ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 5/8 ojú ìwé 6-11
  • Àwọn Àǹfààní Igbó Kìjikìji

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àǹfààní Igbó Kìjikìji
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igbó Aláìlẹ́gbẹ́ Kan
  • Oúnjẹ, Afẹ́fẹ́ Atura, àti Egbòogi
  • “Ohun Tí A Fẹ́ Nìkan La Óò Dáàbò Bò”
  • Pípiyẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji
    Jí!—1998
  • Orísun Ìbànújẹ́ Lórí Igbó Kìjikìji Náà
    Jí!—1997
  • Ǹjẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji Wa Yóò Máa Wà Nìṣó?
    Jí!—1998
  • Igbó Kìjikìji
    Jí!—2023
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 5/8 ojú ìwé 6-11

Àwọn Àǹfààní Igbó Kìjikìji

NÍ 1844, ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì náà, Konstantin von Tischendorf, kófìrí abala 129 ìwé àfọwọ́kọ ìgbàanì kan nínú apẹ̀rẹ̀ ìdapàǹtísí nínú ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan. Tischendorf kó àwọn abala ìwé tó níye lórí náà lọ, wọ́n sì jẹ́ apá kan Codex Sinaiticus nísinsìnyí—ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà Bíbélì àfọwọ́kọ tó lókìkí jù lọ lágbàáyé.

A gba ohun ìní ṣíṣeyebíye yẹn lọ́wọ́ ìparun kó tó pẹ́ jù. Àwọn igbó kìjikìji—tí a sábà máa ń gbójú fo ìníyelórí wọn ní gidi dá—kò rìnnà kore tó bẹ́ẹ̀. Lọ́dọọdún, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìdánásungbó láti ọwọ́ àwọn ọlọ́gbà-ẹran àti àwọn àgbẹ̀ alákòókiri ní ń ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ olóoru. Al Gore, igbákejì ààrẹ United States lọ́wọ́lọ́wọ́, tó fojú rí irú ìdánásungbó bẹ́ẹ̀ kan ní ẹkùn ilẹ̀ Amazon, wí pé: “Ìsọdahoro náà kò ṣeé gbà gbọ́. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ títóbijù nínú ìtàn.”

A kì í sábà sun ohun tí a mọ̀ pé ó níye lórí. Ọ̀ràn ìbànújẹ́ ti igbó kìjikìji ni pé a ti ń bà wọ́n jẹ́ kí a tó lóye ìníyelórí wọn, kí a tó mọ bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́, àní kí a tó mọ ohun tó wà nínú wọn pàápàá. Dídánásun igbó kìjikìji kan dà bí dídánásun àgbájọ ìwé ibi ìkówèésí kan láti mú kí ilé móoru—láìyẹ àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà wò.

Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nípa “àwọn ìwé” wọ̀nyí, àkójọ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìsọfúnni tó wà nínú àwọn igbó kìjikìji. Wọ́n pèsè “ìsọfúnni” gbígbádùnmọ́ni.

Igbó Aláìlẹ́gbẹ́ Kan

Ní 1526, Gonzalo Fernández de Oviedo, olùṣàkọsílẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Sípéènì, ké gbàjarè pé: “A kò lè ṣàlàyé nípa àwọn igi tó wà ní àwọn erékùṣù ilẹ̀ Indies, nítorí bí wọ́n ṣe pọ̀ yanturu tó.” Ní ọ̀rúndún márùn-ún lẹ́yìn náà, ohun tó sọ ṣì jẹ́ òtítọ́ gan-an. Òǹkọ̀wé Cynthia Russ Ramsay kọ̀wé pé: “Igbó kìjikìji” ló jẹ́ “ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn tó jónírúurú jù, tó díjú jù, tí òye wa nípa rẹ̀ sì kéré jù, lórí ilẹ̀ ayé.”

Onímọ̀ nípa ohun alààyè ilẹ̀ olóoru, Seymour Sohmer, wí pé: “A kò gbọ́dọ̀ gbàgbé láé pé a kò mọ̀ tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ nípa ọ̀nà tí a gbà gbé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn igbó ọlọ́rinrin ti ilẹ̀ olóoru kalẹ̀ àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ mẹ́nu ba oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ tó para pọ̀ wà nínú wọn.” Pípọ̀ tí àwọn irú ọ̀wọ́ náà pọ̀ rẹpẹtẹ àti bí ìgbáraléra wọn ṣe díjú pọ̀ tó mú kí iṣẹ́ olùwádìí má rọrùn.

