Wíwá Ojútùú Kiri
ÒǸKỌ̀WÉ ọmọ ilẹ̀ England náà, John Lyly, sọ pé: “A lè máa fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ kí a máa pa làpálàpá.” Láti yẹra fún ọ̀fìn yẹn, ó yẹ kí a fi sọ́kàn ní gidi pé àwọn ìbànújẹ́ tí a ń ní lónìí nípa igbó kìjikìji jẹ́ ipa àbájáde àwọn ìṣòro líle koko àti pé ìpagbórun yóò máa bá a lọ, àyàfi tí a bá yanjú ìṣòro rẹ̀ láti ìpìlẹ̀. Kí ni àwọn okùnfà wọ̀nyẹn? Ìwádìí kan tí àjọ UN ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ sọ pé, “orísun ipá tí ń gbógun ti ìdáàbòbo Amazon ni ipò òṣì ẹ̀dá ènìyàn àti àìdọ́gba wọn.”
Ìlànà Ìṣèmújáde Ohun Ọ̀gbìn Tí Kò Fi Bẹ́ẹ̀ Gbéṣẹ́
Àwọn olùṣèwádìí kan ṣàlàyé pé, ìpagbórun jẹ́ apá kan àbájáde búburú ti ohun tí a pè ní ìlànà ìṣèmújáde ohun ọ̀gbìn lọ́nà púpọ̀ sí i, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn ní ìhà gúúsù àti àárín gbùngbùn Brazil. Kí ìyẹn tó bẹ̀rẹ̀, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìdílé tí wọ́n ní oko kéékèèké níbẹ̀ ń rí oúnjẹ òòjọ́ wọn nípa gbígbin ìrẹsì, ẹ̀wà, àti ọ̀dùnkún àti nípa sísin ẹran láfikún sí i. Lẹ́yìn náà, iṣẹ́ ìdáwọ́lé aládàá ńlá ti lílo ẹ̀rọ fún ṣíṣọ̀gbìn ẹ̀wà sóyà àti ṣíṣèmújáde iná mànàmáná gba ilẹ̀ wọn, ó sì fi àwọn ìṣèmújáde oníṣẹ́ àgbẹ̀ tí a pa mọ́ fún bíbọ́ àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ okòwò ńlá rọ́pò àwọn màlúù àti irè oko àdúgbò. Láàárín ọdún 1966 sí 1979 nìkan, ilẹ̀ oko tí a yà sọ́tọ̀ fún irè oko tí ó wà fún kíkó lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fi ìpín 182 lórí ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ní àbájáde rẹ̀, 11 lára àwọn àgbẹ̀ aroko 12 pàdánù ilẹ̀ àti oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ìlànà ìṣèmújáde ohun ọ̀gbìn lọ́nà púpọ̀ sí i yọrí sí ìlànà amúnipòkúdu fún wọn.
Ibo ni àwọn àgbẹ̀ tí kò ní ilẹ̀ wọ̀nyí lè lọ? Àwọn òṣèlú, tí wọn kò ṣe tán láti fi àìṣègbè bójú tó ọ̀ràn ilẹ̀ pípín ní àgbègbè ilẹ̀ tiwọn, fi ọ̀nà hàn wọ́n nípa pípolongo àgbègbè ilẹ̀ Amazon bí “ilẹ̀ tí kò lólúwa fún ìlò àwọn ènìyàn tí kò nílẹ̀.” Láàárín ẹ̀wádún kan lẹ́yìn tí wọ́n ṣí àkọ́kọ́ lára àwọn ọ̀nà Amazon sílẹ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọ̀kẹ́ àwọn àgbẹ̀ aláìní láti ìhà gúúsù Brazil àti àwọn ará ìhà àríwá ìlà oòrùn Brazil tí ọ̀dá àti ipò òṣì kọ lù tí wọ́n ti tẹ̀ dó sínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ahéré lẹ́bàá ọ̀nà náà. Nígbà tí wọ́n la àwọn ọ̀nà púpọ̀ sí i, àwọn púpọ̀ tí ń wọ̀nà láti di àgbẹ̀ lọ sí Amazon, ní ìmúrasílẹ̀ láti pa igbó dà sí ilẹ̀ oko. Bí àwọn olùṣèwádìí ṣe ronú sẹ́yìn nípa àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtẹ̀lúdó wọ̀nyí, wọ́n sọ pé, “tí a bá yiiri ìtẹ̀lúdó tí ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé 50 ọdún náà wò, àbájáde rẹ̀ kò fọre.” Ipò òṣì àti ìṣègbè “bá àwọn olùtẹ̀dó náà wọ Amazon,” bákan náà ni wọ́n “ti dá àwọn ìṣòro tuntun sílẹ̀ ní àgbègbè Amazon.”
