Orísun Ìbànújẹ́ Lórí Igbó Kìjikìji Náà
BÍ O bá wo igbó kìjikìji Amazon láti inú ọkọ̀ òfuurufú, yóò rán ọ létí igbó títẹ́ rẹrẹ, tí ó tóbi tó odindi kọ́ńtínẹ́ǹtì kan, tí ó láwọ̀ ewé, tí ó tutù yọ̀yọ̀, tí ó sì mọ́ lóólóó nísinsìnyí gan-an bí ó ti rí nígbà tí Orellana ṣàwárí rẹ̀. Bí o ti ń rìn tìniratìnira lórí ilẹ̀ igbó ọlọ́rinrin, tí ó gbóná janjan náà, tí o ń gbìyànjú láti yẹra fún àwọn kòkòrò tí ó tóbi tó àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú kéékèèké, ó ṣòro fún ọ láti mọ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi dópin sí tí ìfọkànyàwòrán sì ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn ohun tí ó jọ ewé wá di labalábá ní gidi, àwọn àjàrà di ejò, ègé àwọn igi gbígbẹ di àwọn eku tí a mú ta gìrì, tí ń fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Nínú igbó Amazon náà, ìtàn àròsọ ṣì ń jẹ́ kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gidi rúni lójú.
Alálàyé kan sọ pé: “Ẹ̀dà ọ̀rọ̀ tí ó ga jù lọ níbẹ̀ ni pé, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gidi nípa Amazon ní èrò àìdájú nínú gan-an bí àròsọ nípa rẹ̀ ṣe ní.” Ó sì ní èrò àìdájú nínú lóòótọ́! Finú wòye igbó kan tí ó tóbi tó Ìwọ̀ Oòrùn Europe. Finú wòye pé ó ní oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ igi tí ó lé ní 4,000. Finú wòye ẹwà tí oríṣiríṣi irúgbìn òdòdó tí irú ọ̀wọ́ wọn lé ní 60,000 gbé wọ̀ ọ́. Finú wòye bí àwọ̀ títàn àwọn ẹyẹ tí irú ọ̀wọ́ wọn jẹ́ 1,000 ṣe rí nínú rẹ̀. Finú wòye bí oríṣiríṣi irú ọ̀wọ́ ẹranko afọ́mọlọ́mú tí iye wọ́n jẹ́ 300 ṣe rí nínú rẹ̀. Finú wo bí ìkùnyùnmùyùnmù bóyá mílíọ̀nù méjì irú ọ̀wọ́ àwọn kòkòrò ṣe kún ibẹ̀ dẹ́múdẹ́mú. Nísinsìnyí, o ti lóye ìdí tí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣàpèjúwe igbó kìjikìji Amazon náà ṣe ń parí rẹ̀ sí lílo ọ̀rọ̀ ìjúwe dídùn. Àwọn ọ̀rọ̀ ìjúwe dídùn nìkan ló lè sọ bí ìṣẹ̀dá inú igbó kìjikìji títóbi jù lọ ilẹ̀ olóoru yìí ṣe pọ̀ tó lórí ilẹ̀ ayé.
“Àwọn Àkúdàáyà” Tí Wọ́n Wà Ládàádó
Ní 90 ọdún sẹ́yìn, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ America náà, tí ó tún jẹ́ apanilẹ́rìn-ín, Mark Twain ṣàpèjúwe igbó fífanilọ́kàn-mọ́ra yìí gẹ́gẹ́ bí “ilẹ̀ tí agbára oògùn òun ọfọ̀ wà lórí rẹ̀, tí ó ní àwọn ohun ìyanu ilẹ̀ olóoru lánìíjù, ilẹ̀ wíwuni tí gbogbo àwọn ẹyẹ àti òdòdó àti ẹranko jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí ó ṣeé kó lọ sí ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí, ibi tí àwọn ẹlẹ́gungùn àti ọ̀nì àti ọ̀bọ sì wà bíi pé ilé wọn ni, bíi pé wọ́n wà ní Ọgbà Ẹranko.” Lónìí, ọ̀rọ̀ onílàákàyè tí Twain sọ ni a ti yí pa dà lọ́nà amúniṣewọ̀ọ̀. Àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí àti ọgbà ẹranko lè wá jẹ́ kìkì ilé tí ó ṣẹ́ kù fún àwọn ohun ìyanu ilẹ̀ olóoru Amazon tí ń pọ̀ sí i. Èé ṣe?
Okùnfà tí ó ga jù lọ ni gígé tí ènìyàn ń gé igbó kìjikìji Amazon lulẹ̀, pípa ibùgbé àdánidá ohun ọ̀gbìn àti ẹranko. Bí ó ti wù kí ó rí, yàtọ̀ sí pípa ibùgbé náà run lọ́nà títóbi, àwọn okùnfà míràn—tí ó túbọ̀ kún fún àyínìke—wà tí ń yí àwọn irúgbìn àti irú ọ̀wọ́ àwọn ẹranko dà di “àkúdàáyà,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì wà láàyè. Ní ọ̀rọ̀ míràn, àwọn aláṣẹ gbà gbọ́ pé kò sí ohunkóhun tí ó lè ṣèdíwọ́ fún àkúrun àwọn irú ọ̀wọ́ náà.
