ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/01 ojú ìwé 4
  • Ètò Mímú Kí Ìpínkiri Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rọrùn Tí A Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ètò Mímú Kí Ìpínkiri Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rọrùn Tí A Ṣe
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Máa Fúnrúgbìn ní Yanturu, Ṣùgbọ́n Lo Ìfòyemọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 4/01 ojú ìwé 4

Ètò Mímú Kí Ìpínkiri Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Rọrùn Tí A Ṣe

1 Ètò tí a mú rọrùn tí a fi ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kiri láìjẹ́ pé a dá iye owó kan lé e ti lé lọ́dún kan tó ti bẹ̀rẹ̀ báyìí. Ǹjẹ́ ètò yìí ti ṣàṣeyọrí? Àwọn ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá fi hàn pé iye tí a ń fi sóde nínú gbogbo ìwé wa túbọ̀ pọ̀ sí i. Ní ti gidi, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn la ń fún láǹfààní láti ‘wá gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.’—Ìṣí. 22:17.

2 Ṣùgbọ́n, a ò fi dandan mú wa, bẹ́ẹ̀ la ò sì fẹ́ láti kàn máa fi ìwé wa fún ẹnikẹ́ni tí yóò bá tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Bí a ṣe máa ń fi ọgbọ́n lo àwọn ohun ìní wa, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ ẹrù iṣẹ́ olúkúlùkù akéde láti fọgbọ́n lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá gbà látọ̀dọ̀ Society nípasẹ̀ ìjọ rẹ̀ láìsí pé Society dá iye owó kankan lé e. Bí Society bá tiẹ̀ ń fún àwọn akéde ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láìsí dídá iye owó kan lé e, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé kì í ṣe owó ni wọ́n fi ń tẹ̀ ẹ́, tí wọ́n sì fi ń pín in kiri. Gbogbo wa ló yẹ ka ní ìmọrírì gidigidi fún bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa ti wúlò tó nínú ríran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ bí wọn ti ń wá ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi kiri.—Jòh. 17:3.

3 Báwo ló ṣe wá ṣeé ṣe fún Society láti máa pèsè ìwé fún gbogbo èèyàn láìsí dídá iye owó kan lé e? Àwọn ọrẹ ìtìlẹyìn la fi ń bójú tó ìnáwó tó pọndandan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìwé títẹ̀ àti ìpínkiri rẹ̀. Ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ni ìtìlẹyìn yìí ti ń wá ní pàtàkì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò wo ọ̀dọ̀ àwọn aráàlú pé àwọn ni kó wá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ kánjúkánjú jù lọ yìí. A kò tíì ké sí àwọn aráàlú rí pé a fẹ́ ṣe ìkówójọ, bẹ́ẹ̀ la ò sì ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí. Ṣùgbọ́n, a mọrírì ọrẹ ìtìlẹyìn díẹ̀ tó ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tó ń fi ìfẹ́ àti ìmọrírì hàn látọkànwá tí a ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́.

4 Ohun Tí Ọrẹ Ìtìlẹyìn Wa Ń Ṣe: Nítorí náà, ó yẹ ká múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé ṣókí lọ́nà tó ṣe kedere nípa bí a ṣe ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tí a ń ṣe. Gbogbo owó tí a bá rí gbà la fi ń bójú tó ìnáwó ńláǹlà ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà lóde òní. Ní àfikún sí títẹ̀wé fún ìpínkiri jákèjádò ayé, Society tún ń náwó lórí àwọn ọ́fíìsì ẹ̀ka, ilé Bẹ́tẹ́lì, ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ilé ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì, títí kan àwọn míṣọ́nnárì, alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn ojúkò ibi tí a ti ń pín ìwé kiri, àti ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ ìtìlẹ́yìn mìíràn tó pọndandan fún ṣíṣe gbogbo ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ tí Jésù gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́.—Mát. 24:14; 28:19, 20.