Ìgbésẹ̀ Mẹ́ta Síwájú
Láti ṣèrànwọ́ ní gbígbógun ti àwọn okùnfà ìpagbórun, kí a sì mú kí ipò ìgbésí ayé ènìyàn sunwọ̀n sí i nínú igbó kìjikìji Amazon, Àjọ Àbójútó Ìdàgbàsókè àti Àyíká Amazon ṣe ìwé kan jáde, tí ń dámọ̀ràn pé kí àwọn ìjọba tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Amazon gbé ìgbésẹ̀ mẹ́ta lákọ̀ọ́kọ́ ní àfikún sí àwọn nǹkan mìíràn. (1) Ẹ darí àfiyèsí sí àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé àti ti àwùjọ tí wọ́n wà nínú ipò òṣì lóde igbó kìjikìji Amazon. (2) Ẹ lo igbó tí ó wà, kí ẹ sì tún àwọn àgbègbè igbó tí a ti pa run lò. (3) Ẹ rí sí àwọn ìwà ìṣègbè gbígbópọn láàárín àwùjọ—ohun tí ń fa ipò ìnira ẹ̀dá ènìyàn àti ìpagbórun gangan. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Dídókòwò
Ẹ darí àfiyèsí sí àwọn ìṣòro àwùjọ àti ti ọrọ̀ ajé. Àjọ náà sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn yíyàn tí ó gbéṣẹ́ jù láti dín ìpagbórun kù jẹ́ láti dókòwò lórí díẹ̀ lára àwọn àgbègbè tí ó tòṣì jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè Amazon, àwọn èyí tí ó jẹ́ kí àwọn ènìyàn fi ọ̀ran-anyàn rọ́ lọ sí Amazon láti wá ọjọ́ ọ̀la tí ó sàn jù.” Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn mẹ́ńbà àjọ náà fi kún un pé, “a kì í sábà gbé yíyàn yí yẹ̀ wò nínú ìṣètò ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè tàbí ti ẹkùn ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ okòwò ńlá tí ń ṣonígbọ̀wọ́ dídín ìwọ̀n pípa igbó Amazon run kù lọ́nà lílámì kì í ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ náà ṣàlàyé pé, bí àwọn aláṣẹ ìjọba àti àwọn ìjọba ilẹ̀ òkèèrè tí ń dàníyàn bá darí òye yíyè kooro àti owó ìtìlẹ́yìn wọn sórí yíyanjú àwọn ìṣòro bí àìtó ilẹ̀ fún gbogbo ènìyàn tàbí ipò òṣì ní ìlú ńlá ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ tí ó yí Amazon ká, wọn yóò fawọ́ kíkó tí àwọn àgbẹ̀ ń kó lọ sí Amazon kù, wọn óò sì ṣèrànwọ́ láti gba igbó náà là.
Bí ó ti wù kí ó rí, kí ni a lè ṣe fún àwọn àgbẹ̀ kéékèèké tí wọ́n ti ń gbé Amazon ná? Wíwà nìṣó wọn ojoojúmọ́ sinmi lé gbígbin irè oko sórí ilẹ̀ tí kò dára fún ọ̀gbìn.