Ó lè jẹ́ ìwọ̀nba irú ọ̀wọ́ igi díẹ̀ péré ló wà nínú ìwọ̀n hẹ́kítà igbó ilẹ̀ kan tí ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ní ìdàkejì, ìwọ̀n ìlàjì hẹ́kítà ilẹ̀ igbó kìjikìji lè ní irú ọ̀wọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó lé ní 80 nínú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àròpọ̀ gbogbo igi tó wà lórí hẹ́kítà kan jẹ́ ìpíndọ́gba nǹkan bí 300 péré. Níwọ̀n bí pípín irú ohun yíyàtọ̀síra bẹ́ẹ̀ sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí ti ń tánni lókun tó sì gba sùúrù gidigidi, àwọn ilẹ̀ igbó kìjikìji tó fẹ̀ ju hẹ́kítà kan lọ, tí a tíì ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ wọn, kò tó nǹkan. Bí ó ti wù kí ó rí, àbájáde àwọn tí a ti ṣe yani lẹ́nu gan-an.

Àkójọ onírúurú igi náà jẹ́ ibùgbé tí ọ̀pọ̀ ohun tí ń gbé inú igbó—tí ó pọ̀ ju ohun tí ẹnikẹ́ni ti lè ronú kàn lọ—ti ń rí ohun kòṣeémánìí ìgbésí ayé. Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Àpapọ̀ United States sọ pé àmúṣàpẹẹrẹ àgbègbè oníkìlómítà-mẹ́wàá níbùú lóròó ti igbó kìjikìji tí ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkan kan lórí rẹ̀ rí lè ní tó 125 oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú, 100 irú ọ̀wọ́ ẹran afàyàfà, 400 irú ọ̀wọ́ ẹyẹ, àti 150 irú ọ̀wọ́ labalábá nínú. Ní ìfiwéra, a ṣàkíyèsí pé àpapọ̀ Àríwá Amẹ́ríkà kò ní tó 1,000 irú ọ̀wọ́ ẹyẹ, àwọn tó sì ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀ kò tó bẹ́ẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè rí àwọn kan lára àìmọye irú ọ̀wọ́ irúgbìn àti ẹranko náà ní àwọn àyè fífẹ̀ nínú igbó kìjikìji, àwọn mìíràn kì í kọjá ibi ilẹ̀ olókè kan. Ìyẹn ló mú kí wọ́n ṣeé ṣe níjàǹbá tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí àwọn agégẹdú fi parí gígégi ní ẹsẹ̀ òkè kan ní Ecuador lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, 90 lára àwọn irú ọ̀wọ́ igi ìbílẹ̀ tó wà níbẹ̀ ló ti kú run.

Nítorí irú ọ̀ràn ìbànújẹ́ bẹ́ẹ̀, Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Alájọṣepọ̀ Lórí Àwọn Igbó Ilẹ̀ Olóoru ní United States kìlọ̀ pé: “Àgbájọ àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́dọ̀ gbógun ti ìṣòro náà kíákíá ní lemọ́lemọ́ àti ní ìṣọ̀kan bí a óò bá dáàbò bo búrùjí tí a kò mọyì rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí ó sì ṣeé ṣe kí ó má ṣeé dá padà sípò wọ̀nyí lọ́wọ́ ìparun yán-ányán-án ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún tí ń bọ̀.”

Ṣùgbọ́n àwọn ìbéèrè náà lè wá pé: Àwọn búrùjí àdánidá wọ̀nyí ha níye lórí tó bẹ́ẹ̀ bí? Ìparun igbó kìjikìji yóò ha nípa gidigidi lórí ìgbésí ayé wa bí?

