Pípiyẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji
NÍGBÀ kan rí, ojú ilẹ̀ aláwọ̀-ewé mèremère kan, tó gbòòrò, wà ní àyíká pílánẹ́ẹ̀tì wa. Onírúurú igi ló wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn odò fífẹ̀ pẹ̀lú.
Bí ilé ewéko àdánidá ńlá kan, ó jẹ́ àgbègbè rírẹwà tó ní onírúurú nǹkan nínú. Ìdajì àwọn irú ọ̀wọ́ ẹranko, ẹyẹ, àti kòkòrò, tí ń bẹ lágbàáyé, ló ń gbébẹ̀. Àmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni àgbègbè tó ní nǹkan nínú jù lọ lórí ilẹ̀ ayé, ó tún ṣe ẹlẹgẹ́ pẹ̀lú—ó ṣe ẹlẹgẹ́ ju bí ẹnikẹ́ni ti rò lọ.
Ó jọ pé igbó kìjikìji ilẹ̀ olóoru, bí a ti ń pè é nísinsìnyí, tóbi gan-an—ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé bà jẹ́. Àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀. Igbó kìjikìji náà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pòórá ní àwọn erékùṣù Carib. Ní 1671—ọdún mẹ́wàá kí ẹyẹ dodo tó kú run—àwọn oko ìrèké ti rọ́pò igbó náà ní Barbados.a Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn igbó mìíràn ní ẹkùn ilẹ̀ náà, ó jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kárí ayé kan tí ó ti wá ń yára kánkán ní ọ̀rúndún ogún.
Ní báyìí, ìpín 5 péré nínú ọgọ́rùn-ún ojú ilẹ̀ ayé ni igbó kìjikìji ti ilẹ̀ olóoru wà, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún tó jẹ́ ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn. Lọ́dọọdún sì ni a ń gé àpapọ̀ ilẹ̀ igbó tó tóbi ju ìwọ̀n ilẹ̀ England lọ, tàbí 130,000 kìlómítà níbùú lóròó, lulẹ̀, tàbí tí a ń sun wọ́n. Ìwọ̀n ìparun kíkaniláyà yìí ń wu igbó kìjikìji—àti gbogbo ohun tí ń gbé inú rẹ̀—ní ewu kan náà bí ti ẹyẹ dodo. Philip Fearnside, olùwádìí nípa igbó kìjikìji ní Brazil kìlọ̀ pé: “A kò lè sọ pé igbó náà yóò pòórá lọ́dún kan pàtó, àmọ́ bí nǹkan kò bá yí padà, igbó náà yóò pòórá.” Ní October ọdún tó kọjá, Diana Jean Schemo sọ pé: “Àwọn ìsọfúnni oníṣirò tí a rí láàárín àwọn ọ̀sẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé igbó tí a ń gé tí a sì ń sun ní Brazil lọ́dún yìí ju ohun tí ó tíì ṣẹlẹ̀ rí ní Indonesia lọ, níbi tí èéfín ńláńlá ti bo àwọn lájorí ìlú ńláńlá mọ́lẹ̀, tí ó sì tún tàn lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. . . . Àkọsílẹ̀ oníṣirò láti ọ̀dọ̀ àwọn tí a gbà sí iṣẹ́ àkíyèsí, àti iye ìpagbórun ti 1994, tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní lọ́ọ́lọ́ọ́, fi hàn pé dídánásungbó ní ẹkùn ilẹ̀ Amazon ti fi ìpín 28 nínú ọgọ́rùn-ún lọ sókè ju tèṣí lọ, ó sì jẹ́ ìlọsókè ìpín 34 nínú ọgọ́rùn-ún láti 1991 wá.”
“Àwọn Igi Tí Ń Hù Láṣálẹ̀”
Kí ló fà á tí a fi ń pa àwọn igbó kìjikìji tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tó yingin lára wọn ní ọ̀rúndún kan sẹ́yìn run kíákíá bẹ́ẹ̀? Àwọn igbó ilẹ̀ tí ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, tó jẹ́ ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún ojú ilẹ̀ ayé, kò tíì dín kù lọ́nà gbígbàfiyèsí bẹ́ẹ̀ láàárín 50 ọdún tó kọjá. Kí ló mú kí àwọn igbó kìjikìji ṣeé wu léwu tó bẹ́ẹ̀? Ìdáhùn náà wà nínú ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n ní.
