Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
1. Àǹfààní wo ló jẹ yọ bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
1 Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó wàásù ìhìn rere ní gbogbo ayé “láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” Gbogbo òjíṣẹ́ tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni yìí mọ bí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà tá a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, a lè rí àwọn tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa. Ó yẹ kí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run kí wọ́n sì fara mọ́ òtítọ́ kí ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù Jèhófà tó dé. (Mál. 3:18) Báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
2. Báwo la ṣe ń fara wé Jèhófà tá a bá ń bá àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa sọ̀rọ̀?
2 Máa Wo Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì Bí Jèhófà Ṣe Ń Wò Wọ́n: Tá a bá fẹ́ fi irú ìfẹ́ tí Jèhófà ní hàn sí gbogbo èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa láìṣojúsàájú, ó gbọ́dọ̀ máa wù wá gan-an láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, láìka èdè tí wọ́n ń sọ sí. (Sm. 83:18; Iṣe 10:34, 35) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èdè tí ìjọ tá à ń dara pọ̀ mọ́ ń sọ la máa ń fún láfiyèsí jù, kò yẹ ká gbójú fo àwọn tó ń sọ èdè míì tó yàtọ̀ sí tiwa, ó sì yẹ ká wá bá a ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. Tá a bá ń gbójú fo àwọn tó ń sọ èdè míì, ìyẹn kò ní bá ìfẹ́ Jèhófà mu pé ká jẹ́rìí fún èèyàn orílẹ̀-èdè gbogbo. Nígbà náà, báwo la ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa?
3. Irinṣẹ́ tó wúlò wo ni ètò Ọlọ́run ti pèsè fún wa, báwo la sì ṣe lè múra sílẹ̀ láti lò ó?
3 Lo Ìwé Good News for People of All Nations: A ṣe ìwé yìí ká lè máa lò ó tá a bá pàdé àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa. Máa mú ìwé yìí dání nígbà gbogbo, rí i pé o mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ dunjú, kó o sì ṣe tán láti lò ó. Kó o bàa lè tètè rí ibi tí èdè tó o fẹ́ lò wà, á dáa kó o sàmì sí àwọn èdè tí wọ́n ń sọ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín nínú ìwé náà. Tẹ́ ẹ bá ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn èdè yìí, á dáa kó o gba díẹ̀, kó o lè fún ẹni tó o bá wàásù fún lẹ́yìn tó bá ti ka ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé náà.
4. Báwo la ṣe lè lo ìwé Good News for People of All Nations lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
4 Tó o bá rí ẹnì kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó o sì ṣàkíyèsí pé èdè ilẹ̀ òkèèrè ló ń sọ, o lè kọ́kọ́ fi èèpo ẹ̀yìn ìwé náà hàn án, lẹ́yìn náà fi àwòrán orílẹ̀-èdè tó wà nínú èèpo ẹ̀yìn ìwé hàn án, kó o wá fọwọ́ kan ara rẹ kó o sì fọwọ́ kan orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, kó o wá sọ fún ẹni náà pé o fẹ́ mọ orílẹ̀-èdè tó ti wá, kó o sì béèrè èdè tó ń sọ. Tó o bá ti mọ èdè rẹ̀, wo kókó ẹ̀kọ́ inú ìwé, wá ojú ewé tí èdè rẹ̀ wà nínú ìwé náà, ní kó wo ọ̀rọ̀ tó dúdú kirikiri tó wà lókè, kó o wá sọ fún un pé kó ka ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀. Tó bá ti kà á tán, fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan ní èdè rẹ̀ tàbí kó o nawọ́ sí ibi tó ti máa rí gbólóhùn tó fi hàn pé wàá bá a wá ìwé kan tá a tẹ̀ ní èdè rẹ wàá sì mú un wá fún un. Lẹ́yìn náà, fọwọ́ kan ibi tá a fi lẹ́tà dúdú kirikiri kọ “orúkọ mi” sí, kó o sì sọ orúkọ rẹ lọ́nà tó ṣe kedere. Nawọ́ sí ibi tá a fi lẹ́tà dúdú kirikiri kọ “orúkọ rẹ” sí, kó o sì dúró kí ẹni náà sọ orúkọ rẹ̀. Ẹ jọ ṣe àdéhùn pàtó nípa ìgbà tó o máa pa dà wá.