Dídáàbò Bo Igbó Nítorí Àwọn Igi
Ẹ lo igbó náà lálòtúnlò. Lẹ́tà ìròyìn náà, The Disappearing Forests, ìtẹ̀jáde kan tí àjọ UN ṣe, sọ pé: “A ti lo àwọn igbó ilẹ̀ olóoru láìtọ́ jù, àmọ́, a kò lò wọ́n tó. Wíwà nìṣó wọn sinmi lórí ẹ̀dà ọ̀rọ̀ yí.” Ògbóǹkangí kan sọ pé, dípò lílo igbó náà láìtọ́ nípa gígé e lulẹ̀, ó yẹ kí ènìyàn lo igbó náà nípa mímú àwọn irè inú rẹ̀, bí èso, kóró èso, epo, rọ́bà, èròjà olóòórùn dídùn, irúgbìn fún egbòogi, àti àwọn irè àdánidá mìíràn jáde nínú rẹ̀ tàbí kí a kórè wọn. Ó sọ pé irú àwọn ìmújáde oko bẹ́ẹ̀ dúró fún “ìfojúdíwọ̀n ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún iye tí igbó náà tó ní ti ìṣúnná owó.”
Doug Daly, láti Ọgbà Ìtọ́jú Ohun Ọ̀gbìn ní New York, ṣàlàyé ìdí tí òun ṣe gbà gbọ́ pé ṣíṣí kúrò lórí pípa igbó run sórí mímú nǹkan jáde láti inú igbó bọ́gbọ́n mu pé: “Ó ń tu ìjọba lójú—wọn kò rí i kí a yọ àwọn apá títóbi ní ilẹ̀ Amazon kúrò lágbo káràkátà. . . . Ó lè pèsè oúnjẹ òòjọ́ àti iṣẹ́ ṣiṣe fún àwọn ènìyàn, ó sì ń dáàbò bo igbó. Ó ṣòro gidigidi láti rí ohun tí kò dára sọ nípa rẹ̀.”—Wildlife Conservation.
Dídáàbò bo igbó nítorí àwọn igi ń mú kí ipò ìgbésí ayé àwọn olùgbé inú igbó náà sunwọ̀n sí i ní tòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, àwọn olùṣèwádìí ní Belém, ìhà àríwá Brazil, ti ṣèṣirò pé yíyí hẹ́kítà kan ilẹ̀ dà di pápá oko tútù yóò mú èrè dọ́là 25 péré wá lọ́dún. Nítorí náà, láti wulẹ̀ pa owó oṣù tí ó kéré jù lọ ní Brazil, ọkùnrin kan ní láti ní hẹ́kítà 48 pápá oko tútù àti màlúù 16. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé ìròyìn Veja sọ pé, ẹni tí ń bọ̀ wá ni agbo ẹran yẹn lè pa owó púpọ̀ sí i nípa mímu àwọn ohun àdánidá jáde láti inú igbó náà. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè náà, Charles Clement, sọ pé, bí àwọn ohun àmújáde tí ń dúró de ìgbà tí a óò kó wọn pọ̀ ti pọ̀ tó ń yani lẹ́nu. Ọ̀mọ̀wé Clement fi kún un pé: “Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ewébẹ̀, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èso, oje igi, àti epo tí a lè bójú tó, kí a sì kórè rẹ̀ ló wà. Àmọ́, ìṣòro náà ni pé ènìyàn gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé igbó náà jẹ́ orísun ọrọ̀ dípò kí ó jẹ́ ìdíwọ́ fún dídi ọlọ́rọ̀.”
Àǹfààní Mìíràn fún Ilẹ̀ Tí A Fi Ṣòfò
João Ferraz, olùṣèwádìí kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Brazil, sọ pé, ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé àti ìdáàbòbo àyíká lè lọ pọ̀. “Ẹ wo iye igbó tí a ti pa run ná. Kò sí ìdí láti gé àwọn igbó tí a kò tí ì lò rí mìíràn lulẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè gba àwọn àgbègbè tí a ti pa run, tí a sì ti rẹ agbára wọn nípò wálẹ̀ pa dà, kí a sì tún wọn lò.” Ní ẹkùn ilẹ̀ Amazon, ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tí a ti rẹ agbára wọn nípò wálẹ̀ wà tí a lè gbà pa dà.