Oúnjẹ, Afẹ́fẹ́ Atura, àti Egbòogi

Ǹjẹ́ o máa ń fi àwo cornflakes kan, bóyá ẹyin sísè kan, àti ife kọfí gbígbóná kan, ṣe oúnjẹ àárọ̀ rẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, lọ́nà tí kò ṣe tààrà, o ń jàǹfààní lára àwọn igbó ilẹ̀ olóoru. Àgbàdo náà, hóró èso kọfí náà, adìyẹ tó yé ẹyin náà, àti màlúù tí wàrà ti ara rẹ̀ wá náà—gbogbo wọ́n wá láti inú ẹranko àti igi igbó ilẹ̀ olóoru. Gúúsù Amẹ́ríkà ni àgbàdo ti wá, Etiópíà ni kọfí ti wá, ara adìyẹ igbó ilẹ̀ Éṣíà la ti mú adìyẹ tí a fi dọ́sìn wá, àtìrandíran màlúù banteng tí a wu léwu láti Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà ni màlúù tí a ń fún wàrà rẹ̀. Ìwé Tropical Rainforest ṣàlàyé pé: “Odindi ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún ohun tí a ń jẹ ló pilẹ̀ ní ilẹ̀ olóoru.”

Ènìyàn kò gbọ́dọ̀ kẹ̀yìn sí orísun oúnjẹ rẹ̀. Àwọn irè oko àti ohun ọ̀sìn ń daláìlágbára jù nípasẹ̀ àpọ̀jù ìbálòpọ̀ láàárín àwọn ohun alààyè tó bára wọn tan. Igbó kìjikìji, tó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àgbájọ irú ọ̀wọ́ nínú, lè pèsè ìyàtọ̀síra ti apilẹ̀ àbùdá tí a nílò láti fún àwọn irúgbìn tàbí ẹranko wọ̀nyí lókun. Bí àpẹẹrẹ, onímọ̀ nípa ewéko, ará Mexico náà, Rafael Guzmán, ṣàwárí irú ọ̀wọ́ koríko tuntun kan tó bá àgbàdo òde òní dọ́gba. Ohun tó rí yìí ru àwọn àgbẹ̀ lọ́kàn sókè, nítorí pé àwọn àrùn pàtàkì márùn-ún sí méje tí ń ba irè àgbàdo jẹ́ kì í nípa lórí koríko yìí (Zea diploperennis). Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì nírètí láti lo irú ọ̀wọ́ tuntun náà láti mú oríṣi àgbàdo kan tí àrùn kò ní lè nípa lórí rẹ̀ jáde.

Ní 1987, ìjọba ilẹ̀ Mexico dáàbò bo apá ilẹ̀ olókè tí a ti rí àgbàdo ìgbẹ́ yìí. Àmọ́ láìsíyèméjì, pẹ̀lú bí a ṣe ń pa igbó púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ run, a ń pàdánù àwọn irú ọ̀wọ́ oníyebíye bí èyí, kódà, kí a tó ṣàwárí wọn pàápàá. Nínú igbó ìhà Ìlà Oòrùn Gúúsù Éṣíà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ irú ọ̀wọ́ màlúù ìgbẹ́, tó lè fún àwọn ọmọ agbo ẹran àmúsìn lókun, ló wà. Ṣùgbọ́n gbogbo irú ọ̀wọ́ wọ̀nyí ló wà ní bèbè àkúrun nítorí bí a ṣe ń pa ibùgbé àdánidá wọn run.

Bí oúnjẹ tí a ń jẹ ti ṣe pàtàkì gẹ́lẹ́ ni afẹ́fẹ́ atura náà ṣe pàtàkì. Gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tó bá ń gbádùn ìrìn atunilára nínú igbó ṣe lè ti kíyè sí i, àwọn igi ń kó ipa pàtàkì nínú fífi afẹ́fẹ́ oxygen sọ afẹ́fẹ́ àyíká dọ̀tun. Àmọ́ nígbà tí a bá dáná sun wọ́n, a ń tú èéfín olóró afẹ́fẹ́ carbon dioxide àti carbon monoxide sílẹ̀. Gáàsì méjèèjì ń dá ìṣòro sílẹ̀.