5. Ìgbésẹ̀ wo ló yẹ ká gbé ká bàa lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè míì tí wọ́n fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
5 Ètò fún Ìpadàbẹ̀wò: A gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, èdè yòówù kí wọ́n máa sọ. Tá a bá ti kíyè sí i pé ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, a gbọ́dọ̀ kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Please Follow Up (S-43), ká sì tètè fún akọ̀wé ìjọ kó lè fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì (tàbí ìjọ tàbí àwùjọ tó ń sọ èdè yẹn, tó bá mọ̀ ọ́n) kí wọ́n bàa lè ṣètò bí ẹnì kan tó gbọ́ èdè rẹ̀ á ṣe lọ kàn sí i. Ẹ̀ka ọ́fíìsì á wá fi ẹ̀dà fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí àwùjọ tó ń sọ èdè yẹn. Tí àwùjọ tó ń sọ èdè náà bá ti gba lẹ́tà yìí, wọ́n á ṣètò bí ẹnì kan ṣe máa kàn sí onítọ̀hún láìjáfara. Akọ̀wé ìjọ lè fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ní ẹ̀dà fọ́ọ̀mù náà kó bàa lè mọ̀ pé ẹnì kan látinú àwùjọ tó ń sọ èdè kan fìfẹ́ hàn. Bó bá ti ṣe kedere pé ẹnì kan fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ni kẹ́ ẹ tó lo fọ́ọ̀mù yìí.
6. Tí ẹnì kan tó ń sọ èdè míì bá fìfẹ́ hàn, kí ló yẹ ká ṣe?
6 Ó lè gba àkókò díẹ̀ láàárín ìgbà tá a fi fọ́ọ̀mù S-43 ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì kí akéde kan tá a yàn tó kàn sí ẹni tó fìfẹ́ hàn náà. Torí náà, kó má bàa di pé ìfẹ́ onítọ̀hún bẹ̀rẹ̀ sí dín kù, akéde tó kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù S-43 náà ṣì lè máa lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà, kó bàa lè máa lọ koná mọ́ ìfẹ́ tó ní sí òtítọ́, títí dìgbà tí ẹni tó gbọ́ èdè rẹ̀ á fi kàn sí i. Nígbà míì sì rèé, a lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹni tó fìfẹ́ hàn náà. Àmọ́, láàárín àkókò yìí, báwo ni akéde kan á ṣe máa gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè ẹni tó fìfẹ́ hàn náà?
7. Ètò wo ló wà fún gbígba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè àwọn tá a lè bá pàdé lóde ẹ̀rí?
7 Bá A Ṣe Lè Gba Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Fáwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì: Ẹ má ṣe ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn èdè míì. Àmọ́, tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá rí i pé àwọn tó ń sọ èdè pàtó kan ti bẹ̀rẹ̀ sí fìfẹ́ hàn dáadáa, ó lè rí i pé á dáa kóun gba iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ pàtó kan tó mọ níwọ̀n ní èdè yẹn, kí àwọn akéde lè máa rí i lò. Tí ìjọ kò bá ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ẹ lè béèrè fún un. Ó lè gba àkókò díẹ̀ kí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dé ní èdè kan. Torí náà, a ṣì lè tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan jáde látorí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì wa, ìyẹn www.watchtower.org. Ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè, tí akéde kan tàbí ẹni tó fìfẹ́ hàn náà lè rí kà látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kò sí àní-àní pé ètò yìí máa wúlò gan-an láti mú kí ìfẹ́ táwọn tó ń sọ èdè míì ní sí òtítọ́ pọ̀ sí i.
8. Báwo ni ìjọ ṣe lè mú káwọn tó ń sọ èdè míì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òtítọ́?
8 Ojúṣe Ìjọ: Láwọn ìgbà míì, táwọn tó pọ̀ díẹ̀ bá ń sọ èdè kan ládùúgbò kan, tí wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí gbèrú, ó lè máà sí ìjọ kankan nítòsí tó ń ṣe ìpàdé ní èdè yẹn. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, kẹ́ ẹ pe àwọn tó fìfẹ́ hàn tí wọ́n ń sọ èdè yẹn láti wá máa bá yín ṣèpàdé. Tẹ́ ẹ bá fọ̀yàyà kí wọn káàbọ̀, tẹ́ ẹ sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ yín lógún, èyí lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé déédéé. Níbẹ̀rẹ̀, èdè àti àṣà ìbílẹ̀ tó yàtọ̀ síra lé fẹ́ fa ìdíwọ́ díẹ̀; àmọ́, kò sí nǹkan tó lè ṣèdíwọ́ fún ìfẹ́ Kristẹni tòótọ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a jẹ́ ẹgbẹ́ ará karí ayé. (Sef. 3:9; Jòh. 13:35) Ṣó o lè sọ èdè míì bí èdè Faransé, èdè Jámánì, èdè Árábíìkì tàbí èdè ilẹ̀ òkèèrè míì dáadáa? Ṣé ó sì wù ẹ́ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè yẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́, sọ fún akọ̀wé ìjọ yín kó lè fi ìsọfúnni yìí ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ìsọfúnni yìí máa wúlò nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì bá ń wá akéde tó máa lọ ṣèrànwọ́ bí ẹnì kan tó ń sọ èdè míì bá fìfẹ́ hàn sí òtítọ́.