Bẹ̀rẹ̀ ní apá ìparí àwọn ọdún 1960, ìjọba gbé owó rẹpẹtẹ kalẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn olùdókòwò ńlá láti pa igbó náà dà sí pápá oko tútù. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Ferraz ṣe ṣàlàyé, “wọ́n rẹ pápá oko tútù náà nípò wálẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́fà. Lẹ́yìn náà, nígbà tí gbogbo ènìyàn wá mọ̀ pé àṣìṣe ńlá ni, àwọn onílẹ̀ ńláńlá sọ pé: ‘Ó dára, a ti gba owó tí ó pọ̀ tó lọ́wọ́ ìjọba,’ wọ́n sì fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Kí wá ni àbájáde rẹ̀? “Nǹkan bí 80,000 máìlì [200,000 kìlómítà níbùú lóròó] pápá oko tútù níbùú lóròó tí a pa tì ń kú lọ.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lónìí, àwọn olùṣèwádìí bíi Ferraz ń wá àwọn ọ̀nà tuntun tí a lè gbà lo àwọn ilẹ̀ tí a rẹ agbára wọn nípò wálẹ̀ wọ̀nyí. Lọ́nà wo? Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n gbin 320,000 èèhù kóró èso ilẹ̀ Amazon sórí oko ọ̀sìn màlúù kan tí a ti pa tì. Lónìí, àwọn èèhù wọ̀nyẹn ń so èso. Níwọ̀n bí àwọn igi náà ti ń yára hù, tí wọ́n sì ń mú igi tí ó níye lórí jáde, wọ́n ti gbin àwọn èèhù kóró èso ilẹ̀ Amazon sórí ilẹ̀ tí a pa igbó rẹ̀ run ní onírúurú ìhà pẹ̀tẹ́lẹ̀ Amazon. Lójú ìwòye àwọn ògbóǹkangí náà, mímú àwọn nǹkan jáde, kíkọ́ àwọn àgbẹ̀ láti gbin àwọn irè oko tí ń hù ní tòjòtẹ̀rùn, gbígba àwọn ìlànà mú lò láti kórè igi láìpa igbó lára, àti mímú àwọn ilẹ̀ tí a ti rẹ agbára wọn nípò wálẹ̀ pa dà bọ̀ sípò ni yíyàn míràn tí ó kún fún òye, tí ó lè ṣèrànwọ́ láti mú kí igbó náà máa wà nìṣó.—Wo àpótí náà, “Ṣíṣiṣẹ́ fún Ìdáàbòbò.”
Síbẹ̀, àwọn aláṣẹ sọ pé, gbígba àwọn igbó là béèrè ju pípa ilẹ̀ tí a rẹ agbára rẹ̀ nípò wálẹ̀ dà, lọ. Ó ń béèrè fún yíyí àbùdá ẹ̀dá ènìyàn pa dà.
Bí A Ṣe Lè Mú Ohun Tí Ó Wọ́ Tọ́
Ẹ rí sí àwọn ìwà ìṣègbè. Ìwọra ló sábà máa ń fa kí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ojúsàájú, tí ń tẹ ẹ̀tọ́ àwọn ẹlòmíràn lójú. Bí ọlọ́gbọ́n èrò orí ìgbàanì náà, Seneca, sì ṣe sọ, “gbogbo ìṣẹ̀dá kò lè tẹ́ ìwọra lọ́rùn”—títí kan igbó kìjikìji Amazon gbígbòòrò náà.
Ní ìyàtọ̀ sí àwọn àgbẹ̀ aláìní, tí ń làkàkà ní Amazon, àwọn onílé iṣẹ́ okòwò àti àwọn tí wọ́n ní ilẹ̀ ńláńlá ń ṣá igbó lulẹ̀ láti jẹ èrè gọbọi. Àwọn aláṣẹ sì tọ́ka pé a sì tún ní láti bá àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn wí fún lílọ́wọ́ nínú pípa igbó Amazon run lọ́nà gíga. Àwùjọ àwọn olùṣèwádìí kan láti Germany sọ pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè ọlọ́rọ̀, tí wọ́n jẹ́ onílé iṣẹ́ olówò ńlá” ti “ṣokùnfà ìbàjẹ́ àyíká tí ó ti wà ná lọ́nà gíga.” Àjọ Àbójútó Ìdàgbàsókè àti Àyíká Amazon sọ pé dájúdájú, dídáàbò bo Amazon ń béèrè fún “ìlànà ìwà híhù tuntun lágbàáyé, ìlànà ìwà híhù tí yóò mú àṣà ìdàgbàsókè tí a mú sunwọ̀n, tí a gbé karí ìsowọ́pọ̀ṣọ̀kan àti àìṣègbè ẹ̀dá ènìyàn, wá.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èéfín tó ṣì ń bo Amazon nítorí igbó ṣíṣá àti sísun ún, ránni létí pé, láìka àwọn ìsapá tọkùnrin-tobìnrin tí ọ̀ràn nípa àyíká ń jẹ lọ́kàn jákèjádò ayé sí, yíyí àwọn èrò olóye dà sí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi ń fẹ̀rí jíjẹ́ ìṣòro gan-an bí ìgbà tí a bá fẹ́ gbá èéfín mú hàn. Èé ṣe?