Okùnfà kan bẹ́ẹ̀ ni ìdáwà. Àwọn aláṣẹ ìjọba tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìdáàbòbò lè fòfin de gígé àwọn igi lulẹ̀ nínú igbó láti jẹ́ kí àwọn irú ọ̀wọ́ tó wà níbẹ̀ máa wà nìṣó. Bí ó ti wù kí ó rí, àkámọ́ igbó kékeré kan ń mú kí àwọn irú ọ̀wọ́ wọ̀nyí máa retí ikú nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Ìwé Protecting the Tropical Forests—A High-Priority International Task fúnni ní àpẹẹrẹ kan láti ṣàpèjúwe ìdí tí àwọn erékùṣù igbó kéékèèké fi ń kùnà láti gbé ẹ̀mí ró fún ìgbà gígùn gan-an.
Àwọn irú ọ̀wọ́ igi ilẹ̀ olóoru sábà máa ń ní akọ àti abo igi. Láti mú irú jáde, àwọn àdán tí ń gbé lẹ́búlẹ́bú fò láti ara àwọn òdòdó akọ sára ti abo máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Dájúdájú, iṣẹ́ ìgbakọ yìí ń gbéṣẹ́ kìkì tí àwọn igi náà bá hù láyìíká ibi tí àdán náà ń fò dé. Bí abo bá jìnnà sí akọ gan-an—bí ó ti sábà máa ń ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ gbalasa kan tí ó jóná gbẹ bá yí àkámọ́ igbó náà ká—àdán kò ní lè lọ sí ọ̀nà jíjìn bẹ́ẹ̀. Ìròyìn náà sọ pé, àwọn igi náà yóò wá yí pa dà dí “‘àkúdàáyà’ níwọ̀n bí mímú irú jáde wọn fún ìgbà gígùn kò ti ní ṣeé ṣe mọ́.”
Ìsokọ́ra tí ó wà láàárín àwọn igi àti àwọn àdán yìí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àjọṣepọ̀ tí ń mú kí ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn wà ní àgbègbè Amazon. Kí a sọ ọ́ lọ́nà tí yóò yéni, igbó Amazon dà bí ilé ńlá kan tí ń pèsè ibùgbé àti oúnjẹ fún àkójọ àwọn ènìyàn yíyàtọ̀ síra àmọ́ tí wọ́n ní ipò ìbátan sísúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí. Láti yẹra fún àkúnya, àwọn ẹ̀dá inú igbó kìjikìji náà ń gbé ìpele yíyàtọ̀ síra, àwọn kan sún mọ́ ilẹ̀ igbó náà, àwọn mìíràn sún mọ́ òkè fíofío. Gbogbo àwọn ẹ̀dá ibẹ̀ ní iṣẹ́, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ bí agogo—àwọn kan lójú mọmọ, àwọn mìíràn ní alẹ́. Bí a bá gba gbogbo àwọn irú ọ̀wọ́ láyè láti máa ṣe ìpín iṣẹ́ tiwọn nínú iṣẹ́ náà, àwùjọ àwọn ohun ọ̀gbìn àti ẹranko dídíjú pọ̀ àgbègbè Amazon yìí yóò máa bá iṣẹ́ lọ geerege.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn ní Amazon ṣẹlẹgẹ́. Kódà bí ìdíwọ́ tí ènìyàn ń ṣe ní àyíká àwọn irú ọ̀wọ́ inú igbó yìí bá mọ sórí lílo ìwọ̀nba àwọn irú ọ̀wọ́ díẹ̀ láìtọ́, ìbàjẹ́ tí wọ́n ń ṣe yọ lára àwọn ẹranko tó wà ní gbogbo ìpele ọgbà náà. Alágbàwí ààbò ẹ̀dá náà, Norman Myers, fojú díwọ̀n pé, àkúrun irú ọ̀wọ́ irúgbìn kan lè dá kún ikú irú ọ̀wọ́ àwọn ẹranko tí ó tó 30 lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Lẹ́yìn náà, níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn igi inú igbó olóoru ti gbára lé àwọn ẹranko láti fún hóró èso wọn káàkiri, pípa tí ènìyàn ń pa àwọn irú ọ̀wọ́ ẹranko ń ṣamọ̀nà sí pípa àwọn igi tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún run kúrò. (Wo àpótí náà, “Ìsopọ̀ Àárín Igi òun Ẹja.”) Bíi ti ìdáwà, bíba ipò ìbátan jẹ́, yóò máa sọ irú ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀dá igbó púpọ̀ púpọ̀ sí i di “àkúdàáyà” ni.
