Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 25
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 25
Orin 56 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 25 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 13-15 (8 min.)
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 13:34–14:7 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́?—igw ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Róòmù 8:21 Ṣe Máa Ní Ìmúṣẹ, Ìgbà Wo Ló sì Máa Ní Ìmúṣẹ? (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.—1 Tím. 2:3, 4.
10 min: Fọ̀rọ̀ Wá Ọ̀rọ̀ Wò Lẹ́nu Alábòójútó Àwùjọ Kan. Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àwùjọ? Àwọn ìsapá wo lẹ máa ń ṣe kí ẹ lè ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn tó wà ní àwùjọ yín kí ẹ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn akéde jẹ́ kí alábòójútó àwùjọ wọn mọ̀ tí àdírẹ́sì tàbí ìsọfúnni nípa béèyàn ṣe lè kàn sí wọn bá yí pa dà? Kí nìdí tó fi máa dára kí àwọn alàgbà ṣètò kí àwọn àwùjọ máa pàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ dípò kí wọ́n máa pàdé níbì kan náà?
20 min: “Ran Àwọn Afọ́jú Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Mọ Jèhófà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn kan.
Orin 96 àti Àdúrà