ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb21 January ojú ìwé 13
  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wàásù fún Gbogbo Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wàásù fún Gbogbo Èèyàn
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Jẹ́rìí fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I​—Máa Wàásù fún Gbogbo Èèyàn ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Rẹ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2017)
  • Ẹ Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Láti Wàásù Láwọn Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Onírúurú Èdè
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
mwb21 January ojú ìwé 13
Arákùnrin kan ń lo ètò ìṣiṣẹ́ ‘JW Language’ lórí fóònù rẹ̀.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Jèhófà Fẹ́ Ká Wàásù fún Gbogbo Èèyàn

Bí Jèhófà ṣe mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà létòlétò, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe fẹ́ ká wà létòlétò lónìí ká lè máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kárí ayé, gbogbo ẹ̀ka ọ́fíìsì, àyíká, ìjọ àtàwọn àwùjọ kéékèèké ló ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí ìhìn rere náà lè máa tẹ̀ síwájú. Gbogbo èèyàn là ń wàásù fún, kódà a tún máa ń wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa.​—Ifi 14:6, 7.

Ṣé ìwọ náà lè kọ́ èdè míì kó o lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́? Kódà tí ò bá rọrùn fún ẹ láti ya àkókò sọ́tọ̀ kó o lè kọ́ èdè míì, o lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language láti kọ́ bó o ṣe lè fi èdè míì wàásù lọ́nà tó rọrùn. Tó o bá lo ọ̀nà yìí, ó dájú pé ìwọ náà máa láyọ̀ bíi tàwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n fi oríṣiríṣi èdè wàásù “àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run,” tí wọ́n sì rí bí inú àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn ṣe ń dùn.​—Iṣe 2:7-11.

Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ DI Ọ̀RẸ́ JÈHÓFÀ​—MÁA WÀÁSÙ FÚN ÀWỌN TÓ Ń SỌ ÈDÈ MÍÌ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.’ Kọ́là ń ro bó ṣe máa rí ká sọ pé òun lè rí ẹ̀rọ tó máa bá òun wàásù fún obìnrin kan tó ń sọ èdè míì.

    Ìgbà wo lo lè lo ètò ìṣiṣẹ́ JW Language?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.’ Apá téèyàn ti lè kọ́ ìkíni àti béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ní èdè míì lórí ètò ìṣiṣẹ́ ‘JW Language.’

    Àwọn nǹkan wo ló wà lórí ètò ìṣiṣẹ́ yìí?

  • Àwòrán látinú fídíò ‘Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Wàásù fún Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Míì.’ Inú obìnrin yẹn dùn nígbà tí Kọ́lá àti Tósìn kí i ní èdè Ṣáínà.

    Ó yẹ kí gbogbo èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè gbọ́ ìhìn rere

    Oríṣiríṣi èdè wo ni wọ́n ń sọ lágbègbè yín?

  • Kí lo lè ṣe tí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o fẹ́ sọ ò bá gbọ́ èdè rẹ?​—od 100-101 ¶39-41

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́