Ìwọ̀nba Àdánù Díẹ̀ Ha Ni Gígé Ìwọ̀nba Díẹ̀ Lulẹ̀ Ń Mú Wá Bí?
Àwọn kan dáre fún pípa àwọn àgbègbè igbó kan run nípa ríronú pé igbó náà yóò kọ́fẹ pa dà, yóò sì hu irúgbìn tuntun sórí ilẹ̀ tí a ro mọ́ lọ́nà kan náà gan-an tí ara wa fi ń hu awọ tuntun bo ojú ibi tí nǹkan ti gé wa ní ìka. Ṣé lóòótọ́? Ní gidi, kò rí bẹ́ẹ̀.
Dájúdájú, òtítọ́ ni pé igbó máa ń hù pa dà bí ènìyàn bá fi àgbègbè ilẹ̀ kan tí a pa run sílẹ̀ fún ìgbà tí ó pẹ́ tó. Àmọ́, òtítọ́ tún ni pé bí ewéko tuntun tí ó hù náà ṣe máa ń jọ igbó ti tẹ́lẹ̀ kò yàtọ̀ sí bí àdàkọ ìwé tí kò dára kan ṣe máa ń jọ èyí tí a ṣàdàkọ rẹ̀. Ima Vieira, ọmọ ilẹ̀ Brazil tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ewéko, ṣèwádìí nípa àgbègbè igbó kan, tí ó tún hù pa dà, tí ó ti wà fún ọgọ́rùn-ún ọdún ní Amazon, ó sì ṣàwárí pé lára àwọn irú ọ̀wọ́ igi 268 tí ó máa ń gbilẹ̀ nínú igbó ti tẹ́lẹ̀ náà, 65 péré ló wà nínú igbó tí ó tún hù pa dà náà lónìí. Onímọ̀ nípa ewéko náà sọ pé, ìyàtọ̀ yí kan náà jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn irú ọ̀wọ́ ẹranko tí ó wà lágbègbè náà. Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn kan ti sọ, pípa igbó run kì í ṣe yíyí àwọn igbó pa dà sí aṣálẹ̀ pupa, ó ń yí apá kan igbó kìjikìji Amazon pa dà di aláfarajọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ dára tó ti tẹ́lẹ̀.
Ní àfikún, gígé àgbègbè igbó kan tí ó tilẹ̀ kéré sábà máa ń pa ọ̀pọ̀ àwọn irú ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn àti ẹranko tí ń dàgbà, tí ń rákòrò, tí ó sì lọ́ kọ́lọkọ̀lọ ní àgbègbè yẹn nìkan nínú igbó náà láìsí níbòmíràn run. Fún àpẹẹrẹ, àwọn olùṣèwádìí ní Ecuador rí 1,025 irú ọ̀wọ́ irúgbìn ní àgbègbè kan tí ó jẹ́ 1.7 kìlómítà níbùú lóròó nínú igbó olóoru. Ó lé ní 250 lára àwọn irú ọ̀wọ́ wọ̀nyẹn tí kì í hù níbòmíràn lórí ilẹ̀ ayé. Ọmọ ilẹ̀ Brazil náà, Rogério Gribel, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ìbátan láàárín àwọn ohun alààyè àti ibùgbé wọn, sọ pé: “Àpẹẹrẹ kan ládùúgbò ni sauim-de-coleira (lédè Yorùbá, ọ̀bọ aláwọ̀ púpọ̀ tí ojú rẹ̀ bóro),” ọ̀bọ kékeré, jíjojú ní gbèsè tí ó rí bíi pé ó wọ ẹ̀wù funfun alápá péńpé. Dókítà Gribel sọ pé: “Ìwọ̀nba àwọn tó ṣẹ́ kù wulẹ̀ ń gbé àgbègbè igbó kékeré kan nítòsí Manaus ní àárín gbùngbùn Amazon, àmọ́ pípa ibùgbé àdánidá yẹn run yóò mú kí àwọn irú ọ̀wọ́ yìí kú run pátápátá.” Gígé ìwọ̀nba díẹ̀ lulẹ̀ tí ń mú àdánù púpọ̀ wá gbáà ni.
Pípa “Igbó” Run
Bí ó ti wù kí ó rí, pípa igbó run pátápátá ń fa ìbànújẹ́ tí ń dáni níjì jù lọ sórí igbó kìjikìji Amazon náà. Àwọn tí ń la ọ̀nà, àwọn agégẹdú, àwọn awakùsà, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn mìíràn ń pa igbó run, ní pípa odindi ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn dà nù ní ìṣẹ́jú akàn.
