Ẹwà Ìṣẹ̀dá Jèhófà
“Àwọn Igi Jèhófà Ní Ìtẹ́lọ́rùn”
Ǹ JẸ́ o ti wà nínú igbó kìjikìji kan rí níbi tí ìtànṣán oòrùn ti rọra là gbà àárín àwọn igi gíga tó wà níbẹ̀? Ǹjẹ́ o gbọ́ ìró atẹ́gùn bó ṣe ń fẹ́ yaa gba àárín àwọn ewé yẹn?—Aísáyà 7:2.
Láwọn àgbègbè kan lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àkókò kan wà nínú ọdún tí ewé àwọn igi kan máa ń ní àwọ̀ pupa, àwọ̀ olómi ọsàn, àwọ̀ yẹ́lò, àtàwọn àwọ̀ mìíràn lóríṣiríṣi. Àní, ńṣe ló máa ń dà bíi pé a dáná sára àwọn igi wọ̀nyí! Ẹ ò ri bí èyí ṣe bá èrò tó wà nísàlẹ̀ yìí mu tó, pé: “Ẹ tújú ká, ẹ̀yin òkè ńláńlá, pẹ̀lú igbe ìdùnnú, ìwọ igbó àti gbogbo ẹ̀yin igi tí ń bẹ nínú rẹ̀!”—Aísáyà 44:23.a
Bí a bá dá gbogbo ayé sí mẹ́ta, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìdá kan nínú rẹ̀ ni igbó wà. Igbó kìjikìji àti ọ̀pọ̀ àwọn ohun abẹ̀mí tó wà nínú rẹ̀ ń fògo fún Oníṣẹ́ Ọnà àti Ẹlẹ́dàá wọn, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Onísáàmù tá a mí sí náà kọrin pé: “Ẹ yin Jèhófà . . . ẹ̀yin igi eléso àti gbogbo ẹ̀yin kédárì.”—Sáàmù 148:7-9.
Ìwé The Trees Around Us sọ pé: “Igi wúlò púpọ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn, ó sì máa ń dùn-ún wò.” Igbó máa ń dáàbò bò wá, ó máa ń gbé ẹ̀mí wa ró, ó sì tún máa ń sọ omi wa di mímọ́. Àwọn igi tún máa ń sọ atẹ́gùn di mímọ́. Nípasẹ̀ ọ̀nà àgbàyanu tí àwọn ewéko gbà ń pèsè oúnjẹ wọn èyí tí à ń pè ní photosynthesis, àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ewé á yí afẹ́fẹ́ carbon dioxide, omi, èròjà mínírà (mineral) àti ìtànṣán oòrùn sí èròjà tí igi nílò àti afẹ́fẹ́ ọ́síjìn (oxygen).
Igbó jẹ́ ohun àgbàyanu tó bá kan ti ẹwà àti iṣẹ́ ọnà. Àwọn igi ńláńlá wà lára àwọn ohun tó sábà máa ń dùn-ún wò jù lọ nínú igbó. Àìlóǹkà ewéko tí kì í yọ òdòdó, ewédò, àjàrà, àwọn igi kéékèèké àti ewéko ló sì ń gbilẹ̀ sí i. Irú àwọn ohun ọ̀gbìn yìí gbára lé àyíká tí àwọn igi bá wà, ìbòòji abẹ́ àwọn igi yẹn làwọn ohun ọ̀gbìn yẹn fi ń ṣọlá, wọ́n sì máa ń lo ọ̀rinrin tó wá láti ara àwọn igi ńlá bẹ́ẹ̀.
Nínú àwọn igbó tó ní àwọn igi tó máa ń wọ́wé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá ewé tó máa ń rẹ̀ nínú sarè oko kan tó bá di apá ìparí ọdún. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èwé wọ̀nyí? Àwọn kòkòrò, olú, ekòló àtàwọn ẹ̀dá alààyè tín-tìn-tín mìíràn yóò sọ àwọn ewé tó rẹ̀ sílẹ̀ yìí di ajílẹ̀, èròjà pàtàkì kan tó ń sọ ilẹ̀ di ọlọ́ràá. Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sí ohun tó ṣòfò nígbà táwọn òṣìṣẹ́ tí a kò lè rí yìí bá ń tún ilẹ̀ ṣe fún ohun ọ̀gbìn tuntun.