9. Ìgbà wo ló lè gba pé ká bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ èdè, báwo la sì ṣe gbọ́dọ̀ ṣe é?
9 Ilé Ẹ̀kọ́ Èdè: Nígbà tó o bá ń ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń sọ èdè míì, ohun tó máa dáa jù lọ ni pé kó o fún wọn níṣìírí láti lọ máa ṣèpàdé ní ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè wọn, bí ibẹ̀ kò bá jìnnà jù. Bí ìyẹn kò bá ṣeé ṣe, àwọn akéde kan lè pinnu láti kọ́ èdè yẹn kí wọ́n bàa lè ṣèrànwọ́ tó yẹ fáwọn tó fìfẹ́ hàn sí òtítọ́. Bí kò bá sí ìjọ nítòsí, tí àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè ní àgbègbè náà sì pọ̀ díẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì lè pinnu pé kí a dá ilé ẹ̀kọ́ kan silẹ̀ tí wọ́n á ti máa kọ́ èdè náà. Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀ka ọ́fíìsì lè sọ fáwọn ìjọ tó wà nítòsí nípa àìní náà kí wọ́n sì ṣèfilọ̀ pé a ti dá ilé ẹ̀kọ́ èdè kan sílẹ̀. Àwọn tó fẹ́ kọ́ èdè yìí gbọ́dọ̀ ní in lọ́kàn láti kúrò ní ìjọ tí wọ́n wà, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè náà, kí wọ́n lè lọ ṣèrànwọ́ láti mú kí ìtẹ̀síwájú bá ìjọ tàbí àwùjọ tuntun náà.
10. Ìgbà wo la lè dá àwùjọ tó ń sọ èdè míì sílẹ̀, kí ni ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà sì gbọ́dọ̀ ṣe lórí èyí?
10 Bá A Ṣe Lè Dá Àwùjọ Sílẹ̀: Ká tó lè dá àwùjọ tó ń sọ èdè kan sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ dójú ìlà àwọn nǹkan mẹ́rin yìí. (1) Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí èdè náà gbọ́dọ̀ pọ̀ tó, kí ẹ̀rí sì wà pé àwùjọ náà á máa gbèrú. (2) Àwùjọ àwọn akéde kan gbọ́dọ̀ wà tí wọ́n mọ èdè náà tàbí kí wọ́n máa kọ́ ọ lọ́wọ́. (3) Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó dáńgájíá gbọ́dọ̀ wà lárọ̀ọ́wọ́tó táá máa mú ipò iwájú, tó sì jẹ́ pé ó kéré tán, á máa darí ìpàdé kan lọ́sẹ̀ ní èdè náà. (4) Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà kan gbọ́dọ̀ wà táá máa ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ náà. Tá a bá ti dójú ìlà àwọn ohun tá à ń béèrè fún yìí dé ìwọ̀n àyè kan, kí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fi ìsọfúnni nípa àwùjọ náà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kí wọ́n lè fọwọ́ sí i pé kí ìjọ wọn máa ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ tó ń sọ èdè míì. (Wo ìwé A Ṣètò Wa ojú ìwé 106 àti 107.) A ó máa pe alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń bójú tó àwùjọ náà ní “alábòójútó àwùjọ” tàbí “ìránṣẹ́ àwùjọ.”
11. Kí nìdí tó fi jẹ́ àǹfààní ńláǹlà láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
11 Wíwàásù fún àwọn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa jẹ́ apá pàtàkì lára iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé, èyí tí Jésù Kristi tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa dá sílẹ̀. Ǹjẹ́ ká máa fìtara ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ yìí, ká sì rí i bí Jèhófà ṣe ń mi orílẹ̀-èdè jìgìjìgì tó sì ń fa àwọn èèyàn tó fani lọ́kàn mọ́ra sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Hág. 2:7) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa nínú ìsapá yìí! Ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún gbogbo wa bá a ṣe ń sapá láti wàásù fáwọn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, ká sì máa rántí pé láìka àwọn ìdíwọ́ tó máa ń yọjú sí nítorí èdè tó yàtọ̀ síra, Ọlọ́run lè mú kó dàgbà!—1 Kọ́r. 3:6-9.