Nígbà tí àìfohùnṣọ̀kan jíjinlẹ̀ wà nípa ìwọ̀n ìpagbórun pàtó ní Brazil lọ́dọọdún—ìfojúdíwọ̀n mímọ níwọ̀n nípa ìdáàbòbò sọ pé ó jẹ́ 36,000 kìlómítà níbùú lóròó lọ́dọọdún—àròpọ̀ ibi tí a ti pa run nínú igbó kìjikìji Amazon lè pọ̀ ju ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lọ, àgbègbè tí ó tóbi ju Germany lọ. Veja, ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí ó mú ipò iwájú ní Brazil, ròyìn pé, nǹkan bí 40,000 iná inú igbó tí àwọn àgbẹ̀ adánásunko fà lọ láti ìkangun kan orílẹ̀-èdè náà dé ìkangun kejì ní 1995—tí ó fi ìgbà márùn-ún ju ti ọdún tí ó ṣáájú lọ. Ìwé ìròyìn Veja kìlọ̀ pé, ènìyàn ń tanná ran igbó lọ́nà lílágbára bẹ́ẹ̀, pé àwọn apá kan Amazon jọ “ooru gbígbóná janjan ní ààlà ilẹ̀ aláwọ̀ ewé.”
Àwọn Irú Ọ̀wọ́ Ń Pòórá—Nígbà Náà Ń Kọ́?
Àwọn kan béèrè pé: ‘Àmọ́, ṣé a nílò gbogbo àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ irú ọ̀wọ́ wọ̀nyẹn ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni, a nílò wọn, ni alágbàwí ààbò ẹ̀dá náà, Edward O. Wilson, láti Yunifásítì Harvard, sọ. Wilson sọ pé: “Níwọ̀n bí a ti gbára lé ìṣiṣẹ́ ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn láti sọ omi wa di mímọ́ tónítóní, láti mú ilẹ̀ wa lọ́ràá àti láti ṣẹ̀dá afẹ́fẹ́ tí a ń fà símú gan-an, dájúdájú, ìjónírúurú ohun alààyè kì í ṣe ohun tí a lè fọwọ́ rọ́ dànù láìbìkítà.” Ìwé náà, People, Plants, and Patents, sọ pé: “Níní ọ̀pọ̀ onírúurú apilẹ̀ àbùdá lárọ̀ọ́wọ́tó yóò jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí lílà á já ẹ̀dá ènìyàn. Bí ìjónírúurú bá pòórá, àwa pẹ̀lú yóò pòórá láìpẹ́ lẹ́yìn náà.”
Ní tòótọ́, ipa tí pípa àwọn irú ọ̀wọ́ run ń ní lọ jìnnà ré kọjá àwọn igi tí a gé lulẹ̀, àwọn ẹranko tí a wu léwu, àti àwọn onílẹ̀ tí a ń yọ lẹ́nu. (Wo àpótí náà, “Ipa Tí Ènìyàn Ń Kó.”) Kíkéré tí àwọn igbó ń kéré sí i lè kàn ọ́. Ro èyí wò ná: Àgbẹ̀ kan tí ń gé igi pákí lulẹ̀ ní Mòsáḿbíìkì; ìyá kan tí ń lo egbòogi tí a fi ń ṣàkóso ìbímọ ní Uzbekistan; ọmọdékùnrin kan tí ó fara pa, tí wọ́n fún ní egbòogi adẹ̀rọ̀ ìmọ̀lára ní Sarajevo; tàbí oníbàárà kan tí ń fi lọ́fínńdà àrà ọ̀tọ̀ kan runmú ní ilé ìtajà kan ní New York—Àjọ Panos sọ pé, gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń lo àwọn ìmújáde ohun tí ó pilẹ̀ láti inú igbó ilẹ̀ olóoru. Igbó tí a kò tí ì fọwọ́ kàn tipa bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn jákèjádò ayé—àti ìwọ pẹ̀lú.
Kò Sí Àsè, Kò Sí Ìyàn
Lóòótọ́ ni pé, igbó kìjikìji Amazon náà kò lè pèsè àsè jákèjádò ayé, àmọ́ ó lè ṣèrànwọ́ láti ṣèdíwọ́ fún ìyàn kan jákèjádò ayé. (Wo àpótí náà, “Àròsọ Nípa Jíjẹ́ Ilẹ̀ Ọlọ́ràá.”) Lọ́nà wo? Ó dára, ní àwọn ọdún 1970, lórí ìpele tí ó pọ̀, ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í fúnrúgbìn oríṣiríṣi àwọn irúgbìn tí ń mú àwọn irè oko tí ó sábà máa ń tóbi jáde. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi àwọn irúgbìn tuntun, tí ń mú irè oko púpọ̀ wọ̀nyí jáde bọ́ 500 mílíọ̀nù ènìyàn sí i, ìṣòro fífara sin kan wà. Níwọ̀n bí wọn kò ti ní onírúurú apilẹ̀ àbùdá, wọn kò lera, àrùn sì lè kọ lù wọ́n. Fáírọ́ọ̀sì kan lè pa èyí tí ó pọ̀ gan-an lára àwọn irè oko níníyelórí jù lọ ní orílẹ̀-èdè kan run, kí ó sì tanná ran ìyàn.