Lábẹ́ àwọn èwé tó ti rà yẹn ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun abẹ̀mí ti ń gbá yìn-ìn. Ìwé The Forest, sọ pé: “A lè rí tó egbèje dín àádọ́ta [1,350] ìṣẹ̀dá . . . tá a bá gbẹ́ ilẹ̀ tó fẹ̀ tó ọgbọ̀n sẹ̀ǹtímítà dọ́gba-dọ́gba níbùú lóròó tó sì jìn tó sẹ̀ǹtímítà méjì àti ààbọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ẹgbàágbèje àwọn ẹ̀dá alààyè tín-tìn-tín tó wà nínú ẹ̀kúnwọ́ kan erùpẹ̀.” Síwájú sí i, àwọn ẹranko afàyàfà, oríṣiríṣi ẹyẹ, àwọn kòkòrò àtàwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú kún inú igbó bámúbámú. Ta ló yẹ ká fògo fún nítorí oríṣiríṣi ohun ẹlẹ́wà wọ̀nyí? Ẹlẹ́dàá àwọn nǹkan wọ̀nyí sọ̀rọ̀ tó bá a mu pé: “Tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó, àwọn ẹranko tí ń bẹ lórí ẹgbẹ̀rún òkè ńlá.”—Sáàmù 50:10.
A dá agbára àrà ọ̀tọ̀ mọ́ àwọn ẹranko kan tó fi jẹ́ pé wọ́n lè wà lójú kan fún àkókò gígùn láìjẹ láìmu, wọn ò sì ní kú jálẹ̀ àkókò òtútù àti jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí kò bá sí oúnjẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ẹranko ló lè ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, nígbà tí otútù bá mú gan-an, o lè rí agbo ẹtu níbi tí wọ́n ti ń fò kiri lórí pápá. Ẹtu kì í wà lójú kan, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kó oúnjẹ pa mọ́, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bó o ṣe lè rí i nínú àwòrán tó wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì yìí, ńṣe ni wọ́n máa ń wá ìjẹ lára ẹ̀ka igi tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ àti lára ìrudi.
Ọ̀nà púpọ̀ ni Ìwé Mímọ́ ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun ọ̀gbìn. Gẹ́gẹ́ bí òǹkà kan ṣe sọ, o fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádóje [130] irúgbìn tá a dárúkọ nínú Bíbélì, títí kan nǹkan bí ọgbọ̀n igi. Nígbà tí Michael Zohary tó jẹ́ onímọ̀ ewéko ń sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ohun tí a dárúkọ nínú Bíbélì yìí ti ṣe pàtàkì tó, ó sọ pé: “Kódà, bá a ṣe sọ̀rọ̀ nípa ìwúlò igi fún gbogbo ohun alààyè nínú àwọn ìwé àkàgbádùn kò tó bá a ṣe sọ ọ́ nínú Bíbélì.”
Ẹ̀bùn kíkọyọyọ látọ̀dọ̀ Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ làwọn igi àtàwọn igbó kìjikìji jẹ́. Ká sọ pé ìwọ náà ti lo àkókò gígùn nínú igbó rí, ó dájú pé wàá fara mọ́ ọ̀rọ̀ onísáàmù náà pé: “Àwọn igi Jèhófà ní ìtẹ́lọ́rùn, àwọn kédárì Lẹ́bánónì tí ó gbìn, níbi tí àwọn ẹyẹ tìkára wọn ń kọ́ ìtẹ́ sí.”—Sáàmù 104:16, 17.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo 2004 Calendar of Jehovah’s Witnesses, oṣù January/February.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Igi álímọ́ńdì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi eléso tó rẹwà jù lọ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún, tí àwọn igi yòókù kò tíì yọ ìtànná lòun ti máa ń yọ ìtanná. Òjíkùtù làwọn Hébérù àtijọ́ máa ń pe igi álímọ́ńdì, nítorí pé ó máa ń tètè yọ òdòdó. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé yẹtuyẹtu òdòdó tó ní àwọ̀ osùn tàbí àwọ̀ funfun ni igi yìí máa ń yọ.—Oníwàásù 12:5.
Nínú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án àwọn ẹyẹ táwọn èèyàn mọ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún nínú wọn tó jẹ́ ẹyẹ tó ń kọrin. Ìró orin wọn kì í jẹ́ kí inú igbó pa rọ́rọ́. (Sáàmù 104:12) Bí àpẹẹrẹ, ológoṣẹ́ tó ń kọrin ní àwọn àkójọ orin tó gbádùn mọ́ni. Àwọn ẹyẹ tó jọ ẹyẹ ìbákà tí à ń pè ní mourning warblers lédè Gẹ̀ẹ́sì, èyí tí àwòrán rẹ̀ wà níhìn, jẹ́ àwọn ẹyẹ kéékèèké tó máa ń kọrin, a sì fi àwọ̀ mèremère bí àwọ̀ eérú, àwọ̀ yẹ́lò àti àwọ̀ yẹ́lò tó dàpọ̀ mọ́ àwọ̀ ewé ṣe wọ́n lọ́ṣọ̀ọ́.—Sáàmù 148:1, 10.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Igbó kìjikìji tó wà ní ìlú Normandy, ní orílẹ̀-èdè Faransé