Gbòǹgbò àwọn ìwà abèṣe bí ìwọra ti fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú ìpìlẹ̀ ìgbékalẹ̀ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn, ó rinlẹ̀ gan-an ju bí gbòǹgbò àwọn igi inú Amazon ṣe jinlẹ̀ tó nínú ilẹ̀ igbó náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ kí àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe ohun tí a bá lè ṣe láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdáàbòbo igbó, kò bọ́gbọ́n mu láti retí pé, láìka bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe lè jẹ́ aláìlábòòsí tó sí, yóò ṣàṣeyọrí ní fífa àwọn ohun rírinlẹ̀, tí ó sì díjú pọ̀, tí ń fa ìpagbórun tu tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Ohun tí Ọba Sólómọ́nì ìgbàanì, olùwòye àbùdá ẹ̀dá ènìyàn, sọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn ṣì jẹ́ òtítọ́. “A kò lè mú èyí tí ó wọ́ tọ́” nípasẹ̀ ìsapá ẹ̀dá ènìyàn nìkan. (Oníwàásù 1:15) Òwe Portugal kan tí ó jọ ìyẹn ni, “O pau que nasce torto, morre torto” (Wíwọ́ ni igi tí ó hù ní wíwọ́ yóò wọ́ títí yóò fi kú). Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn igbó kìjikìji tí ó wà lágbàáyé ní ọjọ́ ọ̀la kan. Èé ṣe?
Ìlàlóye Wà Lọ́jọ́ Iwájú
Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, pípọ̀ tí ohun alààyè pọ̀ rẹpẹtẹ nínú igbó Amazon wú òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Brazil náà, Euclides da Cunha, lórí gan-an tí ó fi ṣàpèjúwe igbó náà bí “abala apá kan ìwé Jẹ́nẹ́sísì tí a kò ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ tí a ń rí lónìí.” Bí ó sì tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ ènìyàn ti dí ní bíba “abala” yẹn jẹ́ àti ní fífà á ya, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Amazonia Without Myths ti sọ, Amazon tí ó wà náà ṣì jẹ́ “àmì pé ilẹ̀ ń yán hànhàn láti pa dà sí bí ó ṣe wà nígbà Ìṣẹ̀dá.” Àmọ́ báwo ni yóò ti pẹ́ tó?
Ronú èyí wò ná: Gẹ́gẹ́ bí Da Cunha ti sọ ọ́, igbó kìjikìji Amazon àti àwọn igbó kìjikìji mìíràn láyé fi ẹ̀rí “làákàyè àrà ọ̀tọ̀ kan” hàn. Láti inú gbòǹgbò wọn dé inú ewé wọn, àwọn igi inú igbó náà ń fi hàn pé iṣẹ́ ọwọ́ ọ̀gá olùṣètò kan ni àwọn jẹ́. Bí ọ̀ràn ti rí bẹ́ẹ̀, Olùṣètò Ńlá yìí yóò ha gba àwọn oníwọra láyè láti pa àwọn igbó kìjikìji run, kí wọ́n sì run ilẹ̀ ayé bí? Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan dáhùn ìbéèrè yí lọ́nà dídún lọ réré pé, bẹ́ẹ̀ kọ́! Ó kà pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú tìrẹ [Ọlọ́run] sì dé, àti àkókò tí a yàn kalẹ̀ . . . láti mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.”—Ìṣípayá 11:18.