5 Ìbísí pàtàkì tó ń wáyé láàárín àwọn èèyàn Jèhófà ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa béèrè pé kí làwọn lè ṣe láti ṣèrànwọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò lè fúnra wọn wá ṣèrànwọ́ ní kíkọ́ àwọn ẹ̀ka tuntun àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kí wọ́n lọ sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè láti ṣèrànwọ́ nínú iṣẹ́ ìjíhìnrere níbẹ̀. Ṣùgbọ́n kí wọ́n lè kópa kan débi tí agbára wọn dé nínú ìtẹ̀síwájú tó ń dùn mọ́ni tó ń wáyé yìí, ọ̀pọ̀ akéde àti ìdílé wọn sọ ọ́ dàṣà láti máa ya iye kan sọ́tọ̀ déédéé láti fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tí a ń ṣe kárí ayé yìí. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 16:1, 2.) Lọ́nà yìí, wọ́n ń ṣètìlẹyìn fún gbogbo ìgbòkègbodò Society, títí kan pípín ìwé kiri. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe wo ọrẹ àtinúwá tí wọ́n fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé náà pé ńṣe làwọ́n fi ń sanwó ìwé.

6 Nígbà tí a bá dé ọ̀dọ̀ onílé tàbí ọ̀dọ́ àwọn ẹlòmíràn láti jẹ́rìí fún wọn, a gbọ́dọ̀ múra tán láti bá wọn jíròrò ohun kan látinú Bíbélì. Nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, a dábàá onírúurú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó ń gbádùn mọ́ni àti ọ̀pọ̀ kókó ọ̀rọ̀ Bíbélì tó bá a mu. Tàbí kẹ̀, a lè lo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Akéde gbọ́dọ̀ pinnu ohun tí òun yóò ṣe ní ti fífi ìwé lọ ẹni náà, èyí sì sinmi lórí bí ẹni náà bá ṣe dáhùn sí ìhìn Ìjọba náà. Bí ó bá dà bíi pé ẹni ọ̀hún kò fìfẹ́ hàn tó débi tí o fi lè fi ìwé tàbí ìtẹ̀jáde mìíràn lọ̀ ọ́, o lè pinnu láti fọgbọ́n parí ìjíròrò náà kí o sì fi ẹni yẹn sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ ẹlòmíràn. Tàbí o lè fún ẹni náà ní ìwé ìléwọ́ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú bó bá ṣèlérí láti ka ohun tó wà nínú rẹ̀. Rí i dájú pé ó kọ àkọsílẹ̀ pé ẹni náà fìfẹ́ hàn kí o lè ṣe ìpadàbẹ̀wò. O lè ṣe ohun kan náà nígbà tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àkókò tí ó pọ̀ tó láti jíròrò lọ́nà tó nítumọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan nítorí pé ọwọ́ ẹni yẹn dí tàbí nítorí pé ìgbà tí kò sí àyè la dé ọ̀dọ̀ rẹ̀.

7 Ètò mímú kí ìpínkiri ìwé ìròyìn rọrùn ń mú kí olúkúlùkù rí i pé iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń ṣe kò jẹ mọ́ ti ìṣòwò lọ́nàkọnà. Ó tún ń jẹ́ ká lè gbájú mọ́ góńgó wa ti wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn àjọ tó ń ṣe ètò “ìtọrọ ọrẹ fáwọn aláìní,” inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dùn láti rí i pé ìwé wa ń tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́ láìjẹ́ pé a ń dá iye owó kan lé e. A kì í béèrè ọrẹ ìtìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé náà látọ̀dọ̀ àwọn tí kò ní ojúlówó ìfẹ́ nínú iṣẹ́ tí a ń jẹ́. (Wo Ilé-ìṣọ́nà, December 1, 1990, ojú ìwé 22 àti 23.) Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé yìí la ń fi gbogbo ọrẹ ìtìlẹyìn bójú tó, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ ìyọ̀ǹda-ara-ẹni làwọn òṣìṣẹ́ wa ń ṣe, tí a kì í sì í sanwó oṣù tàbí èlé orí ọjà fún ẹnikẹ́ni nínú ètò àjọ wa. Àwọn tó bá béèrè nípa rẹ̀ tàbí àwọn tó bá fi ìfẹ́ hàn sí iṣẹ́ wa nìkan la máa ń bá jíròrò ọ̀ràn fífi ọrẹ ṣètìlẹyìn láti ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ kárí ayé náà.

8 Bí a ṣe ń fi ìtara mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i, tí a sì ń fọgbọ́n lo àwọn ìtẹ̀jáde oníyebíye ti Society, Jèhófà yóò máa mú ìbísí wá. Àwọn èèyàn ọlọ́kàn rere níbi gbogbo ń mọrírì àwọn àlàyé tí a bá fi ìrònújinlẹ̀ ṣe nípa bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe rí, inú wọn sì máa ń dùn bí wọ́n ti ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́