Nítorí náà, láti ṣèmújáde àwọn irè oko tí ń yára kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn àjálù, kí a sì lé ebi dà nù, Àjọ Ètò Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè (FAO) ti ń rọni nísinsìnyí lórí “lílo ìwọ̀n èròjà apilẹ̀ àbùdá gbígbòòrò kan.” Ìyẹn sì ni ibi tí ọ̀ràn ti kan igbó kìjikìji àti àwọn olùgbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Níwọ̀n bí àwọn igbó ilẹ̀ olóoru ti jẹ́ ilé fún ohun tí ó lé ní ìdajì irú ọ̀wọ́ àwọn irúgbìn àgbáyé (títí kan nǹkan bí 1,650 irú ọ̀wọ́ tí ó lè jẹ́ irè oko tí a ń jẹ), igbó kìjikìji Amazon tí ó jẹ́ ibi ìtọ́jú irúgbìn àdánidá ni ibi tí ó dára fún olùṣèwádìí èyíkéyìí tí ń wá irú ọ̀wọ́ irúgbìn igbó. Ní àfikún, àwọn olùgbé inú igbó náà mọ bí wọn óò ṣe lo àwọn irúgbìn wọ̀nyí. Fún àpẹẹrẹ, kì í ṣe pé àwọn ará Brazil ti ẹ̀yà Ámẹ́ríńdíà Cayapo ń mú onírúurú àwọn irè oko tuntun bí sí i nìkan ni àmọ́, wọ́n tún ń pa irú àwọn kan, tí wọ́n gbìn sẹ́bàá òkè, mọ́. Fífi onírúurú àwọn irè oko bẹ́ẹ̀ lọ́ra pẹ̀lú onírúurú àwọn irè oko etílé tí àrùn lè kọ lù yóò mú kí okun àti agbára ìkọ́fẹpadà irúgbìn tí ènìyàn ń jẹ pọ̀ sí i. Àjọ FAO sọ pé, a sì nílò àfikún yẹn ní kíákíá, nítorí pé “ìbísí ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún ìmújáde oúnjẹ pọn dandan ní ọdún 25 tí ń bọ̀.” Láìka èyí sí, àwọn katakata tí ń gé igbó lulẹ̀ túbọ̀ ń kó wọnú igbó kìjikìji Amazon jìnnà ni.
Kí wá ni àwọn àbájáde rẹ̀ fún ẹ̀dá ènìyàn? Ó dára, bíbà tí ènìyàn ń ba igbó kìjikìji jẹ́ wulẹ̀ dà bí àgbẹ̀ tí ń jẹ kóró àgbàdo rẹ̀—ó fi pa ebi tí ń pa á lọ́wọ́lọ́wọ́ àmọ́, ó ń wu ìpèsè oúnjẹ ọjọ́ iwájú léwu. Àwùjọ àwọn ògbóǹkangí kan nípa ìjónírúurú ohun alààyè kìlọ̀ láìpẹ́ yìí pé, “ìdáàbòbò àti ìdàgbàsókè ìjónírúurú irè oko yòó kù jẹ́ ọ̀ràn tí ó kan gbogbo ayé ní pàtàkì.
Àwọn Irúgbìn Tí Ń Fini Lọ́kàn Balẹ̀
Nísinsìnyí, ṣàyẹ̀wò “ilé egbòogi” igbó, ìwọ yóò sì rí i pé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn àjàrà ilẹ̀ olóoru àti àwọn irúgbìn míràn. Fún àpẹẹrẹ, àwọn egbòogi alkaloid tí a yọ lára àwọn àjàrà inú Amazon ni a ń lò bí adẹ̀rọ̀ iṣan kí a tó ṣiṣẹ́ abẹ fún ènìyàn; 4 lára àwọn ọmọdé 5 tí ó ní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ ni a ti ràn lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ẹ̀mí wọn gùn sí i, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn kẹ́míkà tí ó wà nínú irúgbìn rosy periwinkle, òdòdó igbó kan. Igbó náà tún ṣèmújáde àwọn egbòogi quinine, tí a fi ń wo ibà sàn; egbòogi digitalis, tí a fi ń wo àìlùkìkì ọkàn àyà sàn; àti egbòogi diosgenin, tí ó wà nínú àwọn egbòogi tí a fi ń ṣàkóso ìbímọ. Àwọn irúgbìn míràn ti fini lọ́kàn balẹ̀ nínú wíwo àrùn AIDS àti àrùn jẹjẹrẹ sàn. Ìròyìn àjọ UN kan sọ pé: “Nínú Amazon nìkan, a ti ṣàkọsílẹ̀ 2,000 irú ọ̀wọ́ irúgbìn tí àwọn ọmọ ìbílẹ̀ ibẹ̀ ń lò bí egbòogi, tí ó sì lè wúlò nínú ìpoògùn.” Ìwádìí mìíràn sọ pé, jákèjádò ayé, ènìyàn 8 lára ènìyàn 10 ní ń yíjú sí egbòogi láti wo àwọn àìsàn wọn.
