Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 18
Orin 50 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 24 ìpínrọ̀ 18 sí 21, àti àpótí tó wà lójú ìwé 249 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 9-12 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 10:13–11:4 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Fi Hàn Pé Jèhófà Nìkan Là Ń Jọ́sìn—Róòmù 6:16, 17 (5 min.)
No. 3: Ìrètí Wo Ló Wà Fáwọn Tó Ti Kú?—igw ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.—1 Tím. 2:3, 4.
10 min: Bí Pọ́ọ̀lù Ṣe Ran Àwọn Gíríìkì Lọ́wọ́ Láti Ní Ìmọ̀ Pípéye Nípa Òtítọ́. Ìjíròrò. Ẹ ka Ìṣe 17:22-31. Kí ẹ jíròrò bí àwọn ẹ̀kọ́ tí ìtàn yìí kọ́ wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.
20 min: Jèhófà Á Jẹ́ Kó O Nígboyà. Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò náà Jèhófà Á Jẹ́ Kó O Nígboyà. (Lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN ỌMỌDÉ.) Ní kí àwọn ará sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú fídíò náà. Ní kí àwọn ọmọ iléèwé sọ bí fídíò yìí ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìgboyà wàásù fún àwọn ọmọ kíláàsì wọn àtàwọn olùkọ́ wọn. Ṣe àṣefihàn ìrírí kan tó gbádùn mọ́ni jù lọ lára àwọn ìrírí tí àwọn ọmọ náà ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí ní iléèwé. Tí kò bá sí ètò láti wo fídíò náà, ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọmọdé Tó Mú Inú Ọlọ́run Dùn,” tá a mú jáde látinú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, ojú ìwé 215 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 216 ìpínrọ̀ 3. Ní kí àwọn ará sọ ohun tí wọ́n kọ́ látinú àpilẹ̀kọ náà. Ní kí àwọn ọmọléèwé sọ bí àpẹẹrẹ ọ̀dọ́bìnrin ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ṣe lè mú kí wọ́n fìgboyà jẹ́rìí fún àwọn ọmọléèwé àti olùkọ́ wọn. Ṣe àṣefihàn ìrírí kan tó gbádùn mọ́ni tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà ní nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí ní iléèwé.
Orin 60 àti Àdúrà