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣàkíyèsí pé àsọtẹ́lẹ̀ yí wí fún wa pé, kì í ṣe pé Ẹlẹ́dàá yóò rídìí gbòǹgbò ìṣòro náà nípa mímú àwọn oníwọra kúrò nìkan ni, àmọ́, pé ní àkókò tiwa ni yóò ṣe ìyẹn. Èé ṣe tí a fi lè sọ gbólóhùn yí? Ní gidi, àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í gbégbèésẹ̀ ní àkókò kan tí ènìyàn bá ń “run” ayé “bà jẹ́.” Nígbà tí a kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn, ènìyàn kò pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ sì ni èèlò tí wọ́n lè fi ṣe ìyẹn kò tó. Àmọ́, ipò náà ti yàtọ̀. Ìwé náà, Protecting the Tropical Forests—A High-Priority International Task, sọ pé: “Fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, ó wà ní ipò àtiba ìpìlẹ̀ wíwà nìṣó òun fúnra rẹ̀ jẹ́ lónìí, kì í ṣe ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ kan tàbí àwọn àgbègbè kan nìkan ni, àmọ́ kárí ayé.”
Nítorí náà, “àkókò tí a yàn kalẹ̀” tí Ẹlẹ́dàá náà yóò gbégbèésẹ̀ lòdì sí “àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́” ti sún mọ́lé. Igbó kìjikìji Amazon àti àwọn àyíká mìíràn tí a wu léwu lórí ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ ọ̀la kan. Ẹlẹ́dàá yóò rí i dájú pé ó ṣẹlẹ̀—ìyẹn kì í sì í ṣe àròsọ, àmọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ gidi.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Ṣíṣiṣẹ́ fún Ìdáàbòbò
Àtúnhù igbó ńlá kan tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó 400,000 mítà níbùú lóròó ní àárín gbùngbùn ìlú ńlá Manaus ní Amazon ni onírúurú ọ́fíìsì Ilé Iṣẹ́ Ìṣèwádìí Àpapọ̀ fún Amazon, ní Brazil, tàbí INPA, fi ṣe ilé. Ilé iṣẹ́ tí ó ti wà fún ọdún 42 yí, tí ó ní ẹ̀ka 13 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ń bójú tó ohun gbogbo láti àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn dé orí àbójútó igbó dé orí ìlera ẹ̀dá ènìyàn ni ilé iṣẹ́ ìṣèwádìí tí ó tóbi jù lọ ní ẹkùn ilẹ̀ náà. Ó tún jẹ́ ilé fún ọ̀kan lára ibi àkójọ àwọn irúgbìn, ẹja, eranko afàyàfà, jomijòkè, ẹranko afọ́mọlọ́mú, ẹyẹ, àti àwọn kòkòrò inú Amazon tí ó kún jù lọ lágbàáyé. Iṣẹ́ ọwọ́ àwọn 280 olùṣèwádìí tí ilé iṣẹ́ náà ní ń ṣàlékún òye sísunwọ̀n tí ènìyàn ní nípa àwọn ìbáṣepọ̀ dídíjú àárín àwọn ohun alààyè pẹ̀lú àyíká wọn ní Amazon. Àwọn tí wọ́n ti ṣèbẹ̀wò sí ilé iṣẹ́ náà ní ìmọ̀lára ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára nígbà tí wọ́n ń fi ibẹ̀ sílẹ̀. Láìka àwọn ìkálọ́wọ́kò òfin ìjọba àti ti ìṣèlú sí, àwọn ará Brazil àti àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ láti ilẹ̀ òkèèrè ti múra tán láti ṣiṣẹ́ fún ìdáàbòbò yíyọrí-ọlá láàárín àwọn igbó kìjikìji lágbàáyé—Amazon.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ọ̀nà tí a là gba àárín igbó fún gígé gẹdú
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Àwọn ìmújáde oko láti inú igbó kìjikìji náà: àwọn èso, kóró èso, epo, rọ́bà, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan
[Credit Line]
J. van Leeuwen, INPA-CPCA, Manaus, Brazil