Àwọn kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé àwọn ìgbòkègbodò ènìyàn ti sọ ìwọ̀n afẹ́fẹ́ carbon dioxide inú afẹ́fẹ́ àyíká ilẹ̀ ayé di ìlọ́po méjì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsọdìbàjẹ́ tí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ń fà la ń kà sí olórí okùnfà rẹ̀, a ti gbọ́ pé dídánásungbó ń kó èyí tó lé ní ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí a ń tú jáde. Bí afẹ́fẹ́ carbon dioxide bá ti tú sínú afẹ́fẹ́ àyíká, ó ń dá ohun tí a ń pè ní ìmáyégbóná, tí ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò fa kí àgbáyé gbóná lọ́nà bíburújáì, sílẹ̀.

Afẹ́fẹ́ carbon monoxide ló burú jù. Òun ni lájorí èròjà panipani tó wà nínú kùrukùru tó jẹ́ orísun ewu fún àwọn àgbègbè àrọko ìlú ńlá. Àmọ́, ó ya olùwádìí James Greenberg lẹ́nu láti rí “ìwọ̀n afẹ́fẹ́ carbon monoxide kan náà tó wà ní àwọn àrọko United States ní àwọn igbó àgbègbè Amazon.” Dídánásungbó Amazon láìfèròsí i ti ba afẹ́fẹ́ àyíká tí a ṣètò pé kí àwọn igi náà máa sọ di mímọ́ gan-an jẹ́!

Ní àfikún sí jíjẹ́ orísun oúnjẹ àti afẹ́fẹ́ atura, igbó kìjikìji tún lè jẹ́ orísun onírúurú egbòogi. Ìdámẹ́rin gbogbo egbòogi tí àwọn dókítà ń kọ fúnni ló ń ti ara àwọn ewéko tí ń hù nínú igbó ilẹ̀ olóoru wá. Láti inú igbó òkè ńlá inú ìkùukùu ti Andes ni èròjà quinine, tí a fi ń bá ibà jà ti wá; èròjà curare tí a fi ń mú iṣan ara dẹ̀ nígbà iṣẹ́ abẹ wá láti àgbègbè Amazon; irúgbìn rosy periwinkle, tí àwọn èròjà alkaloid ara rẹ̀ ń mú kí ìwọ̀n ìlàájá ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn àrùn leukemia pọ̀ sí i, ń wá láti Madagascar. Láìka irú ìyọrísí kíkọyọyọ bẹ́ẹ̀ sí, ìpín 7 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára gbogbo irúgbìn ilẹ̀ olóoru ni a ti yẹ̀ wò fún àwọn ànímọ́ tí wọ́n ní láti di egbòogi. Àkókò sì ń tán lọ. Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Àrùn Jẹjẹrẹ ní United States kìlọ̀ pé, “pípa tí a ń pa igbó ọlọ́rinrin ti ilẹ̀ olóoru run lọ́nà gbígbòòrò lè já sí ìfàsẹ́yìn ńláǹlà nínú ìgbétásì ìgbógunti àrùn jẹjẹrẹ.”

Àwọn iṣẹ́ pàtàkì mìíràn wà tí àwọn igbó kìjikìji ń ṣe—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í mọyì wọn títí di ìgbà tí àwọn igbó náà kò bá sí mọ́. Lára ìwọ̀nyí ni mímú kí òjò àti ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wà déédéé àti ṣíṣèdíwọ́ fún ìṣànlọ erùpẹ̀. Ìwé The Emerald Realm: Earth’s Precious Rain Forests sọ pé: “Ohun tí ń ti inú igbó ilẹ̀ olóoru jáde lágbàáyé pọ rẹpẹtẹ ju ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ ní báyìí lọ. Ṣùgbọ́n a mọ̀ nísinsìnyí pàápàá pé ìníyelórí rẹ̀ kò ṣeé díwọ̀n.”

“Ohun Tí A Fẹ́ Nìkan La Óò Dáàbò Bò”

Ó dájú pé ìwà òmùgọ̀ tó burú jù lọ ni láti ba ohun tó lè ṣèpèsè fún wa lọ́pọ̀ yanturu bẹ́ẹ̀ jẹ́. Ní èyí tí ó lé ní 3,000 ọdún sẹ́yìn, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa dáàbò bo àwọn igi eléso nígbà tí wọ́n bá ń bá ìlú àwọn ọ̀tá wọn jà. Ìdí rírọrùn kan ló fún wọn, pé: “Wọ́n ń pèsè oúnjẹ fún yín.” Síwájú sí i, “àwọn igi oko kì í ṣe ènìyàn débi tí ìwọ yóò fi sàga tì wọ́n.” (Diutarónómì 20:19, 20, The New English Bible) Ohun kan náà ni a lè sọ nípa igbó kìjikìji tí a ń gbógun tì.

