Ǹjẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji Wa Yóò Máa Wà Nìṣó?
NÍBẸ̀RẸ̀ ọ̀rúndún yìí, ẹyẹlé aláṣìíkiri ti Àríwá Amẹ́ríkà kú run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹyẹ tó pọ̀ jù lọ tí ó tíì wà rí. Àwọn onímọ̀ nípa ẹyẹ ṣírò rẹ̀ pé ní ọ̀rúndún méjì sẹ́yìn, ó pọ̀ tó bílíọ̀nù márùn-ún sí mẹ́wàá!
Bí ó ti wù kí ó rí, láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún, ẹran ẹyẹ olówó-pọ́ọ́kú kan tó hàn kedere pé kò lè tán di ohun tí a kò rí mọ́, lọ́nà kan tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ìdínkù [irú ọ̀wọ́ kan] lọ́nà àgbàyanu tí kò lẹ́gbẹ́.” Ohun ìrántí tí a gbé kalẹ̀ lórúkọ ẹyẹlé aláṣìíkiri náà ní Ọgbà Ẹ̀dá ti Ìpínlẹ̀ ní Wyalusing, Wisconsin, U.S.A., kà pé: “Irú ọ̀wọ́ yìí kú run nípasẹ̀ ìwọra àti àìnírònú ènìyàn.”
Ohun tó dé bá ẹyẹlé aláṣìíkiri náà rán wa létí pé kódà, ẹ̀dá tó pọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé lè kàgbákò ìgbóguntì láti ọwọ́ ẹ̀dá ènìyàn. Ìwọra àti àìnírònú ṣì gbilẹ̀ síbẹ̀. Ewu tòde òní kì í ṣe ti irú ọ̀wọ́ kan ṣoṣo, bí kò ṣe ti ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn lódindi. Bí àwọn igbó kìjikìji bá pòórá, gbogbo olùgbé inú wọn—nǹkan bí ìdajì gbogbo irú ọ̀wọ́ orí ilẹ̀ ayé—yóò pòórá. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé irú àjálù bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ “àjálù títóbijùlọ tí ẹ̀dá ènìyàn tíì [mú wá] sórí àwọn ohun alààyè.”
Lóòótọ́, a ní ìmọ̀ nípa àyíká nísinsìnyí ju ti ọ̀rúndún kan sẹ́yìn lọ. Àmọ́ òye yìí kò tíì pọ̀ tó láti mú ìgbì ìparun tí kò dẹ́kun náà rọlẹ̀. Onímọ̀ nípa ewéko, Manuel Fidalgo, dárò pé: “A ń ba ohun kan tí a kò lè díye lé jẹ́, àkókò tó ṣẹ́ kù kò sì tó nǹkan. Ominú ń kọ mí pé níwọ̀n ọdún díẹ̀ sí i, ìwọ̀nba igbó tí yóò kù tí a kò ní tíì fọwọ́ kàn yóò jẹ́ àwọn tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tí àwọn agégẹdú kò lè dé.”
Ẹ̀rù ń ba àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ nítorí ó ṣòro púpọ̀ láti mú àwọn igbó kìjikìji bọ̀ sípò. Ìwé The Emerald Realm: Earth’s Precious Rain Forests ṣàpèjúwe ìsaṣálẹ̀dìgbẹ́ ní ṣàkó gẹ́gẹ́ bí “ohun tí kì í yá, tó sì gbówó lérí, . . . ojútùú ìkẹyìn sí ìparun igbó kìjikìji.” Pátápinrá rẹ̀, àtúngbìn yóò kan àwọn irú ọ̀wọ́ igi ilẹ̀ olóoru díẹ̀ péré, àwọn ọ̀dọ́ igi náà yóò sì nílò àbójútó déédéé láti máà jẹ́ kí àwọn èpò fún wọn pa.
Ọ̀ràn nípa bóyá igbó kan tún lè padà ní láárí bí ti tẹ́lẹ̀ mọ́ sinmi lórí bí àgbègbè tí a tún gbìn náà ṣe sún mọ́ igbó kìjikìji tí a kò lò rí tó. Sísúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí nìkan ló lè mú kí àgbègbè tí a tún gbìn náà tún padà ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún irú ọ̀wọ́ tó wà nínú igbó kìjikìji gidi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìgbésẹ̀ náà yóò gba ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Àwọn àgbègbè kan tí a ti pa tì ní ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, nígbà tí ọ̀làjú àwọn Maya sojú dé, kò tíì kọ́fẹ padà ní kíkún.
“Àjọṣe Tuntun Láàárín Ọ̀pọ̀ Orílẹ̀-Èdè Ni Bí”?
Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Smithsonian, ní Washington, D.C., dábàá pé kí a ya ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn igbó kìjikìji tó wà nísinsìnyí sọ́tọ̀ fún ìran ọjọ́ ọ̀la, láti dáàbò bo ọ̀pọ̀ irú ọ̀wọ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Lọ́wọ́lọ́wọ́, nǹkan bí ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún la ń dáàbò bò, ṣùgbọ́n orúkọ lásán ni ọ̀pọ̀ lára àwọn igbó àìro tàbí ọgbà ẹ̀dá ti orílẹ̀-èdè wọ̀nyí fi ń jẹ́ ọgbà ẹ̀dá, nítorí pé kò sí owó tàbí àwọn òṣìṣẹ́ láti dáàbò bò wọ́n. Ní kedere, a gbọ́dọ̀ wá nǹkan ṣe.