Ọ̀mọ̀wé Philip M. Fearnside sọ pé, nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti dáàbò bo àwọn irúgbìn tí ń dáàbò bò wá. Ó fi kún un pé: “A ka pípàdánù igbó Amazon sí ohun tí ó lè mú ìfàsẹ́yìn eléwu wá bá àwọn ìsapá láti wá ìwòsàn fún àrùn jẹjẹrẹ tí ń yọ ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nu. . . . Èrò pé àwọn àṣeyọrí híhàn gbangba tí ìmọ̀ ìṣègùn lóde òní ti ṣe gbà wá láyè láti dá apá pàtàkì kan lára àwọn ìpèsè wọ̀nyí sílẹ̀ lómìnira, jẹ́ irú ìdára-ẹni-lójú líléwu púpọ̀ tí ó lè yọrí sí ikú.”
Síbẹ̀síbẹ̀, ènìyàn ń bá a lọ ní pípa àwọn ẹranko àti irúgbìn run lọ́nà tí ó yára ju bí a ṣe lè rí wọn, kí a sì mọ ìsọ̀rí tí a óò pín in sí. Ó lè yà ọ́ lẹ́nu pé: ‘Kí ló dé tí ìpagbórun náà fi ń bá a lọ? A ha lè yí ìtẹ̀sí náà pa dà bí? Ìrètí ọjọ́ iwájú kan ha wà fún igbó kìjikìji Amazon bí?’
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Àròsọ Nípa Jíjẹ́ Ilẹ̀ Ọlọ́ràá
Ìwé ìròyìn Counterpart sọ pé, èrò pé ilẹ̀ Amazon lọ́ràá jẹ́ “àròsọ tí ó ṣòro láti fọwọ́ rọ́ dà nù.” Ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, olùyẹ̀wòkiri náà, Alexander von Humboldt, ṣàpèjúwe Amazon bí “àgbègbè ayé tí ń ṣèmújáde ọ̀pọ̀ irè oko.” Ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, Ààrẹ Theodore Roosevelt ti United States pẹ̀lú lérò pé Amazon fini lọ́kàn balẹ̀ lórí iṣẹ́ àgbẹ̀ tí yóò ṣèmújáde lọ́pọ̀ yanturu. Ó kọ̀wé pé: “A kò lè gba irú ilẹ̀ tí ó ní èròjà nínú, tí ó sì lọ́ràá bẹ́ẹ̀ láyè láti wà láìlò.”
Ní gidi, àgbẹ̀ tí ó gbà gbọ́ nínú ohun kan náà tí wọ́n gbà gbọ́, yóò rí i pé fún ọdún kan tàbí méjì, ilẹ̀ náà yóò mú irè oko tí ó dára níwọ̀nba jáde, nítorí pé àwọn eérú igi àti irúgbìn tí a sun ṣiṣẹ́ bí ajílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn ìyẹn, ilẹ̀ náà yóò ṣá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn irúgbìn aláwọ̀ ewé tí ó hù gan-an nínú igbó náà ń fini lọ́kàn balẹ̀ nípa pé ilẹ̀ náà ní èròjà ọlọ́ràá nínú, ní tòótọ́, ilẹ̀ náà ni ó dá kún bí a ṣe ń ya wọ igbó náà. Èé ṣe?
Jí! fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ pẹ̀lú Ọ̀mọ̀wé Flávio J. Luizão, olùṣèwádìí kan ní Ibùdó Ìṣèwádìí Ìjọba Àpapọ̀ ní Amazon àti ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ nípa ilẹ̀ igbó kìjikìji. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìyí:
‘Láìdà bí ọ̀pọ̀ àwọn ilẹ̀ inú igbó mìíràn, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ní àgbègbè Amazon kì í rí èròjà ọlọ́ràá fà láti ìsàlẹ̀ wá sókè, láti inú àpáta tí ń jẹrà, nítorí pé àpáta tí èròjà ń ti inú rẹ̀ wá kò ní èròjà tó, ó sì jìnnà jù sí òkè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ilẹ̀ tí ó lu náà ń rí èròjà láti òkè lọ sí ìsàlẹ̀, láti inú òjò àti òkìtì koríko. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀kán òjò àti àwọn ewé tí ó já bọ́ nílò ìrànlọ́wọ́ láti di èròjà. Èé ṣe?
