ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kọ́ríńtì 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kọ́ríńtì

      • Ó ń wu Pọ́ọ̀lù láti mú kí wọ́n láyọ̀ (1-4)

      • Ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n dárí jì, tí wọ́n sì gbà pa dà (5-11)

      • Pọ́ọ̀lù lọ sí Tíróásì àti Makedóníà (12, 13)

      • Iṣẹ́ òjíṣẹ́ jẹ́ ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun (14-17)

        • A kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (17)

2 Kọ́ríńtì 2:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 7:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    11/1/1996, ojú ìwé 11

2 Kọ́ríńtì 2:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 5:1

2 Kọ́ríńtì 2:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbé e mì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 15:23, 24
  • +Heb 12:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2010, ojú ìwé 13

    10/1/1998, ojú ìwé 17-18

2 Kọ́ríńtì 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 12:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2013, ojú ìwé 20

    10/1/1998, ojú ìwé 17

2 Kọ́ríńtì 2:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2006, ojú ìwé 29

2 Kọ́ríńtì 2:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọgbọ́n àyínìke.”

  • *

    Tàbí “èrò ọkàn; ète.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 22:31; 2Ti 2:26
  • +Ef 6:11, 12; 1Pe 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2006, ojú ìwé 27

    1/15/2006, ojú ìwé 29

    8/15/2002, ojú ìwé 26-28

    10/1/1998, ojú ìwé 18

2 Kọ́ríńtì 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 16:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 166

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/1998, ojú ìwé 30

2 Kọ́ríńtì 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 2:3; Tit 1:4
  • +2Kọ 7:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 166

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/1998, ojú ìwé 30

2 Kọ́ríńtì 2:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbalẹ̀ kan.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2010, ojú ìwé 23

    9/1/2005, ojú ìwé 31

2 Kọ́ríńtì 2:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2010, ojú ìwé 23

    7/15/2008, ojú ìwé 28

    9/1/2005, ojú ìwé 31

2 Kọ́ríńtì 2:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òórùn dídùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 15:19; 2Kọ 4:3; 1Pe 2:7, 8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2010, ojú ìwé 23

    7/15/2008, ojú ìwé 28

    9/1/2005, ojú ìwé 31

2 Kọ́ríńtì 2:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “a kò fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe òwò; a kò fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ èrè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 4:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/1/1992, ojú ìwé 26-29

Àwọn míì

2 Kọ́r. 2:42Kọ 7:8, 9
2 Kọ́r. 2:51Kọ 5:1
2 Kọ́r. 2:7Lk 15:23, 24
2 Kọ́r. 2:7Heb 12:12
2 Kọ́r. 2:8Ro 12:10
2 Kọ́r. 2:11Lk 22:31; 2Ti 2:26
2 Kọ́r. 2:11Ef 6:11, 12; 1Pe 5:8
2 Kọ́r. 2:12Iṣe 16:8
2 Kọ́r. 2:13Ga 2:3; Tit 1:4
2 Kọ́r. 2:132Kọ 7:5
2 Kọ́r. 2:16Jo 15:19; 2Kọ 4:3; 1Pe 2:7, 8
2 Kọ́r. 2:172Kọ 4:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kọ́ríńtì 2:1-17

Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì

2 Mo ti pinnu lọ́kàn mi pé mi ò ní wá sọ́dọ̀ yín nínú ìbànújẹ́ mọ́. 2 Torí tí mo bá bà yín nínú jẹ́, ta ló máa múnú mi dùn tí kì í bá ṣe ẹni tí mo bà nínú jẹ́? 3 Ìdí tí mo fi kọ ìwé tí mo kọ sí yín ni pé, tí mo bá dé mi ò ní banú jẹ́ lórí àwọn tó yẹ kí n máa yọ̀ nítorí wọn, torí ó dá mi lójú pé ohun tó ń fún mi láyọ̀ ń fún gbogbo yín náà láyọ̀. 4 Nítorí nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú àti ìdààmú ọkàn ni mo kọ̀wé sí yín pẹ̀lú ọ̀pọ̀ omijé, kì í ṣe láti bà yín nínú jẹ́,+ àmọ́ ó jẹ́ láti mú kí ẹ mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

5 Tí ẹnikẹ́ni bá ti fa ìbànújẹ́,+ èmi kọ́ ló bà nínú jẹ́, gbogbo yín ni dé àyè kan. Mi ò fẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi le koko jù. 6 Ìbáwí tó múná tí èyí tó pọ̀ jù lára yín ti fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti tó; 7 ní báyìí, ṣe ló yẹ kí ẹ dárí jì í tinútinú, kí ẹ sì tù ú nínú,+ kí ìbànújẹ́ tó pọ̀ lápọ̀jù má bàa bò ó mọ́lẹ̀.*+ 8 Torí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ òun.+ 9 Ìdí nìyí tí mo tún fi kọ̀wé sí yín: kí n lè mọ̀ bóyá ẹ máa ṣe ohun tó fi hàn pé ẹ jẹ́ onígbọràn nínú ohun gbogbo. 10 Tí ẹ bá dárí ohunkóhun ji ẹnikẹ́ni, èmi náà ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, ohunkóhun tí mo bá ti dárí rẹ̀ jini (ìyẹn tí mo bá ti dárí ohunkóhun jini) ó jẹ́ nítorí yín níwájú Kristi, 11 kí Sátánì má bàa fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n* borí wa,+ nítorí a mọ àwọn ọgbọ́n* rẹ̀.+

12 Nígbà tí mo dé Tíróásì+ láti kéde ìhìn rere nípa Kristi, tí ilẹ̀kùn kan sì ṣí fún mi nínú Olúwa, 13 ẹ̀mí mi ò lélẹ̀ torí mi ò rí Títù + arákùnrin mi. Torí náà, mo dágbére fún wọn, mo sì forí lé Makedóníà.+

14 Àmọ́ ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tó máa ń darí wa nínu ìjáde àwọn tó ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun pẹ̀lú Kristi, tó sì ń tipasẹ̀ wa mú kí òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ta sánsán* dé ibi gbogbo! 15 Nítorí lójú Ọlọ́run, a jẹ́ òórùn dídùn ti Kristi, tó ń ta sánsán láàárín àwọn tó ń rí ìgbàlà àti láàárín àwọn tó ń ṣègbé; 16 lójú àwọn tó ń ṣègbé, a jẹ́ òórùn* ikú tó ń yọrí sí ikú,+ lójú àwọn tó ń rí ìgbàlà, a jẹ́ òórùn dídùn ti ìyè tó ń yọrí sí ìyè. Ta ló sì kúnjú ìwọ̀n fún nǹkan wọ̀nyí? 17 Àwa ni, nítorí a kì í ṣe akirità ọ̀rọ̀ Ọlọ́run*+ bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe jẹ́, àmọ́ à ń fi òótọ́ inú sọ̀rọ̀ bí Ọlọ́run ṣe rán wa, àní, níwájú Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Kristi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́