Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ó wu Jèhófà pé kí àwọn èèyàn láti inú “gbogbo orílẹ̀-èdè” ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú òun. (Ìṣe 10:34, 35) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé, a ó sì wàásù ìhìn rere yìí “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé” àti “fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 24:14) Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè” máa fetí sí ìhìn rere. (Sek. 8:23) Ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù rí fi hàn pé àwọn tó máa la ìpọ́njú ńlá já máa wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n [tàbí èdè].” (Ìṣí. 7:9, 13, 14) Èyí jẹ́ ká rí i pé, ó yẹ ká máa sapá láti jẹ́rìí fún àwọn tó ń sọ èdè míì ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Nígbà tẹ́ ẹ bá tún máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ ṣe ìdánrawò bí ẹ ṣe lè jẹ́rìí fún ẹnì kan tí kò gbọ́ èdè yín.