Arnold Newman, sọ nínú ìwé rẹ̀, Tropical Rainforest, pé a ti júwe igbó kìjikìji lọ́nà yíyẹ gẹ́gẹ́ bí “àwọn igi tí ń hù láṣálẹ̀.” Ó ṣàlàyé pé ní àwọn apá kan bèbè odò Amazon àti ní Borneo, “kódà, ilẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ iyanrìn funfun pátápátá ń hu àwọn igbó ńláńlá lọ́nà tó yani lẹ́nu.” Nígbà tó ṣe pé ọ̀pọ̀ jù lọ igbó kìjikìji ni kò sí lórí iyanrìn, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo wọn ló wà lórí ilẹ̀ tí kò lọ́ràá, tí ilẹ̀dú ibẹ̀ kò pọ̀. Nígbà tí ilẹ̀dú tó wà ní igbó ilẹ̀ tí ojú ọjọ́ ti wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lè jinlẹ̀ tó mítà méjì, èyí tó jinlẹ̀ ju sẹ̀ǹtímítà márùn-ún lọ kò wọ́pọ̀ nínú igbó kìjikìji. Ọ̀nà wo ni ìwọ̀n ewéko títutùyọ̀yọ̀ jù lọ lórí ilẹ̀ ayé lè gbà gbilẹ̀ dáadáa nínú irú àyíká tí kò ní láárí bẹ́ẹ̀?
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàwárí ojútùú sí àdììtú yìí ní àwọn ọdún 1960 àti 1970. Wọ́n rí i pé igbó náà ní ń bọ́ ara rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oúnjẹ ọlọ́ràá tí àwọn ewéko náà nílò ni àwọn àrẹ̀ẹ́lẹ̀ ẹ̀ka àti ewé tó wà lórí ilẹ̀ igbó náà ń pèsè, àti pé—ọpẹ́lọpẹ́ ooru àti ọ̀rinrin tí ń wà níbẹ̀ nígbà gbogbo—àwọn ikán, olú, àti àwọn ohun alààyè mìíràn ń yára mú kí wọ́n jẹrà. Kò sí ohun tí ń ṣòfò; ohun gbogbo la ń tún lò. Nípasẹ̀ fífà tí àwọn igi ń fa omi mu àti fífà tí oòrùn ń fa omi gbẹ láti orí ẹ̀ka igi tó bò lókè, igbó kìjikìji máa ń ṣàtúnlò èyí tó pọ̀ tó ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún òjò tó ń rọ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, kùrukùru tí ìgbésẹ̀ yìí ń mú wá ló tún ń bomi rin igbó náà.
Ṣùgbọ́n ìṣètò àgbàyanu yìí ní àbùkù kan. Bí ó bá bà jẹ́ jù, kò lè ṣàtúnṣe ara rẹ̀. Bí o bá gé àgbègbè kékeré kan lulẹ̀ nínú igbó kìjikìji, yóò tún padà sípò láàárín ọdún mélòó kan; ṣùgbọ́n bí o bá gé àgbègbè fífẹ̀ kan lulẹ̀, ó ṣeé ṣe kó má lè padà sípò láé. Àwọn òjò ńlá tí ń rọ̀ ń ṣan ọ̀rá ilẹ̀ tó wà dà nù, oòrùn mímúhanhan tó ń ràn sì ń mú kí ìwọ̀nba ilẹ̀dú fẹ́ẹ́rẹ́ náà dì títí di ìgbà tí ó fi jẹ́ pé àwọn ewéko líle koránkorán nìkan ló lè hù níbẹ̀.
