Máa Fúnrúgbìn ní Yanturu, Ṣùgbọ́n Lo Ìfòyemọ̀
1 Kò sí àgbẹ̀ tí kò mọ̀ pé bí òun bá fúnrúgbìn ní yanturu, òun á kórè ní yanturu bí nǹkan kò bá yíwọ́, ṣùgbọ́n bí òun bá fúnrúgbìn kín-ún, ó ti dájú pé kín-ún náà lòun máa kórè. (2 Kọ́r. 9:6) Àwọn àgbẹ̀ máa ń ṣọ́ra ni kí wọ́n má bàa gbin nǹkan síbi tí kò ti ní lè dàgbà. A nílò ìfòyemọ̀ bí èyí nígbà tí a bá ń fi ìwé wa lọ àwọn èèyàn lóde ẹ̀rí. Ohun tí a fẹ́ ni pé àwọn tó fẹ́ láti ka ìwé wa ni a fẹ́ fi wọ́n lé lọ́wọ́. A fẹ́ kí àwọn tó jẹ́ ẹni yíyẹ ní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà àti ìrètí Ìjọba náà.
2 Ǹjẹ́ o rí i pé àwọn ìwé ìròyìn, ìwé pẹlẹbẹ, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ń ṣẹ́jọ sínú àpótí ìwé ní ilé rẹ nígbà tó jẹ́ pé o ṣì lè lò wọ́n láti jẹ́ kí àwọn ẹni yíyẹ tó wà ní ìpínlẹ̀ rẹ ní ìmọ̀ òtítọ́? (Fi wé Mátíù 25:25.) Ǹjẹ́ o máa ń fà sẹ́yìn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti fi ìwé ìròyìn àti àwọn ìwé wa mìíràn lọ àwọn èèyàn nígbà tí o bá dé ọ̀dọ̀ wọn fún ìgbà àkọ́kọ́ kìkì nítorí pé o rí i pé kò rọrùn fún ọ láti sọ nípa bí a ti ń ṣe ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà? Àwọn akéde onírìírí ti rí i pé àwọn onílé tí wọ́n mọrírì máa ń ṣètìlẹyìn nígbà tí a bá sọ fún wọn ní tààràtà nípa bí a ṣe ń lo ọrẹ tí wọ́n bá fi ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà, tí a sì sọ ọ́ ní ṣókí.
3 O lè sọ pé:
◼ “O lè máa ṣe kàyéfì nípa bí a ṣe lè máa fún àwọn èèyàn ní ìwé láìjẹ́ pé a béèrè iye kan ní pàtó. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ jákèjádò ayé tí a máa ń fi ọrẹ àtinúwá ṣètìlẹ́yìn fún. Bí o bá fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ yìí, inú mi yóò dùn gidigidi láti gbà á.”
4 Ọ̀pọ̀ onílé ló máa ń béèrè iye owó ìwé wa.
O lè fèsì pé:
◼ “A kì í dá iye lé ìwé wa nítorí ọrẹ àtinúwá la máa fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa. Bí o bá fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹyìn lónìí, inú wa yóò dùn, a óò sì lò ó fún iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe jákèjádò ayé.”
Tàbí o lè sọ pé:
◼ “A máa ń fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ní ìwé wa. Bí o bá fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ tí a ń ṣe jákèjádò ayé yìí, inú mi yóò dùn láti bá ọ fi ọrẹ náà ránṣẹ́.”
5 Lẹ́nu iṣẹ́ ìwé ìròyìn, àwọn akéde kan máa ń ṣí ìwé ìròyìn náà wọ́n á sì fi han onílé níbi tí a kọ ọ́ sí pé:
◼ “Bí o ṣe rí i níhìn-ín, ọrẹ àtinúwá ni a fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wa. Bí o bá fẹ́ láti fi ọrẹ díẹ̀ ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ yìí, mo lè gbà á.”
Tún wo gbólóhùn mìíràn tí o lè sọ ní ṣókí:
◼ “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í dá iye lé ìwé wa, a máa ń gba ọrẹ tó mọ níwọ̀n fún iṣẹ́ tí a ń ṣe jákèjádò ayé yìí.”
6 Kí a má ṣe fà sẹ́yìn nínú fífúnrúgbìn Ìjọba náà nítorí pé a ń lọ́tìkọ̀ láti sọ bí a ṣe ń gbọ́ bùkátà iṣẹ́ yìí. Lọ́wọ́ kan náà, a nílò ìfòyemọ̀ kí a má bàa fi àwọn ìwé wa ṣòfò sórí ‘ilẹ̀ àpáta.’ (Máàkù 4:5, 6, 16, 17) Inú àwọn tó mọrírì ìhìn rere tí a ń mú tọ̀ wọ́n lọ máa ń dùn pé àwọn ní àǹfààní láti fi ohun ìní àwọn tì í lẹ́yìn.—Fi wé Mátíù 10:42.