2:17) Síbẹ̀ náà, àwọn òtítọ́ pàtàkì látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde yìí. Kì í ṣe owó kékeré là ń ná láti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde yìí, ó sì tún máa ń gba ìsapá láti kó wọn ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ jákèjádò ayé. Torí náà, ìwọnba tá a nílò ni ká máa gbà.

Ó tún yẹ ká máa lo òye nígbà tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní ìwé wa, pàápàá nígbà tá a bá ń wàásù níbi térò pọ̀ sí. (Mt 7:6) Dípò tí a ó kàn fi máa fún gbogbo àwọn tó ń kọja ní ìwé, ó dáa ká bá wọn sọ̀rọ̀ díẹ̀, ká lè mọ̀ bóyá wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Ká tó lè fún ẹnì kan ní ìwé wa, ó kéré tán, ó yẹ kó ṣe ọ̀kan lára àwọn kókó tó wà nínú àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ yìí. Tí kò bá dá ẹ lójú pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ó máa dáa kó o kúkú fún un ní àṣàrò kúkúrú. Àmọ́ ṣá o, tó bá ní ká fún òun ní ìwé ìròyìn tàbí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ míì, kò burú tá a bá fún un ní ẹ̀dà kan.​—Owe 3:27, 28.

ṢÉ ẸNI NÁÀ . . .

  • fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ò ń sọ̀rọ̀?

  • dá sí ìjíròrò náà?

  • gbà láti ka ìtẹ̀jáde náà?

  • ṣe ìtìlẹ́yìn?

  • mọ rírì ohun tó gbọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́