Ilẹ̀, Gẹdú, àti Ẹran Àfihábúrẹ́dì
Lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí kò ní ilẹ̀ oko púpọ̀ tó, ó jọ pé ilẹ̀ igbó wọn gbígbòòrò tí ẹnikẹ́ni kò ro rí, ti tó fi ṣèfà jẹ. Ojútùú “rírọrùn” kan ni láti fún àwọn mẹ̀kúnnù aláìnílẹ̀ tó tálákà níṣìírí láti ṣá àwọn apá kan igbó náà kí wọ́n sì gbà á—tí ó jọ bí àwọn àṣíwọ̀lú ará Yúróòpù ṣe tẹ̀ dó níhà Ìwọ̀ Oòrùn Amẹ́ríkà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìyọrísí rẹ̀ ń ṣèbàjẹ́ fún igbó náà àti àwọn àgbẹ̀ náà lápapọ̀.
Igbó kìjikìji ọlọ́ràá náà lè fúnni lérò pé ohunkóhun tí a bá gbìn síbẹ̀ yóò dára. Ṣùgbọ́n ní kété tí a bá ti gé àwọn igi náà lulẹ̀, èròǹgbà nípa ọ̀rá ilẹ̀ náà ń pòórá ní kíákíá. Victoria, obìnrin ará Áfíríkà kan tí ń ro ilẹ̀ kékeré kan tí ìdílé rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ mú lára igbó náà láìpẹ́, ṣàlàyé ìṣòro náà.
“Bàbá ọkọ mi ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣá igbó yìí, ó sì sun ún kí n lè ríbi gbin ẹ̀pà, pákí, àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ díẹ̀ sí ni. Irè tí n óò kó lóko náà gbọ́dọ̀ dára gan-an lọ́dún yìí, ṣùgbọ́n lọ́dún méjì tàbí mẹ́ta sí i, ilẹ̀ náà yóò ṣá, yóò sì di dandan pé kí a ṣá ilẹ̀ mìíràn. Iṣẹ́ takuntakun ni, ṣùgbọ́n ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà máa gbọ́ bùkátà ni.”
Ó kéré tán, 200 mílíọ̀nù àgbẹ̀ agékosunko bí ti Victoria àti ìdílé rẹ̀ ló wà! Àwọn ni wọ́n sì ń pa ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún igbó tí a ń pa run lọ́dọọdún run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbẹ̀ alákòókiri wọ̀nyí ì bá yan ọ̀nà rírọrùn mìíràn láti ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ láàyò, wọn kò ní ọ̀nà mìíràn. Bí wọ́n ṣe ń kojú ìgbìyànjú ojoojúmọ́ láti gbọ́ bùkátà, dídáàbòbo-igbó-kìjikìji jẹ́ ohun afẹ́ tí wọn kò lè ṣe.
Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àgbẹ̀ ń gé igbó lulẹ̀ láti fi gbinrè, àwọn mìíràn ń gé e lulẹ̀ láti fi bọ́ ẹran. Nínú àwọn igbó kìjikìji Àáríngbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà, ọ̀sìn agbo ẹran jẹ́ orísun ìpagbórun pàtàkì mìíràn. Ẹran tí ń wá láti ara àwọn màlúù wọ̀nyí sábà máa ń kọjá lọ sí Àríwá Amẹ́ríkà níkẹyìn, níbi tí àwọn ilé iṣẹ́ ìpèsè oúnjẹ wàràǹṣeṣà ti ń fẹ́ ọ̀pọ̀ ẹran olówó-pọ́ọ́kú tí wọ́n fi ń ṣe ẹran lílọ̀ tí wọ́n fi ń há búrẹ́dì láàárín.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọlọ́sìn-ẹran ń ní ìṣòro kan náà tí àwọn àgbẹ̀ alárojẹ ń ní. Àwọn ewéko àfiṣoúnjẹ tí ń hù nínú ilẹ̀ eléérú igbó kìjikìji kì í sábà tó láti fi bọ́ ẹran ju ọdún márùn-ún lọ. Sísọ igbó kìjikìji di pápá ìjẹko màlúù lè mérè wá fún àwọn mélòó kan, ṣùgbọ́n ó dájú pé ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà ìfiǹkanṣòfò jù lọ láti gbà mú oúnjẹ jáde tí ènìyàn tíì ṣàwárí rẹ̀.b
Ewu pàtàkì mìíràn tí ń kojú igbó kìjikìji ni gígé gẹdú. Kì í ṣe pé gígé gẹdú ń pa igbó run ní gidi ṣáá ni. Àwọn ilé iṣẹ́ kan ń gé àwọn irú ọ̀wọ́ igi àfipawó kan lọ́nà kan tí igbó náà ń kọ́fẹ padà láìpẹ́. Àmọ́ ìdá méjì nínú mẹ́ta ìwọ̀n 45,000 kìlómítà igbó níbùú lóròó tí àwọn ilé iṣẹ́ gẹdú ń kó nífà lọ́dọọdún ni a ti ń gé ọ̀pọ̀ igi gẹdú lágèéjù tó bẹ́ẹ̀ tí ìpín 1 péré nínú 5 igi inú igbó fi ń wà láìfarapa.