‘Omi òjò tí ń rọ̀ sórí igbó kìjikìji kò ní èròjà púpọ̀ nínú fúnra rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, bí ó bá ta sára àwọn ewé, tí ó sì ṣàn gba ara àwọn igi, yóò fa àwọn èròjà mọ́ra lára àwọn ewé, ẹ̀ka igi, ewédò, èèhọ̀n, ìtẹ́ àwọn kòkòrò, eruku. Nígbà tí omi náà bá máa fi wọ inú ilẹ̀, ó ti yí pa dà di oúnjẹ dáradára fún irúgbìn. Láti máà jẹ́ kí omi yìí wulẹ̀ ṣàn lọ sí àwọn ẹsẹ̀ odò, ilẹ̀ náà ń lo àkámọ́ èròjà kan tí àwọn gbòǹgbò tí ó wà káàkiri láyìíká ìwọ̀nba sẹ̀ǹtímítà díẹ̀ àkọ́kọ́ ilẹ̀ òkè náà mú jáde. Ẹ̀rí pé àkámọ́ náà gbéṣẹ́ ni pé àwọn ẹsẹ̀ odò tí ń gba omi òjò náà mọ́ra tilẹ̀ ní àwọn èròjà tí kò dára tó ti ilẹ̀ igbó náà fúnra rẹ̀. Nítorí náà, àwọn èròjà náà lọ sínú àwọn gbòǹgbò kí omi tó dé inú ẹsẹ̀ odò tàbí odò.
‘Orísun oúnjẹ mìíràn ni òkìtì koríko—àwọn ewé tó já bọ́, àwọn èèhù ẹ̀ka, àti àwọn èso. Nǹkan bíi tọ́ọ̀nù mẹ́jọ òkìtì koríko ń bọ́ sórí hẹ́kítà kan [saarè méjì ààbọ̀] orí ilẹ̀ igbó lọ́dọọdún. Àmọ́, báwo ni òkìtì koríko ṣe ń dé abẹ́ ilẹ̀, tí ó sì wọnú ìṣètò gbòǹgbò irúgbìn? Àwọn ikán máa ń ṣèrànlọ́wọ́. Wọ́n ń gé àwọn ègé roboto pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ lára àwọn ewé náà, wọ́n sì ń kó àwọn ègé wọ̀nyí wọ inú àwọn ìtẹ́ wọn lábẹ́lẹ̀. Ní pàtàkì ní ìgbà òjò ni àwùjọ wọ́n máa ń kó wọnú ìgbòkègbodò, ní gbígbé iye pípọ̀ rẹpẹtẹ tí ó jẹ́ ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo òkìtì koríko orí ilẹ̀ igbó kiri lábẹ́lẹ̀. Níbẹ̀, wọ́n ń lo àwọn ewé náà láti mọ ọgbà láti gbin olú. Olú yìí yóò wá mú èròjà irúgbìn náà jẹrà lẹ́yìn náà, yóò sì tú afẹ́fẹ́ nitrogen, phosphorus, calcium, àti àwọn èròjà míràn—àwọn èròjà tí ó wúlò fún irúgbìn—dà sílẹ̀.
‘Kí ni àwọn ikán náà ń rí láti inú rẹ̀? Oúnjẹ. Wọ́n ń jẹ àwọn olú náà, wọ́n sì lè gbé díẹ̀ lára àwọn ewé náà mì pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ọwọ́ àwọn kòkòrò tíntìntín inú ìfun ikán náà yóò dí ní yíyí oúnjẹ àwọn ikán náà pa dà lọ́nà oníkẹ́míkà, kí àbájáde rẹ̀ lè jẹ́ pé, ìgbẹ́ àwọn kòkòrò náà yóò di oúnjẹ eléròjà nínú fún irúgbìn. Nítorí náà, ẹ̀kán òjò àti àlòtúnlò èròjà ajílẹ̀ jẹ́ méjì lára àwọn ohun tó mú kí igbó kìjikìji náà ṣì wà, kí ó sì máa kún sí i.
‘Ó rọrùn láti rí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ bí o bá ro igbó mọ́, tí o sì sun ún. Kò tún sí àwọn ẹ̀ka títẹ́ lókè tí yóò gba ẹ̀kán òjò sára tàbí ìpele òkìtì koríko kan tí a óò tún lò. Kàkà bẹ́ẹ̀, òjò púpọ̀ rẹpẹtẹ yóò máa dà bo ilẹ̀ náà tààràtà pẹ̀lú agbára púpọ̀, ipa tí wọ́n ń ní yóò sì mú kí ojú ilẹ̀ náà le koránkorán. Lákòókò kan náà, ìtànṣán oòrùn tí ń tàn sórí ilẹ̀ náà tààràtà ń mú kí ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ojú ilẹ̀ náà pọ̀ sí i, ó sì ń ki ilẹ̀ náà. Àbájáde rẹ̀ ni pé, omi òjò yóò máa ṣàn kúrò lórí ilẹ̀ náà, yóò máa bọ́ àwọn odò dípò ilẹ̀. Èròjà tí a ń pàdánù láti inú ilẹ̀ tí a ń pa igbó rẹ̀ run, tí a sì ń sun, lè pọ̀ gan-an tí àwọn odò ìtòsí àwọn àgbègbè tí a pa igbó wọn run tilẹ̀ ń jìyà àpọ̀jù àwọn èròjà, tí èyí sì ń wu àwọn irú ọ̀wọ́ inú omi léwu. Ní kedere, bí a kò bá da igbó láàmú, yóò pèsè fún ara rẹ̀, àmọ́ ìdíwọ́ tí ènìyàn ń ṣe ń yọrí sí ìjábá.’
