ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 58-62
“Pòkìkí Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà Níhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà”
“Ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà” kì í ṣe ọdún orí kàlẹ́ńdà
Ó jẹ́ àkókò kan tí Jèhófà fún àwọn ọlọ́kàn tútù láǹfààní láti gbọ́ ìkéde òmìnira, kí wọ́n sì ṣe ìpinnu
Ní ọ̀rúndún kìíní, ọdún ìtẹ́wọ́gbà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni, ó sì parí ní “ọjọ́ ẹ̀san” Jèhófà, ìyẹn lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Jerúsálẹ́mù pa run
Ní àkókò wa, ọdún ìtẹ́wọ́gbà bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù gorí ìtẹ́ lọ́run ní ọdún 1914, ó sì máa parí nígbà ìpọ́njú ńlá
Jèhófà ń fi “igi ńlá òdodo” bù kún àwọn èèyàn rẹ̀
Àwọn igi tó ga jù láyé sábà máa ń dàgbà pa pọ̀, wọ́n sì máa ń ran ara wọn lọ́wọ́
Àwọn ìtàkùn wọn máa ń so kọ́ra, èyí sì máa ń mú kí wọ́n lè fìdí múlẹ̀ dáadáa débi tí ìjì ò fi ní lè fà wọ́n tu
Àwọn igi ńlá máa ń ṣíji bo àwọn igi kéékèèké tó wà lábẹ́ wọn, àwọn ewé tó sì ń jábọ́ lórí rẹ̀ máa ń mú kí ilẹ̀ lọ́ràá
“Igi ńlá òdodo” náà, ìyẹn àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ń ṣètìlẹ́yìn fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni kárí ayé, wọ́n sì ń dáàbò bò wọ́n