Onímọ̀ nípa ewéko, Manuel Fidalgo, dárò pé: “Ó ń yà mí lẹ́nu nígbà tí mo bá rí igbó kíkàmàmà kan tí a pa run nípasẹ̀ gígé gẹdú lọ́nà àìláàlà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́ pé àwọn ewéko àti igi mìíràn lè hù ní àgbègbè tí a gé lulẹ̀ náà, igbó onípò-kejì ni èyí tí yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ hù náà—kì í ní láárí tó ní ti iye irú ọ̀wọ́ tí yóò wà níbẹ̀. Yóò gba ọ̀rọ̀ọ̀rúndún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rúndún pàápàá kí igbó àtijọ́ náà tó kọ́fẹ padà.”
Àwọn ilé iṣẹ́ agégẹdú tún ń mú ìparun igbó yára kánkán ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Ní pàtàkì, àwọn tí ń da ẹran jẹko àti àwọn àgbẹ̀ alákòókiri ń gba àwọn ọ̀nà tí àwọn agégẹdú là wọgbó. Nígbà mìíràn, àwọn ìràwé tí àwọn agégẹdú fi sílẹ̀ ló máa ń tanná ran igbó, tó sì ń pa igbó run ju igbó tí àwọn agégẹdú ti gé lọ. Ní Borneo, irú iná bẹ́ẹ̀ kan ṣoṣo ló sun àádọ́ta ọ̀kẹ́ hẹ́kítà ní 1983.
Kí La Ń Ṣe Láti Dáàbò Bo Igbó?
Nítorí àwọn ewu wọ̀nyí, a ń sapá láti dáàbò bo igbó tó ṣẹ́ kù. Àmọ́ iṣẹ́ náà tóbi gan-an. Àwọn ọgbà ohun alààyè ti orílẹ̀-èdè lè dáàbò bo igbó kìjikìji tọ́ọ́rọ́ kan, ṣùgbọ́n ọdẹ ṣíṣe, gẹdú gígé, àti iṣẹ́ àgbẹ̀ ìgékosunko ṣì ń bá a lọ nínú ọ̀pọ̀ ọgbà ohun alààyè. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà kò ní owó púpọ̀ tó láti ná sórí àbójútó ọgbà ohun alààyè.
Ó rọrùn fún àwọn ilé iṣẹ́ àgbáyé láti tan àwọn ìjọba tí owó ti gbẹ lápò wọn sí títa ẹ̀tọ́ ìgégẹdú—nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà mélòó kan tó wà láti fi san àwọn gbèsè tí wọ́n jẹ sí ilẹ̀ òkèèrè. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àgbẹ̀ alákòókiri kò sì ní ibòmíràn láti lọ ju kí wọ́n túbọ̀ wọnú igbó kìjikìji náà lọ.
Nínú ayé kan tí ọ̀pọ̀ ìṣòro bẹ́ẹ̀ fún lọ́rùn, dídáàbòbo-igbó-kìjikìji ha ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ bí? Kí ni a lè pàdánù bí wọ́n bá pòórá?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹyẹ dodo jẹ́ ẹyẹ ńlá kan, tó wúwo, tí kò lè fò, tí ó kú run ní 1681.
b Nítorí àtakò tó gbòdekan, àwọn ilé iṣẹ́ ìpèsè oúnjẹ ní wàràǹṣeṣà kan ti ṣíwọ́ kíkó ẹran olówó-pọ́ọ́kú wọlé láti àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ olóoru.