Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 11
Orin 84 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 24 ìpínrọ̀ 11 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 4-8 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 6:14-23 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Sẹ́ni Tó Bá Kú?—igw ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Sọ fún Ọkùnrin Kan Pé Kó Má Ṣe Pe Òun Ní “Olùkọ́ Rere”—Máàkù 10:17, 18 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.—1 Tím. 2:3, 4.
10 min: Ran Onírúurú Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lé Ní Ìmọ̀ Pípéye Nípa Òtítọ́. Àsọyé tá a gbé ka ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí. (Wo Ilé Ìṣọ́ November 15, 2013, ojú ìwé 11 sí 12, ìpínrọ̀ 8.) Ka 1 Tímótì 2:3, 4 àti 1 Kọ́ríńtì 9:19-23, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Mẹ́nu ba àwọn apá kan nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti oṣù yìí, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe tan mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ oṣù yìí.
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn ṣókí kan tó sì nítumọ̀ nípa bí akéde kan ṣe ń fi ìwé Good News for People of All Nations jẹ́rìí fún ẹnì kan lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
Orin 105 àti Àdúrà