Ní kedere, àwọn igbó kìjikìji, bí àwọn igi eléso, níye lórí nígbà tí a bá fi wọ́n sóròó ju nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nínú ayé òde òní, àwọn àǹfààní tí a ń rí ní kíákíá máa ń jẹni lógún ju àwọn ìníyelórí tí yóò pẹ́ kó tó tẹni lọ́wọ́ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìmọ̀ lè yí ìhùwà padà. Ará Senegal tó jẹ́ onímọ̀ ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti ibùgbé wọn náà, Baba Dioum, tọ́ka sí i pé: “Ní gidi, ohun tí a fẹ́ nìkan la óò dáàbò bò; ohun tó yé wa nìkan la óò fẹ́; ohun tí a kọ́ nìkan ni yóò sì yé wa.”

Tischendorf jí àwọn abala ìwé ìgbàanì wọ̀nyẹn gbé ní Aṣálẹ̀ Sínáì nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé àfọwọ́kọ àtọdúnmọ́dún, ó sì fẹ́ láti pa wọ́n mọ́. Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn púpọ̀ tó yóò kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn igbó kìjikìji, kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n kó tó pẹ́ jù?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

Dídánásun igbó kìjikìji kan dà bí dídánásun àgbájọ ìwé ibi ìkówèésí kan láti mú kí ilé móoru—láìyẹ àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà wò 

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Dídáàbòbo Àwọn Ẹ̀dá Inú Igbó

JESÚS ELÁ fi nǹkan bí ọdún 15 ṣọdẹ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹranko mìíràn nínú igbó kìjikìji ilẹ̀ Áfíríkà. Àmọ́ kò ṣọdẹ mọ́. Ó ti di afinimọ̀nà inú ọgbà kan nínú igbó àìro tí a yà sọ́tọ̀ láti dáàbò bo 750 ìnàkí orí ilẹ̀ títẹ́jú ní Equatorial Guinea.

Jesús ṣàlàyé pé: “Ìgbà tí n kò ṣọdẹ ni mo ń gbádùn igbó kìjikìji náà jù. Ní tèmi, igbó náà dà bí abúlé mi nítorí pé ọkàn mi ń balẹ̀ níbí, ó sì ń pèsè gbogbo ohun tí mo nílò fún mi. A gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti dáàbò bo àwọn igbó wọ̀nyí fún àwọn ọmọ wa.”

Jesús, tí ń fi ìháragàgà ṣàjọpín ìfẹ́ tó ní fún igbó náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, rìnnà kore. Owó tí ń wọlé fún un nísinsìnyí tí ó ń dáàbò bo àwọn ìnàkí náà pọ̀ ju ti ìgbà tó ń ṣọdẹ wọn lọ. Níwọ̀n bí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ti ń láyọ̀ láti sanwó fún àǹfààní tí wọ́n ní láti rí irú àwọn ẹranko bẹ́ẹ̀ nínú ìgbẹ́, àwọn ọgbà ohun alààyè lè pawó fún àwọn ará àdúgbò, kí wọ́n sì fún àwọn olùṣèbẹ̀wò ní ìran mánigbàgbé nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹ̀dá. Ṣùgbọ́n ìwé Tropical Rainforest ṣàlàyé pé, ìdáàbòbò “àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn” fífanimọ́ra yìí ń béèrè fún “àgbègbè ìdáàbòbò àwọn ohun àdánidá tó gbòòrò, tó ní nínú, lọ́nà yíyẹ, àwọn odindi ọrùn odò.”a