Peter Raven, agbẹnusọ kan fún ìdáàbòbò igbó kìjikìji, ṣàlàyé pé: “Àwọn ìsapá láti dáàbò bo àwọn igbó kìjikìji nílò àjọṣe tuntun láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, mímọ̀ pé àwọn ènìyàn níbi gbogbo ń kópa nínú pípinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ ayé. A gbọ́dọ̀ wá àwọn ọ̀nà láti dín ipò òṣì àti ebi kù jákèjádò ayé. A óò ní láti ṣe àwọn àdéhùn tuntun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”
Lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó jọ pé àwọn ìdámọ̀ràn rẹ̀ lọ́gbọ́n nínú. Dídáàbò bo àwọn igbó kìjikìji ń fẹ́ ojútùú kárí ayé kan—bí àwọn ipò mìíràn tí ń kojú aráyé ṣe ṣe. Ìṣòro náà wà nínú rírí ‘àdéhùn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè’ gbà kí àjálù kárí ayé tó ṣẹlẹ̀, àti kí a tó ṣe ìpalára tó kọjá àtúnṣe. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Peter Raven ti dọ́gbọ́n túmọ̀ sí, pípa àwọn igbó kìjikìji run ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ìṣòro tí kò rọrùn láti kápá mìíràn ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, bí ebi àti ipò òṣì.
Di báyìí ná, àwọn ìsapá ọlọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè láti bójú tó irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ kò tíì ṣàṣeyọrí púpọ̀. Àwọn ènìyàn kan ń béèrè pé, Ǹjẹ́ ọjọ́ kan yóò wà, tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò borí àwọn ìlépa kékeré tí ń forí gbárí, ti orílẹ̀-èdè wọn, nítorí àǹfààní ire àpapọ̀, tàbí àlá kan lásán ni ìwákiri “àjọṣe tuntun láàárín ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè” jẹ́?
Kò jọ pé ìtàn fúnni ní ìdí fifẹsẹ̀múlẹ̀ fún ìfojúsọ́nà rere. Síbẹ̀síbẹ̀, a sábà máa ń gbójú fo kókó kan dá—èrò Ẹlẹ́dàá tó dá igbó kìjikìji. Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward O. Wilson láti Harvard tọ́ka sí i pé: “A gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé apá kan Ìṣẹ̀dá la ń bà jẹ́, tí a ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ohun tí àwa tìkára wa jogún du àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn.”
Ǹjẹ́ Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé yóò gba aráyé láyè láti ba iṣẹ́ ọwọ́ òun jẹ́ pátápátá? Ìyẹn kò ṣeé ronú kàn.a Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe gbé ojútùú tirẹ̀ kalẹ̀? Ó ṣèlérí pé òun yóò fìdí Ìjọba kan kalẹ̀—ìjọba àtọ̀runwá kan tí kò mọ ààlà orílẹ̀-èdè—tí yóò yanjú gbogbo ìṣòro ilẹ̀ ayé, tí “a kì yóò run láé.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Kì í ṣe kìkì pé Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń ba pílánẹ́ẹ̀tì náà jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n yóò tún bójú tó ìmúbọ̀sípò ẹwà àdánidá ilẹ̀ ayé. Gbogbo ilẹ̀ ayé pátápátá yóò wá di ọgbà ẹ̀dá àgbáyé kan níkẹyìn, gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa ṣe pète rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15; Lúùkù 23:42, 43) Àwọn ènìyàn níbi gbogbo yóò jẹ́ àwọn “tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà,” wọn yóò sì kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àti láti mọyì gbogbo ohun tí ó dá, títí kan igbó kìjikìji.—Aísáyà 54:13.
Nígbà tí onísáàmù náà ń ṣàpèjúwe àkókò oníbùkún náà, ó kọ̀wé pé: “Kí gbogbo igi igbó fi ìdùnnú bú jáde níwájú Jèhófà. Nítorí ó ti wá; nítorí ó ti wá ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé. Òun yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso, yóò sì fi ìṣòtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.”—Sáàmù 96:12, 13.
A láyọ̀ pé ọjọ́ ọ̀la igbó kìjikìji kò sí lọ́wọ́ ìdàníyàn—tàbí ìwọra—ènìyàn. Bíbélì fún wa ní ìdí láti ní ìgbọ́kànlé pé Ẹlẹ́dàá fúnra rẹ̀ yóò dá sí ọ̀ràn láti dáàbò bo àwọn igbó ilẹ̀ olóoru wa. Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò rí ẹwà ara igbó kìjikìji.—Ìṣípayá 21:1-4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lọ́nà wíwọnilọ́kàn, àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá tí ń lépa ìdáàbòbò iye tí ó bá lè ṣeé ṣe lára àwọn irú ọ̀wọ́ tí a wu léwu ṣàpèjúwe ìlànà ìwà híhù wọn bí “ìlànà Nóà” nítorí pé Nóà la fún láṣẹ láti kó “gbogbo ẹ̀dá alààyè ti gbogbo onírúurú ẹran” sínú áàkì. (Jẹ́nẹ́sísì 6:19) Onímọ̀ nípa ohun alààyè náà, David Ehrenfeld, sọ pé: “Wíwà tí [àwọn irú ọ̀wọ́] ti wà tipẹ́tipẹ́ nínú ìṣẹ̀dá gbọ́dọ̀ ní ẹ̀tọ́ tí kò ṣeé ṣiyèméjì nípa rẹ̀ náà, láti máa wà nìṣó, nínú.”