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ipa Tí Ènìyàn Ń Kó
Kì í ṣe àwọn irúgbìn àti ẹranko nìkan ni bíbà tí ènìyàn ń ba àyíká ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn jẹ́ àti pípa tí wọ́n ń pa igbó run ń ṣèpalára fún, àmọ́ ó ń pa àwọn ẹ̀dá ènìyàn lára pẹ̀lú. Nǹkan bí àwọn 300,000 Ámẹ́ríńdíà, àwọn àṣẹ́kù lára àwọn 5,000,000 Ámẹ́ríńdíà tí wọ́n ń gbé àgbègbè Amazon ní Brazil nígbà kan rí, ṣì ń gbé pọ̀ pẹ̀lú igbó àyíká wọn. Àwọn agégẹdú, àwọn tí ń wá wúrà, àti àwọn mìíràn, tí púpọ̀ lára wọn ka àwọn Ámẹ́ríńdíà náà sí “àwọn tí ń dí ìdàgbàsókè lọ́wọ́” ń yọ àwọn Ámẹ́ríńdíà náà lẹ́nu lọ́pọ̀lọpọ̀.
Lẹ́yìn náà, àwọn caboclo tún wà pẹ̀lú, àwọn ènìyàn líle tí wọ́n jẹ́ àdàlù ìrandíran àwọn aláwọ̀ funfun àti Ámẹ́ríńdíà, tí àwọn baba ńlá wọn fi Amazon ṣe ibùjókòó ní nǹkan bí 100 ọdún sẹ́yìn. Nítorí pé wọ́n ń gbé nínú àwọn abà orí òpó, wọ́n lè máà tí ì gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn” rí, àmọ́ wọ́n ń rí ohun amẹ́mìíró láti inú igbó náà láìpa á run. Síbẹ̀, rírọ́ tí àwọn ènìyàn tuntun wá ń rọ́ wọ igbó tí wọ́n fi ṣelé nísinsìnyí ń nípa lórí ìwàláàyè wọn ojoojúmọ́.
Ní gídi, ọjọ́ ọ̀la nǹkan bíi 2,000,000 àwọn tí ń ṣa kóró èso, àwọn akọrọ́bà, àwọn apẹja, àti àwọn ọmọ ìbílẹ̀ míràn, tí ń gbé ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àyípoyípo ìgbà nínú igbó náà àti àkúnya òun gbígbẹ àwọn odò jákèjádò inú igbó kìjikìji Amazon náà, kò dájú. Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ó yẹ kí àwọn ìsapá láti dáàbò bo igbó náà pọ̀ ju dídáàbò bo àwọn igi ọ̀ganwó àti àwọn esé. Ó yẹ kí wọ́n dáàbò bo àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùgbé inú igbó náà pẹ̀lú.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìsopọ̀ Àárín Igi òun Ẹja
Nígbà òjò, Odò Amazon máa ń kún, yóò sì bo àwọn igi tí ń hù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ igbó mọ́lẹ̀. Nígbà tí omi náà bá kún jù lọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn igi tí ó wà nínú àwọn igbó wọ̀nyí máa ń so èso, wọn óò sì gbọn èso wọn—àmọ́, dájúdájú, kò sí eku èyíkéyìí tí omi ti bò mọ́lẹ̀ tí ó lè gbé wọ́n káàkiri. Ìhín ni ẹja tambaqui (Colonnonea macropomum) ti ń kó ipa kan, ìṣẹ̀dá líléfòó kan tí ń fọ́ kóró èso, tí ó ní agbára ìgbóòórùn mímúná. Bí ó ti ń lúwẹ̀ẹ́ láàárín ẹ̀ka àwọn igi tí omi ti bò mọ́lẹ̀, ó máa ń gbóòórùn àwọn igi tí wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbọn kóró èso. Bí àwọn kóró èso náà bá já bọ́ sínú omi, ẹja náà yóò fi párì rẹ̀ lílágbára fọ́ èèpo rẹ̀, yóò gbé kóró èso náà mì, èso ara wọn yóò sì dà nínú rẹ̀, yóò sì yà wọ́n sílẹ̀ igbó náà láti hù nígbà tí ìkún omi náà bá fà. Ẹja àti igi jàǹfààní. Ẹja tambaqui ń kó ọ̀rá sára, àwọn igi sì ń ṣèmújáde igi kéékèèké. Gígé àwọn igi wọ̀nyẹn ń wu wíwà nìṣó ẹja tambaqui àti nǹkan bí àwọn 200 irú ọ̀wọ́ ẹja ajèso mìíràn léwu.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Àwọn àdán ń gbé lẹ́búlẹ́bú láti ara akọ òdòdó lọ sí ara abo rẹ̀
[Credit Line]
Rogério Gribel
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ibi ìtọ́jú irúgbìn àti ilé egbòogi igbó rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Iná ń wu ààlà ilẹ̀ aláwọ̀ ewé léwu
[Credit Line]
Philip M. Fearnside