Èé ṣe tí àwọn ọgbà ohun alààyè fi ní láti tóbi tó bẹ́ẹ̀ láti pèsè ààbò tó pọ̀ tó? John Terborgh ṣèṣirò nínú ìwé rẹ̀, Diversity and the Tropical Rain Forest, pé iye àwọn ẹranko jaguar tó jọjú (nǹkan bí 300 àwọn àgbà tí ń bímọ) nílò nǹkan bí 7,500 kìlómítà níbùú lóròó. Ó parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Bí a bá gbé e karí ìdiwọ̀n yìí, àwọn ọgbà ohun alààyè mélòó kan péré ló wà lágbàáyé, tó ní àyè tó fún àwọn ẹranko jaguar.” Àwọn ẹkùn lè nílò ilẹ̀ tó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀wọ́ àwọn ẹkùn tí ń bímọ kan (400 ẹranko) lè nílò ilẹ̀ tó pọ̀ tó 40,000 kìlómítà níbùú lóròó.

Nípa yíya igbó àìro títóbi sọ́tọ̀ fún àwọn ẹranko jẹranjẹran báyìí, a lè dáàbò bo àwọn ilẹ̀ igbó kìjikìji bákan náà. Àfikún àǹfààní kan ni pé àwọn ẹranko wọ̀nyí ń kópa pàtàkì nínú mímú kí àwùjọ àwọn ẹranko máa gbèrú ní gbogbogbòò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọrùn odò ni àgbègbè tí omi bá ti ń ṣàn wọ inú odò, ìsokọ́ra odò, tàbí àgbájọ omi mìíràn.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

1. Ọ̀pọ̀ ẹlẹ́ǹgà inú igbó kìjikìji ló ní àwọ̀ málamàla títànyòyò. Àwọn kòkòrò mìíràn ní ìrísí ẹ̀tàn tó bẹ́ẹ̀ tí ó ṣòro láti dá wọn rí

2. Àwọn labalábá ni ẹ̀dá tó gbàfiyèsí jù, tó sì ṣẹlẹgẹ́ jù nínú igbó kìjikìji

3. Àwùjọ àwọn ọ̀bọ tí ń bẹ́ gìjàgìjà láti orí ẹ̀ka kan sí òmíràn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìran tí ń dáni lára yá jù lọ nínú igbó

4. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ẹranko jaguar ni ọba igbó kìjikìji ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ṣàṣà onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ ló tíì rí ọ̀kan nínú ìgbẹ́ rí

5. Ìtànná òdòdó orchid ẹlẹgẹ́ ló ń ṣe àwọn igbó ọlọ́rinrin tó ṣù bolẹ̀ lórí àwọn òkè ńlá ilẹ̀ olóoru lọ́ṣọ̀ọ́

6. Àwọn ẹkùn tó kù nígbẹ̀ẹ́ kò tó 5,000

7. Kòkòrò rhinoceros beetle ti ilẹ̀ olóoru Amẹ́ríkà, tí a sọ lórúkọ yíyẹ wẹ́kú ní àwọn ìwo bíbanilẹ́rù, ṣùgbọ́n kì í pani lára rárá

8. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ń dáàbò bo irú ọ̀wọ́ àwọn ìnàkí, a ṣì ń rí ẹran wọn lọ́jà nílẹ̀ Áfíríkà. Ewéko ni òmìrán oníwàtútù yìí máa ń jẹ, ó sì máa ń wọ́ ìgbẹ́ ní ẹgbẹẹgbẹ́ ìdílé

9. Wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa àwọn ẹranko ocelot run tán nítorí awọ ara wọn kíkàmàmà

10. Àwọn ayékòótọ́ wà lára àwọn ẹyẹ tí ń pariwo jù, tó sì ń kẹ́gbẹ́ jẹ̀ jù nínú igbó

11. Bí àwọn ojú rẹ̀ kòǹdòkòǹdò ṣe fi hàn, ẹranko galago ń fòru wá ìjẹ

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò: Zoo de Baños

Fọ́tò: Zoo de la Casa de Campo, Madrid

[Credit Line]

Fọ́tò: Zoo de Baños

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Láti inú igbó kìjikìji la ti ń rí (1) kòkó, (2) irúgbìn “rosy periwinkle,” tó wúlò fún ìtọ́jú àrùn “leukemia,” àti (3) epo pupa. (4) Pípagbórun ń yọrí sí ìyẹ̀gẹ̀rẹ̀-ilẹ̀ tí ń ba nǹkan jẹ́ gan-an

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́